< Jeremiah 40 >

1 Ọ̀rọ̀ náà sì tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa lẹ́yìn tí Nebusaradani balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ ti tú u sílẹ̀ ní Rama. Ó rí Jeremiah tí a fi ẹ̀wọ̀n dè láàrín gbogbo àwọn tí wọ́n mú ní Jerusalẹmu àti Juda. Wọ́n kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì Babeli.
The word that has been to Jeremiah from YHWH, after Nebuzar-Adan, chief of the executioners, has sent him from Ramah, in his taking him—and he a prisoner in chains—in the midst of all the expulsion of Jerusalem and of Judah, who are removed to Babylon.
2 Nígbà tí balógun ẹ̀ṣọ́ rí Jeremiah, ó sọ fún un wí pé, “Olúwa Ọlọ́run rẹ ni ó pàṣẹ ibí yìí fún mi.
And the chief of the executioners takes Jeremiah and says to him, “Your God YHWH has spoken this calamity concerning this place,
3 Nísinsin yìí, Olúwa ti mú un jáde; ó ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ pé òun yóò ṣe. Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ nítorí wí pé ẹ̀yin ènìyàn ṣẹ̀ sí Olúwa, àti pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀.
and YHWH brings [it] in, and does as He spoke, because you have sinned against YHWH, and have not listened to His voice, even this thing has been to you.
4 Ṣùgbọ́n, ní òní yìí mò ń tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n tí ó wà ní ọwọ́ rẹ. Bí o bá fẹ́, tẹ̀lé mi ká lọ sí Babeli, èmi yóò sì bojútó ọ; ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá fẹ́, dúró síbí. Wò ó, gbogbo orílẹ̀-èdè wà níwájú rẹ, lọ sí ibikíbi tí ó bá tẹ́ ọ lọ́rùn.”
And now, behold, I have loosed you today from the chains that [are] on your hand; if [it is] good in your eyes to come with me [to] Babylon, come, and I keep my eye on you: and if [it is] evil in your eyes to come with me to Babylon, refrain; see, all the land [is] before you, to where [it is] good, and to where [it is] right in your eyes to go—go.”
5 Ẹ̀wẹ̀, kí ó tó di pé Jeremiah pẹ̀yìndà láti máa lọ, Nebusaradani fi kún un wí pé, “Padà tọ Gedaliah ọmọ Ahikamu lọ, ọmọ Ṣafani, ẹni tí ọba Babeli ti fi jẹ baálẹ̀ lórí ìlú Juda, kí o sì máa gbé ní àárín àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o máa lọ ibikíbi tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ.” Nígbà náà ni balógun náà fún un ní oúnjẹ àti ẹ̀bùn, ó sì jẹ́ kí ó lọ.
And while he does not reply—“Or turn back to Gedaliah son of Ahikam, son of Shaphan, whom the king of Babylon has appointed over the cities of Judah, and dwell with him in the midst of the people, or wherever it is right in your eyes to go—go.” And the chief of the executioners gives a ration and gift to him, and sends him away,
6 Báyìí ni Jeremiah lọ sí ọ̀dọ̀ Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu ní Mispa, ó sì dúró tì í láàrín àwọn ènìyàn tí ó ṣẹ́kù ní ilẹ̀ náà.
and Jeremiah comes to Gedaliah son of Ahikam, to Mizpah, and dwells with him in the midst of the people who are left in the land.
7 Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ènìyàn tí wọ́n kù lórí orílẹ̀-èdè náà gbọ́ pé ọba Babeli ti yan Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu gẹ́gẹ́ bí baálẹ̀ ní ilẹ̀ náà; àti pé ó ti fi àwọn ọkùnrin, obìnrin àti ọmọdé tí wọ́n jẹ́ tálákà ní ilẹ̀ náà tí wọn kò kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì sí ìkáwọ́ rẹ̀,
And all the heads of the forces that [are] in the field hear, they and their men, that the king of Babylon has appointed Gedaliah son of Ahikam over the land, and that he has charged him [with] men, and women, and infants, and of the poor of the land, of those who have not been removed to Babylon;
8 wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Gedaliah ní Mispa; Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah, Johanani àti Jonatani ọmọkùnrin ti Karea, Seraiah ọmọkùnrin Tanhumeti tí í ṣe ọmọkùnrin Efai ará Netofa àti Jesaniah ọmọkùnrin Maakati àti àwọn ènìyàn wọn.
and they come to Gedaliah at Mizpah, even Ishmael son of Nethaniah, and Johanan and Jonathan [the] sons of Kareah, and Seraiah son of Tanhumeth, and the sons of Ephai the Netophathite, and Jezaniah son of the Maachathite, they and their men.
