< Jeremiah 52 >
1 Sedekiah jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó jẹ ọba. Ọdún mọ́kànlá ló fi jẹ ọba ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali ọmọ Jeremiah; láti Libina ló ti wá.
2 Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa gẹ́gẹ́ bí Jehoiakimu ti ṣe.
3 Nítorí ìbínú Olúwa ni gbogbo èyí ṣe ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu àti Juda àti ní ìkẹyìn. Ó sì gbà wọ́n gbọ́ ní iwájú rẹ̀. Sedekiah ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babeli.
4 Nígbà tí ó di ọdún kẹsànán ti Sedekiah tí ń ṣe ìjọba ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù kẹwàá Nebukadnessari ọba Babeli sì lọ sí Jerusalẹmu pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, wọ́n pàgọ́ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà; wọ́n sì mọ odi yíká rẹ̀.
5 Ìlú náà sì wá lábẹ́ ìhámọ́ títí di ọdún kọkànlá ọba Sedekiah.
6 Ní ọjọ́ kẹsànán, oṣù mẹ́rin ìyàn ìlú náà sì ti burú dé ibi pé kò sí oúnjẹ kankan mọ́ fún àwọn ènìyàn láti jẹ.
7 Bákan náà, odi ìlú náà ti ya àwọn ọmọ-ogun sì tí sálọ. Wọn fi ìlú náà sílẹ̀ ní òru nípa ojú ọ̀nà tó wà láàrín odi méjèèjì lẹ́bàá ọgbà ọba. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, àwọn ará Babeli yìí yí ìlú náà ká. Wọ́n sá gba aginjù lọ.
8 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ogun Babeli lépa ọba Sedekiah wọ́n sì le bá ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun sì pínyà, kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ wọ́n sì túká.
9 Wọ́n sì mu ní ìgbèkùn. Wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli, ní Ribla ní ilẹ̀ Hamati níbẹ̀ ni ó ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀.
10 Ní Ribla ni ọba Babeli ti pa ọmọkùnrin Sedekiah lójú rẹ̀; ó sì tún pa gbogbo àwọn aláṣẹ Juda.
11 Lẹ́yìn náà, ọba Babeli yọ Sedekiah ní ojú, o sì fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì gbe e lọ sí Babeli níbi tí ó ti fi sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.
12 Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù karùn-ún, tí ó jẹ́ ọdún kọkàndínlógún Nebukadnessari ọba Babeli, ni Nebusaradani balógun ìṣọ́ wá sí Jerusalẹmu.
13 Ó dáná sun pẹpẹ Olúwa, ààfin ọba àti gbogbo àwọn ilé Jerusalẹmu. Ó sì dáná sun gbogbo àwọn ilé ńlá ńlá.
14 Gbogbo àwọn ogun Babeli, tí ó wà lọ́dọ̀ olórí ẹ̀ṣọ́, wó ògiri tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀.
15 Nebusaradani balógun ìṣọ́ kó gbogbo àwọn tálákà àti gbogbo àwọn tí ó kù ní ìlú, ní ìgbèkùn lọ sí Babeli, pẹ̀lú àwọn tí ó ya lọ, tí ó sì ya tọ ọba Babeli lọ, àti ìyókù àwọn ènìyàn náà.
16 Ṣùgbọ́n Nebusaradani, balógun ìṣọ́ fi àwọn tálákà tó kú ní ilẹ̀ náà sílẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà àti ro oko.
17 Àwọn ará Babeli fọ́ ọ̀wọ̀n idẹ wọ̀n-ọn-nì àti àwọn ìjókòó wọ̀n-ọn-nì, àti agbada idẹ títóbi wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ilé Olúwa, àwọn ará Babeli fọ́ túútúú, wọ́n sì kó gbogbo idẹ náà lọ sí Babeli.
