< Jeremiah 50 >
1 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa fi sẹ́nu wòlíì Jeremiah láti sọ fún ará ilẹ̀ Babeli:
This is the word that Yahweh declared about Babylon, the land of the Chaldeans, by the hand of Jeremiah the prophet,
2 “Ẹ sọ ọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ sì kéde, kí ẹ sì gbé àsíá sókè, ẹ kéde rẹ̀ ẹ má sì ṣe bò ó, wí pé, ‘A kó Babeli, ojú tí Beli, a fọ́ Merodaki túútúú, ojú ti àwọn ère rẹ̀, a fọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀ túútúú.’
“Report to the nations and cause them to listen. Lift up a signal and cause them to listen. Do not conceal it. Say, 'Babylon is taken. Bel is made ashamed. Marduk is dismayed. Its idols are put to shame; its images are dismayed.'
3 Àwọn ìlú ní apá àríwá yóò sì máa gbóguntì wọ́n. Gbogbo àwọn ènìyàn àti ẹranko ni yóò sá kúrò ní ìlú yìí.
A nation from the north will arise against it, and make her land a desolation. No one will live in it; both man and beast will flee away.
4 “Ní ọjọ́ wọ̀nyí àti ní àkókò náà,” ni Olúwa wí, “Àwọn ọmọ Israẹli yóò jùmọ̀ wá, àwọn, àti àwọn ọmọ Juda, wọn yóò lọ pẹ̀lú ẹkún láti ṣàfẹ́rí Olúwa Ọlọ́run wọn.
In those days and at that time—this is Yahweh's declaration—the people of Israel and the people of Judah will come together to go with weeping and seek Yahweh their God.
5 Wọn ó máa béèrè ọ̀nà Sioni, ojú wọn yóò sì yí síhà ibẹ̀, wí pé ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a darapọ̀ mọ́ Olúwa ní májẹ̀mú ayérayé, tí a kì yóò gbàgbé.
They will ask the way to Zion and will set off toward it, saying, We will go and join ourselves to Yahweh in an everlasting covenant that will not be forgotten.”
6 “Àwọn ènìyàn mi ti jẹ́ àgùntàn tí ó sọnù, àwọn olùṣọ́-àgùntàn wọn ti jẹ́ kí wọn ṣìnà, wọ́n ti jẹ́ kí wọn rìn lórí òkè wọ́n ti lọ láti orí òkè ńlá dé òkè kékeré, wọn ti gbàgbé ibùsùn wọn.
My people have been a lost flock. Their shepherds have led them astray in the mountains; they have turned them around from hill to hill. They went, they forgot the place where they had lived.
7 Gbogbo àwọn tí ó rí wọn, ti pa wọ́n jẹ àwọn ọ̀tá wọ́n sì wí pé, ‘Àwa kò jẹ̀bi nítorí pé wọ́n ti ṣẹ̀ sí Olúwa ibùgbé òdodo àti ìrètí àwọn baba wọn.’
Everyone who went out to them devoured them. Their adversaries said, 'We are not guilty, because they sinned against Yahweh, their true home—Yahweh, the hope of their ancestors.'
8 “Jáde kúrò ní Babeli, ẹ fi ilẹ̀ àwọn ará Kaldea sílẹ̀, kí ẹ sì jẹ́ bí òbúkọ níwájú agbo ẹran.
Leave from the midst of Babylon; go out from the land of the Chaldeans; be like male goats that leave before the rest of the flock does.
9 Nítorí pé èmi yóò ru, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò gbé sókè sí Babeli àwọn orílẹ̀-èdè ńlá láti ilẹ̀ àríwá. Wọn yóò gba àyà wọn lẹ́gbẹ́ rẹ̀; láti àríwá wá, à ó sì mú ọ. Ọfà wọn yóò dàbí ọfà àwọn akọni akíkanjú tí wọn kì í wà lọ́wọ́ òfo.
For see, I am about to set in motion and raise up a group of great nations from the north against Babylon. They will arrange themselves against her. Babylon will be captured from there. Their arrows are like a skilled warrior who does not return empty-handed.
10 A ó dààmú Babeli, gbogbo àwọn tó dààmú rẹ yóò sì mú ìfẹ́ wọn ṣẹ,” ni Olúwa wí.
Chaldea will become plunder. All those who plunder it will be satisfied—this is Yahweh's declaration.
11 “Nítorí pé inú yín dùn nítorí pé ẹ̀yìn yọ̀, ẹ̀yìn olè tí ó jí ìní mi, nítorí tí ẹ̀yìn fi ayọ̀ fò bí ẹgbọrọ abo màlúù sí koríko tútù, ẹ sì ń yan bí akọ ẹṣin.
