< Job 1 >
1 Ọkùnrin kan wà ní ilẹ̀ Usi, orúkọ ẹni tí í jẹ́ Jobu; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́, ó dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó kórìíra ìwà búburú.
乌斯地有一个人名叫约伯;那人完全正直,敬畏 神,远离恶事。
2 A sì bi ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta fún un.
他生了七个儿子,三个女儿。
3 Ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin àgùntàn, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ìbákasẹ, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì pọ̀; bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin yìí sì pọ̀jù gbogbo àwọn ará ìlà-oòrùn lọ.
他的家产有七千羊,三千骆驼,五百对牛,五百母驴,并有许多仆婢。这人在东方人中就为至大。
4 Àwọn ọmọ rẹ̀ a sì máa lọ í jẹun àsè nínú ilé ara wọn, olúkúlùkù ní ọjọ́ rẹ̀; wọn a sì máa ránṣẹ́ pé arábìnrin wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti jẹun àti láti pẹ̀lú wọn.
他的儿子按着日子各在自己家里设摆筵宴,就打发人去,请了他们的三个姊妹来,与他们一同吃喝。
5 Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ àsè wọn pé yíká, ni Jobu ránṣẹ́ lọ í yà wọ́n sí mímọ́, ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì rú ẹbọ sísun níwọ̀n iye gbogbo wọn; nítorí tí Jobu wí pé: bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣọpẹ́ fún Ọlọ́run lọ́kàn wọn. Bẹ́ẹ̀ ní Jobu máa ń ṣe nígbà gbogbo.
筵宴的日子过了,约伯打发人去叫他们自洁。他清早起来,按着他们众人的数目献燔祭;因为他说:“恐怕我儿子犯了罪,心中弃掉 神。”约伯常常这样行。
6 Ǹjẹ́ ó di ọjọ́ kan, nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá í pé níwájú Olúwa, Satani sì wá pẹ̀lú wọn.
有一天, 神的众子来侍立在耶和华面前,撒但也来在其中。
7 Olúwa sì bi Satani wí pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Nígbà náà ní Satani dá Olúwa lóhùn wí pé, “Ní ìlọsíwá-sẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.”
耶和华问撒但说:“你从哪里来?”撒但回答说:“我从地上走来走去,往返而来。”
8 Olúwa sì sọ fún Satani pé, “Ìwọ ha kíyèsi Jobu ìránṣẹ́ mi, pé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí í ṣe olóòtítọ́, tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti ó sì kórìíra ìwà búburú.”
耶和华问撒但说:“你曾用心察看我的仆人约伯没有?地上再没有人像他完全正直,敬畏 神,远离恶事。”
9 Nígbà náà ni Satani dá Olúwa lóhùn wí pé, “Jobu ha bẹ̀rù Ọlọ́run ní asán bí?”
撒但回答耶和华说:“约伯敬畏 神,岂是无故呢?
10 “Ìwọ kò ha ti ṣọgbà yìí ká, àti yí ilé rẹ̀ àti yí ohun tí ó ní ká, ní ìhà gbogbo? Ìwọ bùsi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì ń pọ̀ si ní ilẹ̀.
你岂不是四面圈上篱笆围护他和他的家,并他一切所有的吗?他手所做的都蒙你赐福;他的家产也在地上增多。
11 Ǹjẹ́, nawọ́ rẹ nísinsin yìí, kí ó sì fi tọ́ ohun gbogbo tí ó ni; bí kì yóò sì bọ́hùn ni ojú rẹ.”
你且伸手毁他一切所有的;他必当面弃掉你。”
12 Olúwa sì dá Satani lóhùn wí pé, “Kíyèsi i, ohun gbogbo tí ó ní ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, kìkì òun tìkára rẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ rẹ kàn.” Bẹ́ẹ̀ ni Satani jáde lọ kúrò níwájú Olúwa.
耶和华对撒但说:“凡他所有的都在你手中;只是不可伸手加害于他。”于是撒但从耶和华面前退去。
13 Ó sì di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin, tí wọ́n mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n wọn ọkùnrin,
有一天,约伯的儿女正在他们长兄的家里吃饭喝酒,
14 oníṣẹ́ kan sì tọ Jobu wá wí pé, “Àwọn ọ̀dá màlúù ń tulẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹ ní ẹ̀gbẹ́ wọn,
有报信的来见约伯,说:“牛正耕地,驴在旁边吃草,
15 àwọn ará Sabeani sì kọlù wọ́n, wọ́n sì ń kó wọn lọ pẹ̀lú, wọ́n ti fi idà sá àwọn ìránṣẹ́ pa, èmi nìkan ṣoṣo ní ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ.”
示巴人忽然闯来,把牲畜掳去,并用刀杀了仆人;惟有我一人逃脱,来报信给你。”
16 Bí ó ti ń sọ ní ẹnu; ẹnìkan dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé, “Iná ńlá Ọlọ́run ti ọ̀run bọ́ sí ilẹ̀, ó sì jó àwọn àgùntàn àti àwọn ìránṣẹ́; èmi nìkan ṣoṣo ní ó sálà láti ròyìn fún ọ.”
他还说话的时候,又有人来说:“神从天上降下火来,将群羊和仆人都烧灭了;惟有我一人逃脱,来报信给你。”
17 Bí ó sì ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan sì dé pẹ̀lú tí ó wí pé, “Àwọn ará Kaldea píngun sí ọ̀nà mẹ́ta, wọ́n sì kọlù àwọn ìbákasẹ, wọ́n sì kó wọn lọ, pẹ̀lúpẹ̀lú wọ́n sì fi idà sá àwọn ìránṣẹ́ pa; èmi nìkan ṣoṣo ni ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ!”
他还说话的时候,又有人来说:“迦勒底人分作三队忽然闯来,把骆驼掳去,并用刀杀了仆人;惟有我一人逃脱,来报信给你。”
18 Bí ó ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin ń jẹ, wọ́n ń mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n.
他还说话的时候,又有人来说:“你的儿女正在他们长兄的家里吃饭喝酒,
19 Sì kíyèsi i, ẹ̀fúùfù ńlá ńlá ti ìhà ijù fẹ́ wá kọlu igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilé, ó sì wó lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà, wọ́n sì kú, èmi nìkan ṣoṣo ni ó yọ láti ròyìn fún ọ.
不料,有狂风从旷野刮来,击打房屋的四角,房屋倒塌在少年人身上,他们就都死了;惟有我一人逃脱,来报信给你。”
20 Nígbà náà ni Jobu dìde, ó sì fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, ó sì fá orí rẹ̀ ó wólẹ̀ ó sì gbàdúrà
约伯便起来,撕裂外袍,剃了头,伏在地上下拜,
21 wí pé, “Ní ìhòhò ní mo ti inú ìyá mi jáde wá, ni ìhòhò ní èmi yóò sì tún padà lọ. Olúwa fi fún ni, Olúwa sì gbà á lọ, ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa.”
说:“我赤身出于母胎,也必赤身归回;赏赐的是耶和华,收取的也是耶和华。耶和华的名是应当称颂的。”
22 Nínú gbogbo èyí Jobu kò ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi òmùgọ̀ pe Ọlọ́run lẹ́jọ́.
在这一切的事上约伯并不犯罪,也不以 神为愚妄。