18 Bákan náà, wọ́n tún kó àwọn ìkòkò wọ̀n-ọn-nì, ọkọ́ wọ̀n-ọn-nì àti ọ̀pá fìtílà wọ̀n-ọn-nì, àwọn ọpọ́n wọ̀n-ọn-nì, ṣíbí wọ̀n-ọn-nì àti gbogbo ohun èlò idẹ tí wọ́n ń lò níbi pẹpẹ lọ.
19 Balógun ìṣọ́ náà kó àwokòtò wọ̀n-ọn-nì, ohun ìfọnná wọ̀n-ọn-nì, ọpọ́n wọ̀n-ọn-nì, ìkòkò wọ̀n-ọn-nì, ọ̀pá fìtílà wọ̀n-ọn-nì, ṣíbí wọ̀n-ọn-nì àti ago wáìnì wọ̀n-ọn-nì; èyí tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe lọ.
20 Àwọn ọ̀wọ́n méjì, agbada ńlá kan àti àwọn màlúù idẹ méjìlá tí ó wà lábẹ́ ìjókòó alágbéká tí Solomoni ọba ṣe fún ilé Olúwa, idẹ ni gbogbo ohun èlò wọ̀nyí, ó ju èyí tí a lè wọ́n lọ.
21 Ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọ̀wọ́n yìí ni ga ní ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlógún; okùn ìgbọ̀nwọ́ méjìlá sì yí i ká. Ọ̀kọ̀ọ̀kan nípọn tó ìka mẹ́rin, wọ́n sì ní ihò nínú.
22 Ọ̀nà orí idẹ kan tó ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga, wọ́n sì fi èso pomegiranate ṣe ọ̀ṣọ́ sí i lára yíká. Ọ̀wọ́n kejì sì wà pẹ̀lú èso pomegiranate tí ó jọra.
23 Pomegiranate mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún ni ó wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àpapọ̀ gbogbo pomegiranate sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún kan.
24 Balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ mu Seraiah olórí àwọn àlùfáà àti Sefaniah àlùfáà kejì àti àwọn olùṣọ́ ìloro mẹ́ta.
25 Nínú àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, ó mú ìwẹ̀fà kan, tí ó wà ní ìtọ́jú àwọn ológun, àti àwọn olùdámọ̀ràn ọba méje. Bákan náà, ó tún mu akọ̀wé olórí ogun tí ó wà ní ìtọ́jú títo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọgọ́ta nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú náà.
26 Nebusaradani, balógun ìṣọ́ kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn tọ ọba Babeli wá ní Ribla.
27 Ọba Babeli sì kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n ní Ribla ni ilẹ̀ Hamati. Báyìí ni a mú Juda kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.
28 Èyí ni iye àwọn ènìyàn tí Nebukadnessari kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì. Ní ọdún keje ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé mẹ́tàlélógún ará Juda.
29 Ní ọdún kejìdínlógún Nebukadnessari o kó ẹgbẹ̀rin ó lé méjìlélọ́gbọ̀n láti Jerusalẹmu.
30 Ní ọdún kẹtàlélógún àwọn Júù tí Nebusaradani kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín márùn-ún. Gbogbo ènìyàn tí ó kó lápapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀tàlélógún.
31 Ní ọdún kẹtàdínlógójì ti Jehoiakini ọba Juda ni Efili-Merodaki di ọba Babeli. Ó gbé orí Jehoiakini ọba Juda sókè, ó sì tú sílẹ̀ nínú túbú ní ọjọ́ kẹẹdọ́gbọ̀n oṣù kejìlá.
32 Ó ń sọ̀rọ̀ rere fún un, ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ìtẹ́ àwọn ọba tókù lọ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Babeli.
33 Nítorí náà, Jehoiakini pàrọ̀ aṣọ túbú rẹ̀, ó sì ń jẹun ní gbogbo ìgbà ní iwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
34 Ní ojoojúmọ́ ni ọba Babeli ń fún Jehoiakini ní ìpín tirẹ̀ bí ó tí ń bẹ láààyè, títí di ọjọ́ kú rẹ̀.