< Jeremiah 43 >

1 Nígbà tí Jeremiah parí sísọ ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rán an sí wọn tan.
ויהי ככלות ירמיהו לדבר אל כל העם את כל דברי יהוה אלהיהם אשר שלחו יהוה אלהיהם אליהם--את כל הדברים האלה
2 Asariah ọmọ Hoṣaiah àti Johanani ọmọ Karea, àti gbogbo àwọn agbéraga ọkùnrin sọ fún Jeremiah pé, “Ìwọ ń pa irọ́! Olúwa Ọlọ́run wa kò rán ọ láti sọ pé, ‘Ẹ má lọ sí Ejibiti láti ṣàtìpó níbẹ̀.’
ויאמר עזריה בן הושעיה ויוחנן בן קרח וכל האנשים הזדים אמרים אל ירמיהו שקר אתה מדבר--לא שלחך יהוה אלהינו לאמר לא תבאו מצרים לגור שם
3 Ṣùgbọ́n Baruku, ọmọ Neriah, ni ó fi ọ̀rọ̀ sí ọ lẹ́nu sí wa, láti fà wá lé àwọn ará Babeli lọ́wọ́, láti pa wá àti láti kó wa ní ìgbèkùn lọ sí Babeli.”
כי ברוך בן נריה מסית אתך בנו--למען תת אתנו ביד הכשדים להמית אתנו ולהגלות אתנו בבל
4 Nítorí náà, Johanani ti Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun, àti gbogbo àwọn ènìyàn tàpá sí àṣẹ Olúwa nípa dídúró sí Juda.
ולא שמע יוחנן בן קרח וכל שרי החילים וכל העם--בקול יהוה לשבת בארץ יהודה
5 Dípò bẹ́ẹ̀, Johanani ọmọ Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun sì ko àwọn àjẹkù Juda tí wọ́n wá láti gbé ilẹ̀ Juda láti orílẹ̀-èdè gbogbo tí wọ́n ti tú wọn ká.
ויקח יוחנן בן קרח וכל שרי החילים את כל שארית יהודה--אשר שבו מכל הגוים אשר נדחו שם לגור בארץ יהודה
6 Wọ́n tún kó àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, àti àwọn ọmọ ọba tí ó jẹ́ obìnrin èyí tí Nebusaradani balógun ẹ̀ṣọ́ ti fi sílẹ̀ pẹ̀lú Gedaliah ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, àti Jeremiah wòlíì náà àti Baruku ọmọ Neriah.
את הגברים ואת הנשים ואת הטף ואת בנות המלך ואת כל הנפש אשר הניח נבוזראדן רב טבחים את גדליהו בן אחיקם בן שפן ואת ירמיהו הנביא ואת ברוך בן נריהו
7 Nítorí náà, wọn wọ Ejibiti pẹ̀lú àìgbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa, wọ́n sì lọ títí dé Tafanesi.
ויבאו ארץ מצרים כי לא שמעו בקול יהוה ויבאו עד תחפנחס
8 Ní Tafanesi ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá:
ויהי דבר יהוה אל ירמיהו בתחפנחס לאמר
9 “Nígbà tí àwọn Júù ń wòye mú àwọn òkúta pẹ̀lú rẹ, kí o sì rì wọ́n mọ́ inú amọ̀ tí ó wà nínú bíríkì tí ó wà níbi pèpéle ẹnu-ọ̀nà ààfin Farao ní Tafanesi.
קח בידך אבנים גדלות וטמנתם במלט במלבן אשר בפתח בית פרעה בתחפנחס--לעיני אנשים יהודים
10 Báyìí kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí. Èmi yóò ránṣẹ́ sí ìránṣẹ́ mi Nebukadnessari ọba Babeli, Èmi yóò gbé ìjọba rẹ̀ ka orí àwọn òkúta; èyí tí mo ti rì sí ibí yìí, yóò tan ìjọba rẹ̀ jù wọ́n lọ.
ואמרת אליהם כה אמר יהוה צבאות אלהי ישראל הנני שלח ולקחתי את נבוכדראצר מלך בבל עבדי ושמתי כסאו ממעל לאבנים האלה אשר טמנתי ונטה את שפרורו (שפרירו) עליהם
11 Yóò gbé ogun sí Ejibiti; yóò mú ikú bá àwọn tí ó yan ikú; ìgbèkùn fún àwọn tí ó ti yan ìgbèkùn, àti idà fún àwọn tí ó yan idà.
ובאה (ובא) והכה את ארץ מצרים--אשר למות למות ואשר לשבי לשבי ואשר לחרב לחרב
12 Yóò dá, iná sun tẹmpili àwọn òrìṣà Ejibiti, yóò sun tẹmpili àwọn òrìṣà Ejibiti, yóò sì mú wọn lọ ìgbèkùn. Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn, yóò ró aṣọ rẹ̀ mọ́ra, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò ró Ejibiti òun yóò sì lọ kúrò níbẹ̀ ní àlàáfíà.
והצתי אש בבתי אלהי מצרים ושרפם ושבם ועטה את ארץ מצרים כאשר יעטה הרעה את בגדו ויצא משם בשלום
13 Ní tẹmpili ni yóò ti fọ́ ère ilé oòrùn tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti túútúú, yóò sì sun àwọn tẹmpili àwọn òrìṣà Ejibiti.’”
ושבר את מצבות בית שמש אשר בארץ מצרים ואת בתי אלהי מצרים ישרף באש

< Jeremiah 43 >