< Jeremiah 38 >

1 Ṣefatia ọmọ Mattani, Gedaliah ọmọ Paṣuri, Jehukali ọmọ Ṣelemiah, àti Paṣuri ọmọ Malkiah, gbọ́ ohun tí Jeremiah ń sọ fún àwọn ènìyàn nígbà tí ó sọ wí pé,
Et Shephatia, fils de Matthan, et Guedalia, fils de Pashkhur, et Jucal, fils de Shélémia, et Pashkhur, fils de Malkija, entendirent les paroles que Jérémie disait à tout le peuple, disant:
2 “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Ẹnikẹ́ni tó bá dúró nínú ìlú yìí yóò kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tó bá lọ sí Babeli yóò yè; yóò sá àsálà, yóò sì yè.’
Ainsi dit l’Éternel: Celui qui demeurera dans cette ville mourra par l’épée, par la famine, ou par la peste; et celui qui sortira vers les Chaldéens vivra, et aura sa vie pour butin et vivra.
3 Àti pé èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Ìdánilójú wà wí pé a ó fi ìlú náà lé ọwọ́ àwọn ọmọ-ogun ọba Babeli; tí yóò sì kó wa nígbèkùn.’”
Ainsi dit l’Éternel: Cette ville sera livrée certainement en la main de l’armée du roi de Babylone, et il la prendra.
4 Nígbà náà ni àwọn ìjòyè wí fún ọba pé, “Ó yẹ kí a pa ọkùnrin yìí; ó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ-ogun tókù nínú ìlú pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn nípa ohun tí ó ń sọ fún wọn. Ọkùnrin yìí kò fẹ́ ìre fún àwọn ènìyàn bí kò ṣe ìparun.”
Et les princes dirent au roi: Qu’on fasse donc mourir cet homme! car pourquoi rend-il lâches les mains des hommes de guerre qui sont de reste dans cette ville, et les mains de tout le peuple, en leur parlant selon ces paroles? car cet homme ne cherche point la prospérité de ce peuple, mais le mal.
5 Sedekiah ọba sì wí pé, “Ó wà lọ́wọ́ yín. Ọba kò lè ṣe ohunkóhun láti takò yín.”
Et le roi Sédécias dit: Voici, il est entre vos mains; car le roi ne peut rien contre vous.
6 Wọ́n gbé Jeremiah sọ sínú ihò Malkiah, ọmọ ọba, tí ó wà ní àgbàlá ilé túbú; wọ́n fi okùn sọ Jeremiah kalẹ̀ sí ìsàlẹ̀ ihò; kò sì ṣí omi nínú ihò náà bí kò ṣe ẹrọ̀fọ̀, Jeremiah sì rì sínú ẹrọ̀fọ̀ náà.
Et ils prirent Jérémie et le jetèrent dans la fosse de Malkija, fils d’Hammélec, laquelle était dans la cour de la prison; et ils descendirent Jérémie avec des cordes; et il n’y avait point d’eau dans la fosse, mais de la boue, et Jérémie enfonça dans la boue.
7 Ṣùgbọ́n, Ebedimeleki, ará Kuṣi ìjòyè nínú ààfin ọba gbọ́ pé wọ́n ti ju Jeremiah sínú kànga. Nígbà tí ọba jókòó ní ẹnu-bodè Benjamini.
Et Ébed-Mélec, l’Éthiopien, un eunuque, qui était dans la maison du roi, apprit qu’ils avaient mis Jérémie dans la fosse; et le roi était assis dans la porte de Benjamin.
8 Ebedimeleki jáde kúrò láàfin ọba, ó sì sọ fún un pé,
Et Ébed-Mélec sortit de la maison du roi, et parla au roi, disant:
9 “Olúwa mi ọba, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti ṣe ohun búburú sí Jeremiah wòlíì Ọlọ́run. Wọ́n ti gbé e sọ sínú kànga níbi tí kò sí oúnjẹ kankan nínú ìlú mọ́.”
Ô roi, mon seigneur! ces hommes ont mal fait dans tout ce qu’ils ont fait à Jérémie le prophète, qu’ils ont jeté dans la fosse; il mourra là où il est, à cause de la famine, car il n’y a plus de pain dans la ville.
10 Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Ebedimeleki ará Kuṣi pé, “Mú ọgbọ̀n ọkùnrin láti ibí pẹ̀lú rẹ, kí ẹ sì fa wòlíì Jeremiah sókè láti inú ihò, kí ó tó kú.”
Et le roi commanda à Ébed-Mélec, l’Éthiopien, disant: Prends d’ici 30 hommes sous tes ordres, et fais monter Jérémie le prophète hors de la fosse, avant qu’il meure.