You rejoice, you celebrate the plundering of my inheritance; you jump around like a calf stamping in its pasture; you neigh like a powerful horse.
12 Ojú yóò ti ìyá rẹ, ẹni tí ó bí ọ yóò sì gba ìtìjú. Òun ni yóò jẹ́ kékeré jù nínú àwọn orílẹ̀-èdè, ilẹ̀ aṣálẹ̀ àti aginjù tí kò lọ́ràá.
So your mother will be greatly ashamed; the one who bore you will be embarrassed. See, she will be the least of nations, a wilderness, a dry land, and a desert.
13 Nítorí ìbínú Olúwa, kì yóò ní olùgbé; ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú rẹ̀. Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá ni Babeli yóò fi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ọgbẹ́ rẹ̀.
Because of Yahweh's anger, Babylon will not be inhabited, but will be a complete devastation. Everyone who passes by will shudder because of Babylon and will hiss because all of its wounds.
14 “Dúró sí ààyè rẹ ìwọ Babeli àti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ n ta ọfà náà. Ẹ ta ọfà náà sí i, nítorí ó ti ṣẹ̀ sí Olúwa.
Arrange yourselves against Babylon all around her. Everyone who bends a bow must shoot at her. Do not keep back any of your arrows, for she has sinned against Yahweh.
15 Kígbe mọ́ ọn ní gbogbo ọ̀nà! Ó tẹríba, òpó rẹ̀ sì yẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ wí pé èyí ni ìgbẹ̀san Olúwa, gbẹ̀san lára rẹ̀. Ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn.
Raise a shout against her all around! She has surrendered; her towers have fallen; her walls are torn down, for this is Yahweh's vengeance. Take vengeance on her! Do to her just as she has done!
16 Ké afúnrúgbìn kúrò ní Babeli, àti ẹni tí ń di dòjé mú ní igà ìkórè! Nítorí idà àwọn aninilára jẹ́ kí oníkálùkù padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, kí oníkálùkù sì sá padà sí ilẹ̀ rẹ̀.
Destroy both the farmer who sows seed and the one who uses a sickle at the time of harvest in Babylon. Let each person turn back to his own people from the oppressor's sword; let them flee to their own land.
17 “Israẹli jẹ́ àgùntàn tí ó ṣìnà kiri, kìnnìún sì ti lé e lọ. Níṣàájú ọba Asiria pa á jẹ, àti níkẹyìn yìí Nebukadnessari ọba Babeli fa egungun rẹ̀ ya.”
Israel is a sheep scattered and driven away by lions. First the king of Assyria devoured him; then after this, Nebuchadnezzar king of Babylon broke his bones.
18 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára, Ọlọ́run Israẹli wí, “Ǹ ó fi ìyà jẹ ọba Babeli àti ilẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fìyà jẹ ọba, Asiria.
Therefore Yahweh of hosts, the God of Israel, says this: See, I am about to punish the king of Babylon and his land, just as I punished the king of Assyria.
19 Ṣùgbọ́n, èmi yóò mú Israẹli padà wá pápá oko tútù rẹ̀ òun yóò sì máa bọ́ ara rẹ̀ lórí Karmeli àti Baṣani, a ó sì tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ní òkè Efraimu àti ní Gileadi.
I will restore Israel to his homeland; he will graze on Carmel and Bashan. Then he will be satisfied in the hill country of Ephraim and Gilead.
20 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,” ni Olúwa wí, “À ó wá àìṣedéédéé ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli, ṣùgbọ́n a ki yóò rí ohun; àti ẹ̀ṣẹ̀ Juda ni a ki yóò sì rí mọ kankan nítorí èmi yóò dáríjì àwọn tí ó ṣẹ́kù tí mo dá sí.
In those days and at that time, says Yahweh, iniquity will be looked for in Israel, but none will be found. I will inquire about the sins of Judah, but none will be found, for I will forgive the remnant that I spare.”
21 “Kọlu ilẹ̀ Merataimu àti àwọn tí ó ń gbé ní Pekodi. Lépa rẹ pa, kí o sì parun pátápátá,” ni Olúwa wí, “Ṣe gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún ọ.
“Arise against the land of Merathaim, against it and the ones inhabiting Pekod. Put them to the sword and set them apart for destruction—this is Yahweh's declaration—do everything that I am commanding you.
22 Ariwo ogun wà ní ilẹ̀ náà ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìparun ńlá.
The sounds of battle and enormous destruction are in the land.
23 Báwo ni ó ṣe fọ́, tí ó sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ tó, lọ́wọ́ òòlù gbogbo ayé! Báwo ní Babeli ti di ahoro ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè.