9 Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu, ọmọkùnrin ti Ṣafani ṣe ìbúra láti tún fi dá àwọn ènìyàn lójú pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù láti sin àwọn Babeli.” Ó sọ wí pé, “Gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì máa sin ọba Babeli, yóò sì dára fún un yín.
And Gedaliah son of Ahikam, son of Shaphan, swears to them and to their men, saying, “Do not be afraid of serving the Chaldeans, abide in the land, and serve the king of Babylon, and it is well for you;
10 Èmi fúnra mi yóò dúró ní Mispa láti ṣojú yín níwájú Babeli tí wọ́n tọ̀ wá wá. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni yóò máa kórè ọtí wáìnì, èso igi àti òróró; kí ẹ sì kó wọn sí inú àpò àpamọ́wọ́ yín; kí ẹ̀yin sì máa gbé ní ìlú tí ẹ ti gbà.”
and I, behold, I am dwelling in Mizpah to stand before the Chaldeans who have come to us, and you, gather wine, and summer fruit, and oil, and put [them] in your vessels, and dwell in your cities that you have taken.”
11 Nígbà tí gbogbo àwọn Juda ní Moabu, Ammoni, Edomu àti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́ pé ọba Babeli ti fi ohun tókù sílẹ̀ ní Juda, àti pé ó ti yan Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu ọmọkùnrin Ṣafani gẹ́gẹ́ bí gómìnà lórí wọn.
And also all the Jews who [are] in Moab, and among the sons of Ammon, and in Edom, and who [are] in all the lands, have heard that the king of Babylon has given a remnant to Judah, and that he has appointed over them Gedaliah son of Ahikam, son of Shaphan,
12 Gbogbo wọn padà wá sí ilẹ̀ Juda sọ́dọ̀ Gedaliah ní Mispa láti orílẹ̀-èdè gbogbo tí a ti lé wọn sí. Wọ́n sì kórè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọtí wáìnì àti èso igi.
and all the Jews from all the places to where they have been driven, return and enter the land of Judah, to Gedaliah, to Mizpah, and they gather wine and summer fruit—to multiply abundantly.
13 Johanani ọmọkùnrin ti Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun tí ó kù ní orílẹ̀-èdè sì tọ Gedaliah wá ní Mispa.
And Johanan son of Kareah, and all the heads of the forces that [are] in the field, have come to Gedaliah at Mizpah,
14 Wọ́n sì sọ fún un wí pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ha mọ̀ pé Baalisi ọba àwọn Ammoni ti rán Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah láti lọ mú ẹ̀mí rẹ?” Ṣùgbọ́n Gedaliah ọmọkùnrin ti Ahikamu kò gbà wọ́n gbọ́.
and they say to him, “Do you really know that Ba‘alis king of the sons of Ammon has sent Ishmael son of Nethaniah to strike your soul?” And Gedaliah son of Ahikam has not given credence to them.
15 Nígbà náà ni Johanani ọmọkùnrin Karea sọ ní ìkọ̀kọ̀ fún Gedaliah ní Mispa pé, “Jẹ́ kí èmi lọ pa Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah, ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ èyí. Kí ni ìdí rẹ̀ tí yóò ṣe mú ẹ̀mí rẹ, tí o sì ṣe fẹ́ mú àwọn Júù tí ó yí ọ ká túká, kí ìyókù Juda sì parun?”
And Johanan son of Kareah has spoken to Gedaliah in secret, in Mizpah, saying, “Please let me go, and I strike Ishmael son of Nethaniah, and no one knows; why does he strike your soul? And all Judah who are gathered to you have been scattered, and the remnant of Judah has perished.”
16 Ṣùgbọ́n Gedaliah ọmọ Ahikamu sọ fún Johanani ọmọ Karea pé, “Má ṣe ṣe nǹkan yìí! Nítorí nǹkan tí ò ń sọ nípa Iṣmaeli kì í ṣe òtítọ́.”
And Gedaliah son of Ahikam says to Johanan son of Kareah, “You do not do this thing, for you are speaking falsehood concerning Ishmael.”

< Jeremiah 40 >