< Jeremiah 45 >

1 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Jeremiah wòlíì sọ fún Baruku ọmọ Neriah ní ọdún kẹrin ti Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda. Lẹ́yìn tí Baruku ti kọ sínú ìwé kíká àwọn ọ̀rọ̀ tí Jeremiah ti ń sọ:
The word that Jeremiah the prophet spoke to Baruch the son of Neriah, when he had written these words in a book at the mouth of Jeremiah, in the fourth year of Jehoiakim the son of Josiah king of Judah, saying,
2 “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ fún ọ, Baruku.
Thus says the LORD, the God of Israel, to you, O Baruch:
3 Ìwọ wí pé, ‘Ègbé ni fún mi! Olúwa ti fi ìbànújẹ́ kún ìrora mi, àárẹ̀ mú mi nínú ẹ̀dùn mi, èmi kò sì rí ìsinmi.’”
You did say, Woe is me now! for the LORD has added grief to my sorrow; I fainted in my sighing, and I find no rest.
4 Olúwa wí pé sọ èyí fún un, “Èyí ni Ọlọ́run sọ: ‘Èyí tí èmi ti kọ́ ni èmi yóò wò lulẹ̀, àti èyí tí èmi ti gbìn ni èmi yóò fàtu, àní ní orí gbogbo ilẹ̀.
Thus shall you say to him, The LORD says thus; Behold, that which I have built will I break down, and that which I have planted I will pluck up, even this whole land.
5 Ṣé ìwọ sì ń wá ohun títóbi fún ara rẹ? Nítorí náà, má ṣe wá wọn. Èmi yóò mú ibi wá sí orí àwọn ènìyàn gbogbo ni Olúwa wí, ṣùgbọ́n níbikíbi tí ìwọ bá lọ ni èmi yóò jẹ́ kí o sá àsálà pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ.’”
And seek you great things for yourself? seek them not: for, behold, I will bring evil on all flesh, says the LORD: but your life will I give to you for a prey in all places where you go.

< Jeremiah 45 >