< Job 17 >

1 “Ẹ̀mí mi bàjẹ́, ọjọ́ mi ni a ti gé kúrú, isà òkú dúró dè mí.
רוחי חבלה ימי נזעכו קברים לי
2 Nítòótọ́ àwọn ẹlẹ́yà wà lọ́dọ̀ mi, ojú mi sì tẹ̀mọ́ ìmúnibínú wọn.
אם-לא התלים עמדי ובהמרותם תלן עיני
3 “Fi fún mi Olúwa, ìlérí tí ìwọ fẹ́; ta ni yóò le ṣe ààbò fún mi?
שימה-נא ערבני עמך מי הוא לידי יתקע
4 Nítorí pé ìwọ ti sé wọ́n láyà kúrò nínú òye; nítorí náà ìwọ kì yóò gbé wọn lékè.
כי-לבם צפנת משכל על-כן לא תרמם
5 Ẹni tí ó sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn dídún fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ fún èrè, òun ni ojú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò mú òfo.
לחלק יגיד רעים ועיני בניו תכלנה
6 “Ọlọ́run ti sọ mi di ẹni òwe fún àwọn ènìyàn; níwájú wọn ni mo dàbí ẹni ìtutọ́ sí ní ojú.
והציגני למשל עמים ותפת לפנים אהיה
7 Ojú mí ṣú bàìbàì nítorí ìbìnújẹ́, gbogbo ẹ̀yà ara mi sì dàbí òjìji.
ותכה מכעש עיני ויצרי כצל כלם
8 Àwọn olódodo yóò yanu sí èyí, ẹni aláìṣẹ̀ sì bínú sí àwọn àgàbàgebè.
ישמו ישרים על-זאת ונקי על-חנף יתערר
9 Olódodo pẹ̀lú yóò di ọ̀nà rẹ̀ mú, àti ọlọ́wọ́ mímọ́ yóò máa lera síwájú.
ויאחז צדיק דרכו וטהר-ידים יסיף אמץ
10 “Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti gbogbo yín, ẹ yípadà, kí ẹ si tún padà nísinsin yìí; èmi kò le rí ọlọ́gbọ́n kan nínú yín.
ואולם--כלם תשבו ובאו נא ולא-אמצא בכם חכם
11 Ọjọ́ tí èmi ti kọjá, ìrò mi ti fà yá, àní ìrò ọkàn mi.
ימי עברו זמתי נתקו-- מורשי לבבי
12 Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń ṣọ́ òru di ọ̀sán; wọ́n ní, ìmọ́lẹ̀ súnmọ́ ibi tí òkùnkùn dé.
לילה ליום ישימו אור קרוב מפני-חשך
13 Bí mo tilẹ̀ ní ìrètí, ipò òku ní ilé mi; mo ti tẹ́ ibùsùn mi sínú òkùnkùn. (Sheol h7585)
אם-אקוה שאול ביתי בחשך רפדתי יצועי (Sheol h7585)
14 Èmi ti wí fún ìdíbàjẹ́ pé, ìwọ ni baba mi, àti fún kòkòrò pé, ìwọ ni ìyá mi àti arábìnrin mi,
לשחת קראתי אבי אתה אמי ואחתי לרמה
15 ìrètí mi ha dà nísinsin yìí? Bí ó ṣe ti ìrètí mi ni, ta ni yóò rí i?
ואיה אפו תקותי ותקותי מי ישורנה
16 Yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ipò òkú, nígbà tí a jùmọ̀ sinmi pọ̀ nínú erùpẹ̀ ilẹ̀?” (Sheol h7585)
בדי שאל תרדנה אם-יחד על-עפר נחת (Sheol h7585)

< Job 17 >