< Job 19 >

1 Ìgbà náà ni Jobu dáhùn, ó sì wí pé:
respondens autem Iob dixit
2 “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin ó fi máa fi ìyà jẹ mí, tí ẹ̀yin ó fi máa fi ọ̀rọ̀ yìí?
usquequo adfligitis animam meam et adteritis me sermonibus
3 Ìgbà mẹ́wàá ní yin yọ mi lénu ẹ̀yin ti ń gàn mí; ojú kò tì yín tí ẹ fi jẹ mí ní yà.
en decies confunditis me et non erubescitis opprimentes me
4 Kí a sì wí bẹ́ẹ̀ pé, mo ṣìnà nítòótọ́, ìṣìnà mi wà lára èmi tìkára mi.
nempe et si ignoravi mecum erit ignorantia mea
5 Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ̀yin ó ṣògo si mi lórí nítòótọ́, tí ẹ ó sì máa fi ẹ̀gàn mi gún mí lójú,
at vos contra me erigimini et arguitis me obprobriis meis
6 kí ẹ mọ̀ nísinsin yìí pé, Ọlọ́run ni ó bì mí ṣubú, ó sì nà àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká.
saltim nunc intellegite quia Deus non aequo iudicio adflixerit me et flagellis suis me cinxerit
7 “Kíyèsi, èmi ń kígbe pe, ‘Ọwọ́ alágbára!’ Ṣùgbọ́n a kò gbọ́ ti èmi; mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdájọ́.
ecce clamabo vim patiens et nemo audiet vociferabor et non est qui iudicet
8 Ó ṣọgbà dí ọ̀nà mi tí èmi kò le è kọjá, Ó sì mú òkùnkùn ṣú sí ipa ọ̀nà mi.
semitam meam circumsepsit et transire non possum et in calle meo tenebras posuit
9 Ó ti bọ́ ògo mi, ó sì ṣí adé kúrò ní orí mi.
spoliavit me gloria mea et abstulit coronam de capite meo
10 Ó ti bà mí jẹ́ ní ìhà gbogbo, ẹ̀mí sì pin; ìrètí mi ni a ó sì fàtu bí igi.
destruxit me undique et pereo et quasi evulsae arbori abstulit spem meam
11 Ó sì tiná bọ ìbínú rẹ̀ sí mi, ó sì kà mí sí bí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀tá rẹ̀.
iratus est contra me furor eius et sic me habuit quasi hostem suum
12 Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ sì dàpọ̀ sí mi, wọ́n sì mọ odi yí mi ká, wọ́n sì yí àgọ́ mi ká.
simul venerunt latrones eius et fecerunt sibi viam per me et obsederunt in gyro tabernaculum meum
13 “Ó mú àwọn arákùnrin mi jìnà sí mi réré, àti àwọn ojúlùmọ̀ mi di àjèjì sí mi pátápátá.
fratres meos longe fecit a me et noti mei quasi alieni recesserunt a me
14 Àwọn alájọbí mi fàsẹ́yìn, àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi sì di onígbàgbé mi.
dereliquerunt me propinqui mei et qui me noverant obliti sunt mei
15 Àwọn ará inú ilé mi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi kà mí sí àjèjì; èmi jásí àjèjì ènìyàn ní ojú wọn.
inquilini domus meae et ancillae meae sicut alienum habuerunt me et quasi peregrinus fui in oculis eorum
16 Mo pe ìránṣẹ́ mi, òun kò sì dá mi lóhùn; mo fi ẹnu mi bẹ̀ ẹ́.
servum meum vocavi et non respondit ore proprio deprecabar illum
17 Ẹ̀mí mi ṣú àyà mi, àti òórùn mi ṣú àwọn ọmọ inú ìyá mi.
halitum meum exhorruit uxor mea et orabam filios uteri mei
18 Àní àwọn ọmọdékùnrin fi mí ṣẹ̀sín, mo dìde, wọ́n sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi.
stulti quoque despiciebant me et cum ab eis recessissem detrahebant mihi
19 Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi kórìíra mi, àwọn olùfẹ́ mi sì kẹ̀yìndà mí.
abominati sunt me quondam consiliarii mei et quem maxime diligebam aversatus est me
20 Egungun mi lẹ̀ mọ́ ara mi àti mọ́ ẹran-ara mi, mo sì yọ́ pẹ̀lú awọ eyín mi.
pelli meae consumptis carnibus adhesit os meum et derelicta sunt tantummodo labia circa dentes meos
21 “Ẹ ṣàánú fún mi, ẹ ṣàánú fún mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, nítorí ọwọ́ Ọlọ́run ti bà mí.
miseremini mei miseremini mei saltim vos amici mei quia manus Domini tetigit me
22 Nítorí kí ni ẹ̀yin ṣe lépa mi bí Ọlọ́run, tí ẹran-ara mi kò tẹ́ yín lọ́rùn?
quare persequimini me sicut Deus et carnibus meis saturamini
23 “Háà! Ìbá ṣe pé a le kọ̀wé ọ̀rọ̀ mi nísinsin yìí, ìbá ṣe pé a le kọ ọ sínú ìwé!
quis mihi tribuat ut scribantur sermones mei quis mihi det ut exarentur in libro
24 Kí a fi kálámù irin àti ti òjé kọ wọ́n sínú àpáta fún láéláé.
stilo ferreo et plumbi lammina vel certe sculpantur in silice
25 Nítorí èmi mọ̀ pé olùdáǹdè mi ń bẹ láààyè àti pe òun ni yóò dìde dúró lórí ilẹ̀ ní ìkẹyìn;
scio enim quod redemptor meus vivat et in novissimo de terra surrecturus sim
26 àti lẹ́yìn ìgbà tí a pa àwọ̀ ara mi run, síbẹ̀ láìsí ẹran-ara mi ni èmi ó rí Ọlọ́run,
et rursum circumdabor pelle mea et in carne mea videbo Deum
27 ẹni tí èmi ó rí fún ara mi, tí ojú mi ó sì wo, kì sì í ṣe ti ẹlòmíràn; ọkàn mi sì dákú ní inú mi.
quem visurus sum ego ipse et oculi mei conspecturi sunt et non alius reposita est haec spes mea in sinu meo
28 “Bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘Àwa ó ti lépa rẹ̀ tó! Àti pé, gbogbo ọ̀rọ̀ náà ni a sá à rí ní ọwọ́ rẹ̀,’
quare ergo nunc dicitis persequamur eum et radicem verbi inveniamus contra eum
29 kí ẹ̀yin kí ó bẹ̀rù, nítorí ìbínú ní í mú ìjìyà wá nípa idà, kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé ìdájọ́ kan ń bẹ.”
fugite ergo a facie gladii quoniam ultor iniquitatum gladius est et scitote esse iudicium

< Job 19 >