< Jeremiah 48 >
1 Nípa Moabu. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: “Ègbé ni fún Nebo nítorí a ó parun. A dójútì Kiriataimu, a sì mú un, ojú yóò ti alágbára, a ó sì fọ́nká.
2 Moabu kò ní ní ìyìn mọ́, ní Heṣboni ni wọn ó pète ìparun rẹ̀, ‘Wá, kí a pa orílẹ̀-èdè náà run.’ Àti ẹ̀yin òmùgọ̀ ọkùnrin pàápàá ni a ó pa lẹ́nu mọ́, a ó fi idà lé e yín.
3 Gbọ́ igbe ní Horonaimu, igbe ìrora àti ìparun ńlá.
4 Moabu yóò di wíwó palẹ̀; àwọn ọmọdé rẹ̀ yóò kígbe síta.
5 Wọ́n gòkè lọ sí Luhiti, wọ́n ń sọkún kíkorò bí wọ́n ti ń lọ; ní ojú ọ̀nà sí Horonaimu igbe ìrora ìparun ni à ń gbọ́ lọ.
6 Sá! Àsálà fún ẹ̀mí yín; kí ẹ sì dàbí aláìní ní aginjù.
7 Níwọ́n ìgbà tí o gbẹ́kẹ̀lé agbára àti ọrọ̀ rẹ, a ó kó ìwọ náà ní ìgbèkùn, Kemoṣi náà yóò lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn pẹ̀lú àlùfáà àti àwọn aláṣẹ rẹ̀.
8 Gbogbo ìlú rẹ ni apanirun yóò dojúkọ, ìlú kan kò sì ní le là. Àfonífojì yóò di ahoro àti ilẹ̀ títẹ́ ni a ó run, nítorí tí Olúwa ti sọ̀rọ̀.
9 Fi iyọ̀ sí Moabu, nítorí yóò ṣègbé, àwọn ìlú rẹ yóò sì di ahoro láìsí ẹni tí yóò gbé inú rẹ̀.
10 “Ìfibú ni fún ẹni tí ó fi ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ Olúwa, ìfibú ni fún ẹni tí ó pa idà mọ́ fún ìtàjẹ̀ sílẹ̀.
11 “Moabu ti wà ní ìsinmi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá bí i ọtí wáìnì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀, tí a kò dà láti ìgò kan sí èkejì kò tí ì lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn rí. Ó dùn lẹ́nu bí ó ti yẹ, òórùn rẹ̀ kò yí padà.
12 Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “nígbà tí n ó rán àwọn tí ó n da ọtí láti inú àwọn ìgò tí wọ́n ó sì dà á síta; wọn ó sọ àwọn ìgò rẹ̀ di òfo, wọn ó sì fọ́ àwọn ife rẹ̀.
13 Nígbà náà Moabu yóò sì tú u nítorí Kemoṣi, bí ojú ti í ti ilé Israẹli nígbà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Beteli.
14 “Báwo ni o ṣe lè sọ pé, ‘Ajagun ni wá, alágbára ní ogun jíjà’?
15 A ó pa Moabu run, a ó sì gba àwọn ìlú rẹ̀; a ó sì dúńbú àwọn arẹwà ọkùnrin rẹ̀,” ni ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
16 “Ìṣubú Moabu súnmọ́; ìpọ́njú yóò dé kánkán.
17 Ẹ dárò fún, gbogbo ẹ̀yin tí ó yí i ká gbogbo ẹ̀yin tí ẹ mọ bí ó ti ní òkìkí tó. Ẹ sọ pé, ‘Báwo ni ọ̀pá agbára rẹ títóbi tí ó sì lógo ṣe fọ́!’
18 “Sọ̀kalẹ̀ níbi ògo rẹ, kí o sì jókòó ní ilẹ̀ gbígbẹ, ẹ̀yin olùgbé ọmọbìnrin Diboni, nítorí tí ẹni tí ó pa Moabu run yóò dojúkọ ọ́ yóò sì pa àwọn ìlú olódi rẹ run.
19 Dúró lẹ́bàá ọ̀nà kí o sì wòran, ìwọ tí ń gbé ní Aroeri. Bí ọkùnrin tí ó sálọ àti obìnrin tí ó ń sá àsálà ‘Kí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀?’
20 Ojú ti Moabu nítorí tí a wó o lulẹ̀. Ẹ hu, kí ẹ sì kígbe! Ẹ kéde rẹ̀ ní Arnoni pé, a pa Moabu run.
21 Ìdájọ́ ti dé sí àwọn òkè pẹrẹsẹ, sórí Holoni, Jahisa àti Mefaati,
22 sórí Diboni, Nebo àti Beti-Diblataimu,
23 sórí Kiriataimu, Beti-Gamu àti Beti-Meoni,
24 sórí Kerioti àti Bosra, sórí gbogbo ìlú Moabu, nítòsí àti ní ọ̀nà jíjìn.
25 A gé ìwo Moabu kúrò, apá rẹ̀ dá,” ni Olúwa wí.
26 “Ẹ jẹ́ kí a mú u mutí nítorí ó kó ìdọ̀tí bá Olúwa, jẹ́ kí Moabu lúwẹ̀ẹ́ nínú èébì rẹ̀, kí ó di ẹni ẹ̀gàn.
