< Jeremiah 47 >

1 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tó tọ wòlíì Jeremiah wá nípa àwọn Filistini, kí ó tó di pé Farao dojúkọ Gasa.
אשר היה דבר יהוה אל ירמיהו הנביא אל פלשתים בטרם יכה פרעה את עזה׃
2 Báyìí ni Olúwa wí: “Wo bí omi ti ń ru sókè ní àríwá, wọn ó di odò tí ń bo bèbè mọ́lẹ̀. Wọn kò ní borí ilẹ̀ àti ohun gbogbo tó wà lórí rẹ̀, ìlú àti àwọn tó ń gbé nínú wọn. Àwọn ènìyàn yóò kígbe, gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà yóò hu
כה אמר יהוה הנה מים עלים מצפון והיו לנחל שוטף וישטפו ארץ ומלואה עיר וישבי בה וזעקו האדם והילל כל יושב הארץ׃
3 nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ìró títẹ̀lé pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin alágbára nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ọ̀tá ńlá àti iye kẹ̀kẹ́ wọn. Àwọn baba kò ní lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́; ọwọ́ wọn yóò kákò.
מקול שעטת פרסות אביריו מרעש לרכבו המון גלגליו לא הפנו אבות אל בנים מרפיון ידים׃
4 Nítorí tí ọjọ́ náà ti pé láti pa àwọn Filistini run, kí a sì mú àwọn tí ó là tí ó lè ran Tire àti Sidoni lọ́wọ́ kúrò. Olúwa ti ṣetán láti pa Filistini run, àwọn tí ó kù ní agbègbè Kafitori.
על היום הבא לשדוד את כל פלשתים להכרית לצר ולצידון כל שריד עזר כי שדד יהוה את פלשתים שארית אי כפתור׃
5 Gasa yóò fá irun orí rẹ̀ nínú ọ̀fọ̀. A ó pa Aṣkeloni lẹ́nu mọ́; ìyókù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ìwọ yóò ti sá ara rẹ lọ́gbẹ́ pẹ́ tó?
באה קרחה אל עזה נדמתה אשקלון שארית עמקם עד מתי תתגודדי׃
6 “Ẹ̀yin kígbe, ‘Yé è, idà Olúwa, yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò sinmi? Padà sínú àkọ̀ rẹ; sinmi kí o sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.’
הוי חרב ליהוה עד אנה לא תשקטי האספי אל תערך הרגעי ודמי׃
7 Ṣùgbọ́n báwo ni yóò ṣe sinmi, nígbà tí Olúwa ti pàṣẹ fún un, nígbà tí ó ti pa á láṣẹ láti dojúkọ Aṣkeloni àti agbègbè rẹ̀.”
איך תשקטי ויהוה צוה לה אל אשקלון ואל חוף הים שם יעדה׃

< Jeremiah 47 >