< Job 12 >
1 Jobu sì dáhùn, ó sì wí pé,
2 “Kò sí àní àní níbẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni àwọn ènìyàn náà, ọgbọ́n yóò sì kú pẹ̀lú yín!
3 Ṣùgbọ́n èmi ní ìyè nínú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin; èmi kò kéré sí i yín. Àní, ta ni kò mọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí?
4 “Èmi dàbí ẹni tí a ń fi ṣe ẹlẹ́yà lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, tí ó ké pe Ọlọ́run, tí ó sì dá a lóhùn, à ń fi olóòtítọ́ ẹni ìdúró ṣinṣin rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà!
5 Ó rọrùn fún ènìyàn láti fi ìbànújẹ́ ẹlòmíràn ṣe ẹlẹ́yà gẹ́gẹ́ bí ìpín àwọn ẹni tí ẹsẹ̀ wọn ṣetán láti yọ̀.
6 Àgọ́ àwọn ìgárá ọlọ́ṣà wá láìní ìbẹ̀rù; àwọn tí ó sì ń mú Ọlọ́run bínú wà láìléwu, àwọn ẹni tí ó sì gbá òrìṣà mú ní ọwọ́ wọn.
7 “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí bí àwọn ẹranko léèrè, wọn o kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, wọn ó sì sọ fún ọ.
8 Tàbí ba ilẹ̀ ayé sọ̀rọ̀, yóò sì kọ́ ọ, àwọn ẹja inú òkun yóò sì sọ fún ọ.
9 Ta ni kò mọ̀ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí pé, ọwọ́ Olúwa ni ó ṣe nǹkan yìí?
10 Ní ọwọ́ ẹni tí ẹ̀mí ohun alààyè gbogbo gbé wà, àti ẹ̀mí gbogbo aráyé.
11 Etí kì í dán ọ̀rọ̀ wò bí tàbí adùn ẹnu kì í sì í tọ́ oúnjẹ rẹ̀ wò bí?
12 Àwọn arúgbó ni ọgbọ́n wà fún, àti nínú gígùn ọjọ́ ni òye.
13 “Ti Ọlọ́run ni ọgbọ́n àti agbára; òun ló ni ìmọ̀ àti òye.
14 Kíyèsi i, ó bì wó, a kò sì lè gbe ró mọ́; Ó sé ènìyàn mọ́, kò sì sí ìtúsílẹ̀ kan.
15 Kíyèsi i, ó dá àwọn omi dúró, wọ́n sì gbẹ; Ó sì rán wọn jáde, wọ́n sì ṣẹ̀ bo ilẹ̀ ayé yípo.
16 Tìrẹ ni agbára àti ìṣẹ́gun; ẹni tí ń ṣìnà àti ẹni tí ń mú ni ṣìnà, tirẹ̀ ni wọ́n ń ṣe.
17 Ó mú àwọn ìgbìmọ̀ lọ ní ìhòhò a sì sọ àwọn onídàájọ́ di òmùgọ̀.
18 Ó tú ìdè ọba ó sì fi àmùrè gbà wọ́n ní ọ̀já.
19 Ó mú àwọn àlùfáà lọ ní ìhòhò ó sì tẹ orí àwọn alágbára ba.
20 Ó mú ọ̀rọ̀ ẹnu ẹni ìgbẹ́kẹ̀lé kúrò ó sì ra àwọn àgbàgbà ní iyè.
21 Ó bu ẹ̀gàn lu àwọn ọmọ ọlọ́lá ó sì tú àmùrè àwọn alágbára.
22 Ó hú ìdí ohun ìjìnlẹ̀ jáde láti inú òkùnkùn wá ó sì mú òjìji ikú wá sínú ìmọ́lẹ̀.
23 Òun a mú orílẹ̀-èdè bí sí i, a sì run wọ́n; òun a sọ orílẹ̀-èdè di ńlá, a sì tún ṣẹ̀ wọn kù.
24 Òun a gba òye àwọn olórí àwọn ènìyàn aráyé, a sì máa mú wọn rin kiri nínú ijù níbi tí ọ̀nà kò sí.
25 Wọn a máa fi ọwọ́ ta ilẹ̀ nínú òkùnkùn níbi tí kò sí ìmọ́lẹ̀; òun a sì máa mú ìrìn ìsìn wọn bí ọ̀mùtí.