27 Ǹjẹ́ Israẹli kò di ẹni ẹ̀gàn rẹ? Ǹjẹ́ a kó o pẹ̀lú àwọn olè tó bẹ́ẹ̀ tí o ń gbọn orí rẹ̀ pẹ̀lú yẹ̀yẹ́ nígbàkígbà bí a bá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
28 Kúrò ní àwọn ìlú rẹ, kí o sì máa gbé láàrín àwọn òkúta, ẹ̀yin tí ó ti ń gbé inú ìlú Moabu. Ẹ dàbí i àdàbà tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí ẹnu ihò.
29 “A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu: àti ìwà mo gbọ́n tan rẹ̀ àti ìgbéraga ọkàn rẹ̀.
30 Mo mọ àfojúdi rẹ̀, ṣùgbọ́n òfo ni,” ni Olúwa wí, “ìfọ́nnu rẹ̀ kò lè ṣe nǹkan kan.
31 Nítorí náà, mo pohùnréré ẹkún lórí Moabu fún àwọn ará Moabu ni mo kígbe lóhùn rara, mo kẹ́dùn fún àwọn ọkùnrin Kiri-Hareseti.
32 Mo sọkún fún ọ bí Jaseri ṣe sọkún ìwọ àjàrà Sibma. Ẹ̀ka rẹ tẹ̀ títí dé Òkun, wọn dé Òkun Jaseri. Ajẹnirun ti kọlu èso rẹ, ìkórè èso àjàrà rẹ.
33 Ayọ̀ àti ìdùnnú ti kúrò nínú ọgbà àjàrà àti oko Moabu. Mo dá ọwọ́ ṣíṣàn ọtí wáìnì dúró lọ́dọ̀ olùfúntí; kò sí ẹni tí ó ń tẹ̀ wọ́n pẹ̀lú igbe ayọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbe wà, wọn kì í ṣe igbe ti ayọ̀.
34 “Ohùn igbe wọn gòkè láti Heṣboni dé Eleale àti Jahasi, láti Soari títí dé Horonaimu àti Eglati-Ṣeliṣi, nítorí àwọn omi Nimrimu pẹ̀lú yóò gbẹ.
35 Ní ti Moabu ni èmi yóò ti fi òpin sí ẹni tí ó rú ẹbọ ní ibí gíga àti ẹni tí ń sun tùràrí fún òrìṣà rẹ̀,” ni Olúwa wí.
36 “Nítorí náà ọkàn mi ró fún Moabu bí fèrè, ọkàn mi ró bí fèrè fún àwọn ọkùnrin Kiri-Hareseti. Nítorí ìṣúra tí ó kójọ ṣègbé.
37 Gbogbo orí ni yóò pá, gbogbo irùngbọ̀n ni a ó gé kúrò, gbogbo ọwọ́ ni a sá lọ́gbẹ́, àti aṣọ ọ̀fọ̀ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́.
38 Ẹkún ńlá ní yóò wà lórí gbogbo òrùlé Moabu, àti ní ìta rẹ̀, nítorí èmi ti fọ́ Moabu bí a ti ń fọ́ ohun èlò tí kò wu ni,” ni Olúwa wí.
39 “Èéṣe tí ẹ fi fọ́ túútúú, tí ẹ sì fi ń pohùnréré ẹkún! Báwo ni Moabu ṣe yí ẹ̀yìn padà ní ìtìjú! Moabu ti di ẹni ìtìjú àti ẹ̀gàn àti ìdààmú sí gbogbo àwọn tí ó yìí ká.”
40 Báyìí ni Olúwa wí: “Wò ó ẹyẹ idì náà ń fò bọ̀ nílẹ̀ ó sì na ìyẹ́ rẹ̀ lórí Moabu.
41 Kerioti ni a ó kó lẹ́rú àti ilé agbára ni ó gbà. Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn akọni Moabu yóò dàbí ọkàn obìnrin tí ó ń rọbí.
42 A ó pa Moabu run gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè nítorí pé ó gbéraga sí Olúwa.
43 Ẹ̀rù àti ọ̀fìn àti okùn dídè ń dúró dè yín, ẹ̀yin ènìyàn Moabu,” ní Olúwa wí.
44 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá fún ẹ̀rù yóò ṣubú sínú ọ̀fìn ẹnikẹ́ni tí o bá jáde síta nínú ọ̀fìn ní à ó mú nínú okùn dídè nítorí tí èmi yóò mú wá sórí Moabu àní ọdún ìjìyà rẹ,” ní Olúwa wí.
45 “Ní abẹ́ òjìji Heṣboni àwọn tí ó sá dúró láìní agbára, nítorí iná ti jáde wá láti Heṣboni, àti ọwọ́ iná láti àárín Sihoni, yóò sì jó iwájú orí Moabu run, àti agbárí àwọn ọmọ aláriwo.
46 Ègbé ní fún ọ Moabu! Àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè Kemoṣi ṣègbé a kó àwọn ọmọkùnrin rẹ lọ sí ilẹ̀ àjèjì àti àwọn ọmọbìnrin rẹ lọ sí ìgbèkùn.
47 “Síbẹ̀, èmi yóò dá ìkólọ Moabu padà ní ọjọ́ ìkẹyìn,” ni Olúwa wí. Eléyìí ní ìdájọ́ ìkẹyìn lórí Moabu.