< Job 13 >

1 “Wò ó, ojú mi ti rí gbogbo èyí rí, etí mí sì gbọ́, ó sì ti yé mi.
הן כל ראתה עיני שמעה אזני ותבן לה׃
2 Ohun tí ẹ̀yin mọ̀, èmi mọ̀ pẹ̀lú, èmi kò kéré sí i yin.
כדעתכם ידעתי גם אני לא נפל אנכי מכם׃
3 Nítòótọ́ èmi ó bá Olódùmarè sọ̀rọ̀, èmi sì ń fẹ́ bá Ọlọ́run sọ àsọyé.
אולם אני אל שדי אדבר והוכח אל אל אחפץ׃
4 Ẹ̀yin fi irọ́ bá mi sọ̀rọ̀, oníṣègùn lásán ni gbogbo yín.
ואולם אתם טפלי שקר רפאי אלל כלכם׃
5 Háà! ẹ̀yin kì bá kúkú dákẹ́! Èyí ni kì bá sì ṣe ọgbọ́n yín.
מי יתן החרש תחרישון ותהי לכם לחכמה׃
6 Ẹ gbọ́ àwíyé mi nísinsin yìí; ẹ sì fetísílẹ̀ sí àròyé ẹnu mi.
שמעו נא תוכחתי ורבות שפתי הקשיבו׃
7 Ẹ̀yin fẹ́ sọ ìsọkúsọ fún Ọlọ́run? Ki ẹ sì fi ẹ̀tàn sọ̀rọ̀ gbè é?
הלאל תדברו עולה ולו תדברו רמיה׃
8 Ẹ̀yin fẹ́ ṣe ojúsàájú rẹ̀? Ẹ̀yin fẹ́ gbèjà fún Ọlọ́run?
הפניו תשאון אם לאל תריבון׃
9 Ó ha dára to tí yóò hú àṣírí yín síta, tàbí kí ẹ̀yin tàn án bí ẹnìkan ti í tan ẹnìkejì?
הטוב כי יחקר אתכם אם כהתל באנוש תהתלו בו׃
10 Yóò máa bá yín wí nítòótọ́, bí ẹ̀yin bá ṣe ojúsàájú ènìyàn níkọ̀kọ̀.
הוכח יוכיח אתכם אם בסתר פנים תשאון׃
11 Ìwà ọlá rẹ̀ kì yóò bà yín lẹ́rù bí? Ìpayà rẹ̀ kì yóò pá yín láyà?
הלא שאתו תבעת אתכם ופחדו יפל עליכם׃
12 Àwọn òwe yín dàbí eérú, bẹ́ẹ̀ ni àwọn odi ìlú yin dàbí amọ̀.
זכרניכם משלי אפר לגבי חמר גביכם׃
13 “Ẹ pa ẹnu yín mọ́ kúrò lára mi, kí èmi kí ó lè sọ̀rọ̀, ki ohun tí ń bọ̀ wá í bá mi, le è máa bọ̀.
החרישו ממני ואדברה אני ויעבר עלי מה׃
14 Ǹjẹ́ nítorí kí ni èmi ṣe ń fi eyín mi bu ẹran-ara mi jẹ, tí mo sì gbé ẹ̀mí mi lé ara mi lọ́wọ́?
על מה אשא בשרי בשני ונפשי אשים בכפי׃
15 Bí ó tilẹ̀ pa mí, síbẹ̀ èmi ó máa gbẹ́kẹ̀lé e, èmi ó máa tẹnumọ́ ọ̀nà mi níwájú rẹ̀.
הן יקטלני לא איחל אך דרכי אל פניו אוכיח׃
16 Èyí ni yóò sì ṣe ìgbàlà mi, àgàbàgebè kì yóò wá síwájú rẹ̀.
גם הוא לי לישועה כי לא לפניו חנף יבוא׃
17 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi ní ìfarabalẹ̀, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mí dún ni etí yín.
שמעו שמוע מלתי ואחותי באזניכם׃
18 Wò ó nísinsin yìí, èmi ti mura ọ̀ràn mi sílẹ̀; èmi mọ̀ pé a ó dá mi láre.
הנה נא ערכתי משפט ידעתי כי אני אצדק׃
19 Ta ni òun ti yóò bá mi ṣàròyé? Ǹjẹ́ nísinsin yìí, èmi fẹ́ pa ẹnu mi mọ́, èmi ó sì jọ̀wọ́ ẹ̀mí mi lọ́wọ́.
מי הוא יריב עמדי כי עתה אחריש ואגוע׃
20 “Ṣùgbọ́n, má ṣe ṣe ohun méjì yìí sí mi, nígbà náà ni èmi kì yóò sì fi ara mi pamọ́ kúrò fún ọ.
אך שתים אל תעש עמדי אז מפניך לא אסתר׃
21 Fa ọwọ́ rẹ sẹ́yìn kúrò lára mi, má sì jẹ́ kí ẹ̀rù rẹ kí ó pá mi láyà.
כפך מעלי הרחק ואמתך אל תבעתני׃
22 Nígbà náà ni kí ìwọ kí ó pè, èmi o sì dáhùn, tàbí jẹ́ kí ń máa sọ̀rọ̀, ki ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.
וקרא ואנכי אענה או אדבר והשיבני׃
23 Mélòó ní àìṣedéédéé àti ẹ̀ṣẹ̀ mi? Mú mi mọ̀ ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ mi.
כמה לי עונות וחטאות פשעי וחטאתי הדיעני׃
24 Nítorí kí ni ìwọ ṣe pa ojú rẹ mọ́, tí o sì yàn mí ní ọ̀tá rẹ?
למה פניך תסתיר ותחשבני לאויב לך׃
25 Ìwọ ó fa ewé ti afẹ́fẹ́ ń fẹ́ síyìn-ín sọ́hùn-ún ya bi? Ìwọ a sì máa lépa ìyàngbò?
העלה נדף תערוץ ואת קש יבש תרדף׃
26 Nítorí pé ìwọ kọ̀wé ohun kíkorò sí mi, o sì mú mi jogún àìṣedéédéé èwe mi.
כי תכתב עלי מררות ותורישני עונות נעורי׃
27 Ìwọ kàn àbà mọ́ mi lẹ́sẹ̀ pẹ̀lú, ìwọ sì ń wò ipa ọ̀nà ìrìn mi ní àwòfín; nípa fífi ìlà yí gígísẹ̀ mi ká.
ותשם בסד רגלי ותשמור כל ארחותי על שרשי רגלי תתחקה׃
28 “Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn ń ṣègbé bí ohun ìdíbàjẹ́, bi aṣọ tí kòkòrò jẹ.
והוא כרקב יבלה כבגד אכלו עש׃

< Job 13 >