< Job 20 >

1 Ìgbà náà ní Sofari, ará Naama dáhùn, ó sì wí pé,
ויען צפר הנעמתי ויאמר
2 “Nítorí náà ní ìrò inú mi dá mi lóhùn, àti nítorí èyí náà ní mo sì yára si gidigidi.
לכן שעפי ישיבוני ובעבור חושי בי
3 Mo ti gbọ́ ẹ̀san ẹ̀gàn mi, ẹ̀mí òye mi sì dá mi lóhùn.
מוסר כלמתי אשמע ורוח מבינתי יענני
4 “Ìwọ kò mọ̀ èyí rí ní ìgbà àtijọ́, láti ìgbà tí a sọ ènìyàn lọ́jọ̀ sílé ayé,
הזאת ידעת מני-עד מני שים אדם עלי-ארץ
5 pé, orin ayọ̀ ènìyàn búburú, ìgbà kúkúrú ni, àti pé, ní ìṣẹ́jú kan ní ayọ̀ àgàbàgebè?
כי רננת רשעים מקרוב ושמחת חנף עדי-רגע
6 Bí ọláńlá rẹ̀ tilẹ̀ gòkè dé ọ̀run, ti orí rẹ̀ sì kan àwọsánmọ̀;
אם-יעלה לשמים שיאו וראשו לעב יגיע
7 ṣùgbọ́n yóò ṣègbé láéláé bí ìgbẹ́ ara rẹ̀; àwọn tí ó ti rí i rí yóò wí pé, ‘Òun ha dà?’
כגללו לנצח יאבד ראיו יאמרו איו
8 Yóò fò lọ bí àlá, a kì yóò sì rí i, àní a ó lé e lọ bi ìran òru.
כחלום יעוף ולא ימצאהו וידד כחזיון לילה
9 Ojú tí ó ti rí i rí kì yóò sì rí i mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ibùjókòó rẹ̀ kì yóò sì ri i mọ́.
עין שזפתו ולא תוסיף ולא-עוד תשורנו מקומו
10 Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wá àti rí ojúrere lọ́dọ̀ tálákà, ọwọ́ rẹ̀ yóò sì kó ọrọ̀ wọn padà.
בניו ירצו דלים וידיו תשבנה אונו
11 Egungun rẹ̀ kún fún agbára ìgbà èwe rẹ̀, tí yóò bá a dùbúlẹ̀ nínú erùpẹ̀.
עצמותיו מלאו עלומו ועמו על-עפר תשכב
12 “Bí ìwà búburú tilẹ̀ dún ní ẹnu rẹ̀, bí ó tilẹ̀ pa á mọ́ nísàlẹ̀ ahọ́n rẹ̀,
אם-תמתיק בפיו רעה-- יכחידנה תחת לשנו
13 bí ó tilẹ̀ dá a sì, tí kò si kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí ó pa á mọ́ síbẹ̀ ní ẹnu rẹ̀,
יחמל עליה ולא יעזבנה וימנענה בתוך חכו
14 ṣùgbọ́n oúnjẹ rẹ̀ nínú ikùn rẹ̀ ti yípadà, ó jásí òróró paramọ́lẹ̀ nínú rẹ̀;
לחמו במעיו נהפך מרורת פתנים בקרבו
15 Ó ti gbé ọrọ̀ mì, yóò sì tún bí i jáde; Ọlọ́run yóò pọ̀ ọ́ yọ jáde láti inú rẹ̀ wá.
חיל בלע ויקאנו מבטנו ירשנו אל
16 Ó ti fà oró paramọ́lẹ̀ mú; ahọ́n ejò olóró ní yóò pa á.
ראש-פתנים יינק תהרגהו לשון אפעה
17 Kì yóò rí odò wọ̀n-ọn-nì, ìṣàn omi, odò tí ń ṣàn fún oyin àti ti òrí-àmọ́.
אל-ירא בפלגות-- נהרי נחלי דבש וחמאה
18 Ohun tí ó ṣiṣẹ́ fún ni yóò mú un padà, kí yóò sì gbé e mì; gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ tí ó ní, kì yóò sì ìgbádùn nínú rẹ̀.
משיב יגע ולא יבלע כחיל תמורתו ולא יעלס
19 Nítorí tí ó fi owó rẹ̀ ni tálákà lára, ó sì ti pẹ̀yìndà si wọ́n; nítorí ti ó fi agbára gbé ilé tí òun kò kọ́.
כי-רצץ עזב דלים בית גזל ולא יבנהו
20 “Nítorí òun kò mọ̀ ìwà pẹ̀lẹ́ nínú ara rẹ̀, kì yóò sì gbà nínú èyí tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ sílẹ̀.
כי לא-ידע שלו בבטנו בחמודו לא ימלט
21 Ohun kan kò kù fún jíjẹ́ rẹ̀; nítorí náà ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì yóò dúró pẹ́.
אין-שריד לאכלו על-כן לא-יחיל טובו
22 Nínú ànító rẹ̀, ìdààmú yóò dé bá a; àwọn ènìyàn búburú yóò dáwọ́jọ lé e lórí.
במלאות שפקו יצר לו כל-יד עמל תבאנו
23 Yóò sì ṣe, nígbà tí ó bá fẹ́ jẹun, Ọlọ́run yóò fà ríru ìbínú rẹ̀ sí í lórí, nígbà tó bá ń jẹun lọ́wọ́, yóò sì rọ òjò ìbínú rẹ̀ lé e lórí.
יהי למלא בטנו--ישלח-בו חרון אפו וימטר עלימו בלחומו
24 Bi o tilẹ̀ sá kúrò lọ́wọ́ ohun ìjà ìrìn; ọrun akọ irin ní yóò ta a po yọ.
יברח מנשק ברזל תחלפהו קשת נחושה
25 O fà á yọ, ó sì jáde kúrò lára; idà dídán ní ń jáde láti inú òróòro wá. Ẹ̀rù ńlá ń bẹ ní ara rẹ̀;
שלף ויצא מגוה וברק ממררתו יהלך עליו אמים
26 òkùnkùn biribiri ní a ti pamọ́ fún ìṣúra rẹ̀. Iná ti a kò fẹ́ ní yóò jó o run yóò sì jẹ èyí tí ó kù nínú àgọ́ rẹ̀ run.
כל-חשך טמון לצפוניו תאכלהו אש לא-נפח ירע שריד באהלו
27 Ọ̀run yóò fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ hàn, ayé yóò sì dìde dúró sí i.
יגלו שמים עונו וארץ מתקוממה לו
28 Ìbísí ilé rẹ̀ yóò kọjá lọ, àti ohun ìní rẹ̀ yóò sàn dànù lọ ni ọjọ́ ìbínú Ọlọ́run.
יגל יבול ביתו נגרות ביום אפו
29 Èyí ni ìpín ènìyàn búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, àti ogún tí a yàn sílẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”
זה חלק-אדם רשע--מאלהים ונחלת אמרו מאל

< Job 20 >