< Jeremiah 39 >

1 Ó sì ṣe, nígbà tí a kó Jerusalẹmu, ní ọdún kẹsànán Sedekiah, ọba Juda, nínú oṣù kẹwàá, Nebukadnessari ọba Babeli gbógun ti Jerusalẹmu pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀, wọ́n sì dó tì í.
Und es geschah, daß Jerusalem gewonnen ward. Denn im neunten Jahr Zedekias, des Königs Judas, im zehnten Monden kam Nebukadnezar, der König zu Babel, und all sein Heer vor Jerusalem und belagerten dieselbige.
2 Ní ọjọ́ kẹsànán, oṣù kẹrin ọdún kọkànlá Sedekiah, ni a wó odi ìlú náà.
Und im elften Jahr Zedekias, am neunten Tag des vierten Monden, brach man in die Stadt.
3 Nígbà náà ni gbogbo àwọn ìjòyè ọba Babeli wá, wọ́n sì jókòó ní àárín ẹnu ibodè, àní Nergali-Ṣareseri ti Samgari, Nebo-Sarsikimu olórí ìwẹ̀fà, Nergali-Ṣareseri, olórí amòye, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìjòyè ọba Babeli yóò kú.
Und zogen hinein alle Fürsten des Königs zu Babel und hielten unter dem Mitteltor, nämlich Nergal-Sarezer, Sangar-Nebo, Sarsechim, der oberste Kämmerer, Nergal-Sarezer, der Hofmeister, und alle andern Fürsten des Königs zu Babel.
4 Nígbà tí Sedekiah ọba Juda àti àwọn ọmọ-ogun rí wọn, wọ́n sá, wọ́n kúrò ní ìlú ní alẹ́, wọ́n gba ọ̀nà ọgbà ọba lọ láàrín ẹnu ibodè pẹ̀lú odi méjì, wọ́n dojúkọ aginjù.
Als sie nun Zedekia, der König Judas, sah samt seinen Kriegsleuten, flohen sie bei Nacht zur Stadt hinaus bei des Königs Garten durchs Tor zwischen zweien Mauern und zogen durchs Feld hindurch.
5 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ogun Babeli lé wọn, wọ́n bá Sedekiah láàrín aginjù Jeriko. Wọ́n mú un ní ìgbèkùn, wọ́n sì mú u tọ Nebukadnessari ọba Babeli àti Ribla ní ilẹ̀ Hamati, níbi tí wọ́n ti ṣe ìdájọ́ rẹ̀.
Aber der Chaldäer Heer jagten ihnen nach und ergriffen Zedekia im Felde bei Jericho und fingen ihn und brachten ihn zu Nebukadnezar, dem Könige zu Babel, gen Riblath, die im Lande Hemath liegt; der sprach ein Urteil über ihn.
6 Níbẹ̀ ní Ribla, ni ọba Babeli ti dúńbú àwọn ọmọ Sedekiah lójú rẹ̀, tí ó sì tún pa gbogbo àwọn ọlọ́lá ilẹ̀ Juda.
Und der König zu Babel ließ die Kinder Zedekias vor seinen Augen töten zu Riblath und tötete alle Fürsten Judas.
7 Nígbà náà ni ó fọ́ ojú Sedekiah, ó sì dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n láti gbé e lọ sí ilẹ̀ Babeli.
Aber Zedekia ließ er die Augen ausstechen und ihn mit Ketten binden, daß er ihn gen Babel führete.
8 Àwọn Babeli dáná sun ààfin ọba àti ilé àwọn ènìyàn, wọ́n sì wó odi Jerusalẹmu.
Und die Chaldäer verbrannten beide, des Königs Haus und der Bürger Häuser, und zerbrachen die Mauern zu Jerusalem.
9 Nebusaradani olórí àwọn ọmọ-ogun mú lọ sí ìgbèkùn Babeli pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó ṣẹ́kù nínú ìlú.
