< Job 16 >
1 Ìgbà náà ní Jobu dáhùn, ó sì wí pé,
Then Job answered:
2 “Èmi ti gbọ́ irú ohun púpọ̀ bẹ́ẹ̀ rí ayọnilẹ́nu onítùnú ènìyàn ní gbogbo yín.
“I have heard many things like these; miserable comforters are you all.
3 Ọ̀rọ̀ asán lè ni òpin? Tàbí kí ni ó gbó ọ láyà tí ìwọ fi dáhùn?
Is there no end to your long-winded speeches? What provokes you to continue testifying?
4 Èmi pẹ̀lú le sọ bí ẹ̀yin; bí ọkàn yín bá wà ní ipò ọkàn mi, èmi le sọ ọ̀rọ̀ dáradára púpọ̀ sí yín ní ọrùn, èmi a sì mi orí mi sí i yín.
I could also speak like you if you were in my place; I could heap up words against you and shake my head at you.
5 Èmi ìbá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi gbà yín ni ìyànjú, àti ṣíṣí ètè mi ìbá sì tu ìbìnújẹ́ yín.
But I would encourage you with my mouth, and the consolation of my lips would bring relief.
6 “Bí èmi tilẹ̀ sọ̀rọ̀, ìbìnújẹ́ mi kò lọ; bí mo sì tilẹ̀ dákẹ́, níbo ni ìtùnú mí ko kúrò?
Even if I speak, my pain is not relieved, and if I hold back, how will it go away?
7 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó dá mi lágara; ìwọ Ọlọ́run mú gbogbo ẹgbẹ́ mi takété.
Surely He has now exhausted me; You have devastated all my family.
8 Ìwọ fi ìhunjọ kùn mí lára, èyí tí o jẹ́rìí tì mí; àti rírù tí ó hàn lára mi, ó jẹ́rìí tì mí ní ojú.
You have bound me, and it has become a witness; my frailty rises up and testifies against me.
9 Ọlọ́run fi i ìbínú rẹ̀ fà mí ya, ó sì gbóguntì mí; ó pa eyín rẹ̀ keke sí mi, ọ̀tá mi sì gbójú rẹ̀ sí mi.
His anger has torn me and opposed me; He gnashes His teeth at me. My adversary pierces me with His eyes.
10 Wọ́n ti fi ẹnu wọn yẹ̀yẹ́ mi; Wọ́n gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ìgbá ẹ̀gàn; wọ́n kó ara wọn pọ̀ sí mi.
They open their mouths against me and strike my cheeks with contempt; they join together against me.
11 Ọlọ́run ti fi mí lé ọwọ́ ẹni búburú, ó sì mú mi ṣubú sí ọwọ́ ènìyàn ìkà.
God has delivered me to unjust men; He has thrown me to the clutches of the wicked.
12 Mo ti jókòó jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n ó fà mí já; ó sì dì mí ni ọrùn mú, ó sì gbọ̀n mí túútúú, ó sì gbé mi kalẹ̀ láti ṣe àmì ìtafàsí rẹ̀;
I was at ease, but He shattered me; He seized me by the neck and crushed me. He has set me up as His target;
13 àwọn tafàtafà rẹ̀ dúró yí mi káàkiri. Ó là mí láyà pẹ̀rẹ̀, kò si dá sí, ó sì tú òróòro ara mi dà sílẹ̀.
His archers surround me. He pierces my kidneys without mercy and spills my gall on the ground.
14 Ìbàjẹ́ lórí ìbàjẹ́ ní ó fi bà mí jẹ́; ó súré kọlù mi bí jagunjagun.
He breaks me with wound upon wound; He rushes me like a mighty warrior.
15 “Mo rán aṣọ ọ̀fọ̀ bò ara mi, mo sì rẹ̀ ìwo mi sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.
I have sewn sackcloth over my skin; I have buried my horn in the dust.
16 Ojú mi ti pọ́n fún ẹkún, òjìji ikú sì ṣẹ́ sí ìpéǹpéjú mi.
My face is red with weeping, and deep shadows ring my eyes;
17 Kì í ṣe nítorí àìṣòótọ́ kan ní ọwọ́ mi; àdúrà mi sì mọ́ pẹ̀lú.
yet my hands are free of violence and my prayer is pure.
18 “Háà! Ilẹ̀ ayé, ìwọ má ṣe bò ẹ̀jẹ̀ mi, kí ẹkún mi má ṣe wà ní ipò kan.
O earth, do not cover my blood; may my cry for help never be laid to rest.
19 Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi i, ẹlẹ́rìí mi ń bẹ ní ọ̀run, ẹ̀rí mi sì ń bẹ lókè ọ̀run.
Even now my witness is in heaven, and my advocate is on high.
20 Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣẹ̀sín, ṣùgbọ́n ojú mi ń da omijé sọ́dọ̀ Ọlọ́run,
My friends are my scoffers as my eyes pour out tears to God.
21 ìbá ṣe pé ẹnìkan le è máa ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọ́run, bí ènìyàn kan ti í ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì rẹ̀.
Oh, that a man might plead with God as he pleads with his neighbor!
22 “Nítorí nígbà tí iye ọdún díẹ̀ rékọjá tán, nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi tí èmi kì yóò padà bọ̀.”
For when only a few years are past I will go the way of no return.