How the hammer of all the lands has been cut apart and destroyed. How Babylon has become a destroyed place among the nations.
24 Mo dẹ pàkúté sílẹ̀ fún ọ ìwọ Babeli, kí o sì tó mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, o ti kó sínú rẹ̀. A mú ọ nítorí pé o tako Olúwa.
I have set a trap for you and you were taken, Babylon, and you did not know it! You were found and captured, because you opposed Yahweh.
25 Olúwa ti kó àwọn ohun èlò ìjà rẹ̀ jáde, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun ti ṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ Babeli.
Yahweh has opened his armory and is bringing out the weapons for carrying out his anger. There is work for the Lord Yahweh of hosts in the land of the Chaldeans.
26 Ẹ wá sórí rẹ̀ láti òpin gbogbo, sí ilé ìṣúra rẹ̀ sílẹ̀, ẹ kó o jọ bí òkìtì ọkà, kí ẹ sì yà á sọ́tọ̀ fún ìparun, ẹ má ṣe fí yòókù sílẹ̀ fún un.
Attack her from far away. Open her granaries and pile her up like heaps of grain. Set her apart for destruction. Leave no remnant of her.
27 Pa gbogbo àwọn akọ màlúù rẹ, jẹ́ kí a kó wọn lọ ibi tí a ó ti pa wọ́n! Ègbé ní fún wọn! Nítorí ọjọ́ wọn dé, àkókò ìbẹ̀wò wọn.
Kill all her bulls. Send them down to the place of slaughter. Woe to them, for their day has come—the time for their punishment.
28 Gbọ́ ohùn àwọn tí ó sálọ, tí ó sì sálà láti Babeli wá, sì sọ ní Sioni, bí Olúwa Ọlọ́run wa ti gbẹ̀san, ẹ̀san fún tẹmpili rẹ̀.
There is the sound of those fleeing, of those who are survivors, from the land of Babylon. These will report the vengeance of Yahweh our God for Zion, and vengeance for his temple.”
29 “Pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àní gbogbo tafàtafà, sórí Babeli, ẹ dó tí ì yíkákiri, ma jẹ́ ki ẹnikẹ́ni sálà. Sán fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí ó ti ṣe, ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ sí i, nítorí tí ó ti gbéraga sí Olúwa, sí Ẹni Mímọ́ Israẹli.
“Summon the archers against Babylon—all those who bend their bows. Camp against her, and let no one escape. Repay her for what she has done. Do to her by the measure she has used. For she had defied Yahweh, the Holy One of Israel.
30 Nítorí náà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ yóò ṣubú ní ìgboro, a ó sì pa àwọn ológun lẹ́nu mọ́,” ní Olúwa wí.
So her young men will fall in the city squares, and all her fighting men will be destroyed on that day —this is Yahweh's declaration.”
31 “Wò ó, èmi yóò dojú kọ ọ́ ìwọ agbéraga,” ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “nítorí ọjọ́ rẹ ti dé, àkókò tí èmi ó bẹ̀ ọ wò.
“See, I am against you, proud one—this is the declaration of the Lord Yahweh of hosts— for your day has come, proud one, the time when I will punish you.
32 Onígbèéraga yóò kọsẹ̀, yóò sì ṣubú, kì yóò sì ṣí ẹni tí yóò gbé dìde. Èmi yóò tan iná ní ìlú náà, èyí tí yóò sì jo run.”
So the proud ones will stumble and fall. No one will raise them up. I will light a fire in their cities; it will devour everything around him.
33 Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ: “A pọ́n àwọn ènìyàn Israẹli lójú àti àwọn ènìyàn Juda pẹ̀lú. Gbogbo àwọn tí ó kó wọn nígbèkùn dì wọn mú ṣinṣin wọn kò sì jẹ́ kí ó sá àsálà.
Yahweh of hosts says this: The people of Israel are oppressed, together with the people of Judah. All the ones who captured them still hold them; they refuse to let them go.
34 Síbẹ̀, Olùràpadà wọn, Alágbára, Olúwa Ọlọ́run Alágbára ni orúkọ rẹ̀. Yóò sì gbe ìjà wọn jà, kí ó ba à lè mú wọn wá sinmi ní ilẹ̀ náà; ṣùgbọ́n kò sí ìsinmi fún àwọn tí ó ń gbé Babeli.
The one who rescues them is strong. Yahweh of hosts is his name. He will truly plead their case, in order to bring rest to the land, and to bring strife to the ones inhabiting Babylon.
35 “Idà lórí àwọn Babeli!” ni Olúwa wí, “lòdì sí àwọn tó ń gbé ní Babeli, àwọn aláṣẹ àti àwọn amòye ọkùnrin.
