< Job 18 >

1 Ìgbà náà ni Bilidadi, ará Ṣuhi, dáhùn, ó sì wí pé,
ויען בלדד השחי ויאמר
2 “Nígbà wo ni ẹ̀yin yóò tó fi ìdí ọ̀rọ̀ tì; ẹ rò ó, nígbẹ̀yìn rẹ̀ ni àwa ó tó máa sọ.
עד-אנה תשימון קנצי למלין תבינו ואחר נדבר
3 Nítorí kí ni a ṣe ń kà wá sí bí ẹranko, tí a sì ń kà wá si bí ẹni ẹ̀gàn ní ojú yín?
מדוע נחשבנו כבהמה נטמינו בעיניכם
4 Ìwọ fa ara rẹ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nínú ìbínú rẹ̀; kí a ha kọ ayé sílẹ̀ nítorí rẹ̀ bi? Tàbí kí a sí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀?
טרף נפשו באפו הלמענך תעזב ארץ ויעתק-צור ממקמו
5 “Nítòótọ́ ìmọ́lẹ̀ ènìyàn búburú ni a ó pa kúrò, ọ̀wọ́-iná rẹ̀ kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀.
גם אור רשעים ידעך ולא-יגה שביב אשו
6 Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn nínú àgọ́ rẹ̀, fìtílà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni a ó sì pa pẹ̀lú.
אור חשך באהלו ונרו עליו ידעך
7 Ìrìn ẹsẹ̀ agbára rẹ̀ yóò di fífọ; ète òun tìkára rẹ̀ ni yóò bí i ṣubú.
יצרו צעדי אונו ותשליכהו עצתו
8 Nípa ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkára rẹ̀ ó ti bọ́ sínú àwọ̀n, ó sì rìn lórí okùn dídẹ.
כי-שלח ברשת ברגליו ועל-שבכה יתהלך
9 Tàkúté ni yóò mú un ní gìgísẹ̀, àwọn àwọ̀n tí a dẹ yóò sì ṣẹ́gun rẹ̀.
יאחז בעקב פח יחזק עליו צמים
10 A dẹkùn sílẹ̀ fún un lórí ilẹ̀, a sì wà ọ̀fìn fún un lójú ọ̀nà.
טמון בארץ חבלו ומלכדתו עלי נתיב
11 Ẹ̀rù ńlá yóò bà á ní ìhà gbogbo, yóò sì lé e dé ẹsẹ̀ rẹ̀.
סביב בעתהו בלהות והפיצהו לרגליו
12 Àìlera rẹ̀ yóò di púpọ̀ fún ebi, ìparun yóò dìde dúró sí i nígbà tí ó bá ṣubú.
יהי-רעב אנו ואיד נכון לצלעו
13 Yóò jẹ ẹ̀yà ara rẹ̀; ikú àkọ́bí ni yóò jẹ agbára rẹ̀ run.
יאכל בדי עורו יאכל בדיו בכור מות
14 A ó fà á tu kúrò nínú àgọ́ tí ó gbẹ́kẹ̀lé, a ó sì mú un tọ ọba ẹ̀rù ńlá nì lọ.
ינתק מאהלו מבטחו ותצעדהו למלך בלהות
15 Yóò sì máa jókòó nínú àgọ́ rẹ̀ èyí tí í ṣe tirẹ̀; sulfuru ti o jóná ni a ó fún káàkiri ibùgbé rẹ̀.
תשכון באהלו מבלי-לו יזרה על-נוהו גפרית
16 Gbòǹgbò rẹ̀ yóò gbẹ níṣàlẹ̀, a ó sì ké ẹ̀ka rẹ̀ kúrò lókè.
מתחת שרשיו יבשו וממעל ימל קצירו
17 Ìrántí rẹ̀ yóò parun kúrò ni ayé, kì yóò sí orúkọ rẹ̀ ní ìgboro ìlú.
זכרו-אבד מני-ארץ ולא-שם לו על-פני-חוץ
18 A ó sì lé e láti inú ìmọ́lẹ̀ sí inú òkùnkùn, a ó sì lé e kúrò ní ayé.
יהדפהו מאור אל-חשך ומתבל ינדהו
19 Kì yóò ní ọmọ tàbí ọmọ ọmọ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò kù nínú agbo ilé rẹ̀.
לא נין לו ולא-נכד בעמו ואין שריד במגוריו
20 Ẹnu yóò ya àwọn ìran ti ìwọ̀-oòrùn sí ìgbà ọjọ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù ìwárìrì ti í bá àwọn ìran ti ìlà-oòrùn.
על-יומו נשמו אחרנים וקדמנים אחזו שער
21 Nítòótọ́ irú bẹ́ẹ̀ ni ibùgbé àwọn ènìyàn búburú, èyí sì ni ipò ẹni tí kò mọ̀ Ọlọ́run.”
אך-אלה משכנות עול וזה מקום לא-ידע-אל

< Job 18 >