Was aber noch von Volk in der Stadt war und was sonst zu ihnen gefallen war, die führete Nebusar-Adan, der Hofmeister, alle miteinander gen Babel gefangen.
10 Ṣùgbọ́n Nebusaradani olórí ogun fi àwọn aláìní sílẹ̀ ní Juda, àwọn tí kò ní ohun kankan ní àkókò náà, ó fún wọn ní ọgbà àjàrà àti oko.
Aber von dem geringen Volk, das nichts hatte, ließ zur selbigen Zeit Nebusar-Adan, der Hauptmann, etliche im Land Juda und gab ihnen Weinberge und Dörflein ein.
11 Nísinsin yìí, Nebukadnessari ọba àwọn Babeli pàṣẹ lórí Jeremiah, láti ọ̀dọ̀ Nebusaradani olórí ogun wá wí pé:
Aber Nebukadnezar, der König zu Babel, hatte Nebusar-Adan, dem Hauptmanne, befohlen von Jeremia und gesagt:
12 “Ẹ gbé e, kí ẹ sì bojútó o. Ẹ má ṣe ṣe ohun búburú fún un, ṣùgbọ́n ohunkóhun tó bá béèrè ni kí ẹ fi fún un.”
Nimm hin und laß dir ihn befohlen sein und tue ihm kein Leid, sondern wie er's von dir begehret, so mache es mit ihm.
13 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú, Nebusaradani balógun ìṣọ́, àti Nebusaradani olórí ìwẹ̀fà, àti Nergali-Ṣareseri, olórí amòye àti gbogbo àwọn ìjòyè ọba Babeli,
Da sandte hin Nebusar-Adan, der Hauptmann, und Nebu-Sasban, der oberste Kämmerer, Nergal-Sarezer, der Hofmeister, und alle Fürsten des Königs zu Babel
14 ránṣẹ́ láti mú Jeremiah kúrò nínú túbú. Wọ́n gbé e lọ fún Gedaliah ọmọ Ahikamu ọmọ Ṣafani láti mú padà lọ sí ilé àti máa wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.
und ließen Jeremia holen aus dem Vorhofe des Gefängnisses und befahlen ihn Gedalja, dem Sohn Ahikams, des Sohns Saphans, daß er ihn hinaus in sein Haus führete und bei dem Volk bliebe.
15 Nígbà tí Jeremiah wà nínú túbú, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ ọ́ wá wí pé:
Es war auch des HERRN Wort geschehen zu Jeremia, weil er noch im Vorhofe des Gefängnisses gefangen lag, und gesprochen:
16 “Lọ sọ fún Ebedimeleki ará Kuṣi, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: Èmi ṣetán láti mú ọ̀rọ̀ mi ṣẹ lórí ìlú yìí nípa àjálù kì í ṣe àlàáfíà. Ní àkókò náà ni yóò ṣẹ lójú rẹ.
Gehe hin und sage Ebed-Melech, dem Mohren: So spricht der HERR Zebaoth, der Gott Israels: Siehe, ich will meine Worte kommen lassen über diese Stadt zum Unglück und zu keinem Guten, und du sollst es sehen zur selbigen Zeit.
17 Ṣùgbọ́n, Èmi yóò gbà ọ́ lọ́jọ́ náà ni Olúwa wí. A kò ní fi ọ́ lé ọwọ́ àwọn tí o bẹ̀rù.
Aber dich will ich erretten zur selbigen Zeit, spricht der HERR, und sollst den Leuten nicht zuteil werden, vor welchen du dich fürchtest.
18 Èmi yóò gbà ọ́ là; o kò ní ṣubú láti ipa idà; ṣùgbọ́n ìwọ yóò sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ, nítorí pé ìwọ ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú mi, ni Olúwa wí.’”
Denn ich will dir davon helfen, daß du nicht durchs Schwert fallest, sondern sollst dein Leben wie eine Beute davonbringen, darum daß du mir vertrauet hast, spricht der HERR.

< Jeremiah 39 >