A sword is against the Chaldeans—this is Yahweh's declaration— and against the inhabitants of Babylon, her leaders, and her wise men.
36 Idà lórí àwọn wòlíì èké wọn yóò di òmùgọ̀! Idà lórí àwọn jagunjagun, wọn yóò sì kún fún ẹ̀rù.
A sword against those who say empty words! They will become fools! A sword against her soldiers! They will be filled with terror.
37 Idà lórí àwọn kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ àti àwọn àjèjì nínú ẹgbẹ́ rẹ̀. Wọn yóò di obìnrin. Idà lórí àwọn ohun ìṣúra rẹ̀!
A sword is coming against their horses, their chariots and all of the people who are in the midst of Babylon, so they will become like women. A sword is coming against her storerooms, and they will be plundered.
38 Ilẹ̀ gbígbẹ lórí omi rẹ̀; yóò sì gbẹ. Nítorí pé ó jẹ́ ilẹ̀ àwọn ère, àwọn ère tí yóò ya òmùgọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù.
A drought is coming on her waters, so they will become dry. For she is a land of worthless idols, and they act like people made insane by their dreadful idols.
39 “Nítorí náà àwọn ẹranko ijù pẹ̀lú ọ̀wàwà ni yóò máa gbé ibẹ̀, abo ògòǹgò yóò sì máa gbé inú rẹ̀, a kì yóò sì gbé inú rẹ̀ mọ́, láéláé, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò ṣàtìpó nínú rẹ̀ láti ìrandíran.
So desert beasts with the jackals will inhabit there, and the young of ostriches will live in her. For all time, she will no longer be inhabited. From generation to generation, she will not be lived in.
40 Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti gba ìjọba Sodomu àti Gomorra pẹ̀lú àwọn ìlú agbègbè wọn,” ni Olúwa wí, “torí náà kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé ibẹ̀; ènìyàn ki yóò gbé nínú rè.
Just as God overthrew Sodom and Gomorrah and their neighbors—this is Yahweh's declaration— no one will live there; no person will stay in her.”
41 “Wò ó! Ọ̀wọ́ ọmọ-ogun láti ìhà àríwá; orílẹ̀-èdè ńlá àti àwọn ọba púpọ̀ ni à ń gbé dìde láti òpin ilẹ̀ ayé.
“See, a people is coming from the north; a great nation and many kings are being stirred up from the farthest parts of the earth.
42 Wọ́n sì di ìhámọ́ra ọ̀kọ̀ àti ọrun, wọ́n burú wọn kò sì ní àánú. Wọ́n n ké bí i rírú omi bí wọ́n ti ṣe ń gun ẹṣin wọn lọ. Wọ́n wá bí àkójọpọ̀ ogun láti kọlù ọ́, ìwọ ọmọbìnrin Babeli.
They will pick up bows and spears. They are cruel and have no compassion. Their sound is like the sea roar, and they are riding on horses, set out in order as men for battle, against you, daughter of Babylon.
43 Ọba Babeli ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn, ọwọ́ wọn sì rọ, ìrora mú wọn bí obìnrin tí ó ń rọbí.
The king of Babylon heard the reports about them and his hands fell limp in distress. Anguish seized him like a woman giving birth.
44 Bí i kìnnìún ni òun ó gòkè wá láti igbó Jordani sí orí ilẹ̀ ọlọ́ràá, Èmi ó lé Babeli kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá. Ta ni àyànfẹ́ náà tí èmi ó yàn sórí rẹ̀? Ta ló dàbí mi, ta ni ó sì pé mi ṣe ẹlẹ́rìí? Ta ni olùṣọ́-àgùntàn náà tí yóò le dúró níwájú mi?”
Behold! He goes up like a lion from the heights of the Jordan to the enduring grazing place For I will quickly cause them to run from it, and I will put someone who will be chosen in charge of it. For who is like me, and who will summon me? What shepherd is able to resist me?
45 Nítorí náà, gbọ́ ohun tí Olúwa sọ nípa Babeli, ẹni tí ó gbìmọ̀ lòdì sí Babeli: n ó sì pa agbo ẹran wọn run.
So listen to the plans that Yahweh has decided against Babylon, the plans that he has planned against the land of the Chaldeans. They will certainly be dragged away, even the smallest flock. Their pasturelands will be turned into ruined places.
46 Ní ohùn igbe ńlá pé; a kò Babeli, ilẹ̀ ayé yóò mì tìtì, a sì gbọ́ igbe náà láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.
At the sound of conquered Babylon the earth shakes, and their shout of distress is heard among the nations.”