< Job 14 >

1 “Ènìyàn tí a bí nínú obìnrin, ọlọ́jọ́ díẹ̀ ni, ó sì kún fún ìpọ́njú.
Life is short and full of trouble,
2 Ó jáde wá bí ìtànná ewéko, a sì ké e lulẹ̀; ó sì ń fò lọ bí òjìji, kò sì dúró pẹ́.
like a flower that blooms and withers, like a passing shadow that soon disappears.
3 Ìwọ sì ń síjú rẹ wò irú èyí ni? Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ?
Do you even notice me, God, and why do you have to drag me to court?
4 Ta ni ó lè mú ohun mímọ́ láti inú àìmọ́ jáde wá? Kò sí ẹnìkan!
Who can bring something clean of what is unclean? No one.
5 Ǹjẹ́ a ti pinnu ọjọ́ rẹ̀, iye oṣù rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, ìwọ ti pààlà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní òun kò le kọjá rẹ̀.
You have determined how long we shall live—the number of months, a time limit on our lives.
6 Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè sinmi, títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe.
So leave us alone and give us some peace—so like a laborer we could enjoy a few hours of rest at the end of the day.
7 “Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a bá ké e lulẹ̀, pé yóò sì tún sọ, àti pé ẹ̀ka rẹ̀ tuntun kì yóò gbẹ.
Even a tree that's cut down has the hope of sprouting again, of sending up shoots and continuing to live.
8 Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀, tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀,
Even though its roots grow old in the earth, and its stump dies in the ground,
9 síbẹ̀ nígbà tí ó bá gbóòórùn omi, yóò sọ, yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn.
just a trickle of water will make it bud and grow branches like a young plant.
10 Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù, àní ènìyàn jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́: Òun kò sì sí mọ́.
But human beings die, their strength dwindles away; they perish, and where are they then?
11 “Bí omi ti í tán nínú ipa odò, àti bí odò ṣì tí í fà tí sì gbẹ,
Like water evaporating from a lake and a river that dries up and disappears,
12 bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́; títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́, wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn.
so human beings lie down and don't get up again. Until the heavens cease to exist they will not awake from their sleep.
13 “Háà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò òkú, kí ìwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀, títí ìbínú rẹ yóò fi rékọjá, ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí ó si rántí mi! (Sheol h7585)
I wish you would hide me in Sheol; conceal me there until your anger is gone. Set a definite time for me there, and remember me! (Sheol h7585)
14 Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí? Gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀ fún mi ni èmi dúró dè, títí àmúdọ̀tún mi yóò fi dé.
Will the dead live again? Then I would have hope through all my time of trouble until my release comes.
15 Ìwọ ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn; ìwọ ó sì ní ìfẹ́ sì iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
You would call and I would answer you; you would long for me, the being that you made.
16 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ń kaye ìṣísẹ̀ mi; ìwọ kò fa ọwọ́ rẹ kúrò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi?
Then you would look after me and wouldn't be watching me to see if I sinned.
17 A fi èdìdì di ìrékọjá mi sínú àpò, ìwọ sì rán àìṣedéédéé mi pọ̀.
My sins would be sealed up in a bag and you would cover my guilt.
18 “Àti nítòótọ́ òkè ńlá tí ó ṣubú, ó dasán, a sì ṣí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀.
But just as the mountains crumble and fall, and the rocks tumble down;
19 Omi a máa yinrin òkúta, ìwọ a sì mú omi sàn bo ohun tí ó hù jáde lórí ilẹ̀, ìwọ sì sọ ìrètí ènìyàn dí òfo.
as water wears away the stones, as floods wash away the soil, so you destroy the hope people have.
20 Ìwọ ṣẹ́gun rẹ̀ láéláé, òun sì kọjá lọ! Ìwọ pa awọ ojú rẹ̀ dà, o sì rán an lọ kúrò.
You continually overpower them and they pass away; you distort their faces in death and send them away.
21 Àwọn ọmọ rẹ̀ bọ́ sí ipò ọlá, òun kò sì mọ̀; wọ́n sì rẹ̀ sílẹ̀, òun kò sì kíyèsi i lára wọn.
Their children may become important or fall from their positions, but they don't know or see any of this.
22 Ṣùgbọ́n ẹran-ara rẹ̀ ni yóò rí ìrora ọkàn rẹ̀ ni yóò sì máa ní ìbìnújẹ́ nínú rẹ̀.”
As people die they only know their own pain and are sad for themselves.”

< Job 14 >