11 Ebedimeleki kó àwọn ọkùnrin náà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n lọ sínú yàrá kan nínú ààfin ọba. Ó mú àwọn aṣọ àkísà àti okùn tọ Jeremiah lọ nínú kànga.
Et Ébed-Mélec prit les hommes sous ses ordres, et alla dans la maison du roi, au-dessous du trésor. Et il prit de là de vieux lambeaux d’étoffes et de vieux haillons, et les descendit avec des cordes à Jérémie dans la fosse;
12 Ebedimeleki ará Kuṣi sọ fún Jeremiah pé, “Fi àkísà àti okùn bọ abẹ́ abíyá rẹ, Jeremiah sì ṣe bẹ́ẹ̀.”
et Ébed-Mélec, l’Éthiopien, dit à Jérémie: Mets ces vieux lambeaux et ces haillons sous les aisselles de tes bras, sous les cordes. Et Jérémie fit ainsi.
13 Báyìí ni wọ́n ṣe fi okùn yọ Jeremiah jáde, wọ́n sì mu un gòkè láti inú ihò wá, Jeremiah sì wà ní àgbàlá ilé túbú.
Et ils tirèrent Jérémie dehors avec les cordes, et le firent monter hors de la fosse. Et Jérémie habita dans la cour de la prison.
14 Nígbà náà ni ọba Sedekiah ránṣẹ́ pe, Jeremiah òjíṣẹ́ Ọlọ́run àti láti mú un wá sí ẹnu ibodè kẹta nílé Olúwa. Ọba sì sọ fún Jeremiah pé, “Èmi yóò bi ọ́ ní ohun kan; má sì ṣe fi ohun kan pamọ́ fún mi.”
Et le roi Sédécias envoya, et se fit amener Jérémie le prophète, à la troisième entrée qui était dans la maison de l’Éternel. Et le roi dit à Jérémie: Je te demanderai une chose; ne me cache rien.
15 Jeremiah sì sọ fún Sedekiah pé, “Tí mo bá fún ọ ní èsì, ṣé o kò nípa mí? Tí mo bá gbà ọ́ nímọ̀ràn, o kò ní gbọ́ tèmi.”
Et Jérémie dit à Sédécias: Si je te le déclare, ne me feras-tu pas mourir? Et si je te donne un conseil, tu ne m’écouteras pas.
16 Ṣùgbọ́n ọba Sedekiah búra ní ìkọ̀kọ̀ fún Jeremiah wí pé, “Dájúdájú bí Olúwa ti ń bẹ, ẹni tí ó fún wa ní ẹ̀mí, èmi kò nípa ọ́ tàbí fà ọ́ fún àwọn tó ń lépa ẹ̀mí rẹ.”
Et le roi Sédécias jura secrètement à Jérémie, disant: L’Éternel est vivant qui a fait notre âme: si je te fais mourir, et si je te livre en la main de ces hommes qui cherchent ta vie!
17 Nígbà náà ni Jeremiah sọ fún Sedekiah pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run alágbára, Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Àyàfi bí o bá jọ̀wọ́ ara rẹ fún àwọn olóyè ọba Babeli, a ó dá ẹ̀mí rẹ sí àti pé ìlú yìí kò ní di jíjó ní iná; ìwọ àti ilé rẹ yóò sì wà láààyè.
Et Jérémie dit à Sédécias: Ainsi dit l’Éternel, le Dieu des armées, le Dieu d’Israël: Si tu sors franchement vers les princes du roi de Babylone, ton âme vivra et cette ville ne sera point brûlée par le feu, mais tu vivras, toi et ta maison.
18 Ṣùgbọ́n tí o kò bá jọ̀wọ́ ara rẹ fún àwọn ìjòyè ọba Babeli, a ó fa ìlú yìí lé ọwọ́ àwọn Babeli. Wọn yóò sì fi iná sun ún, ìwọ gan an kò ní le sá mọ́ wọn lọ́wọ́.’”
Mais si tu ne sors pas vers les princes du roi de Babylone, cette ville sera livrée en la main des Chaldéens, et ils la brûleront par le feu; et toi, tu n’échapperas pas à leur main.
19 Ọba Sedekiah sọ fún Jeremiah pé, “Mò ń bẹ̀rù àwọn Júù tó ti sálọ sí ilẹ̀ Babeli, nítorí pé àwọn ará Babeli lè fà mí lé wọn lọ́wọ́ láti fìyà jẹ mí.”
Et le roi Sédécias dit à Jérémie: Je crains les Juifs qui se sont rendus aux Chaldéens; [j’ai] peur qu’on ne me livre en leur main, et qu’ils ne me maltraitent.
20 Jeremiah sì dáhùn wí pé, “Wọn kò ní fi ọ́ lé e lọ́wọ́. Pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́ nípa ṣíṣe ohun tí mo sọ fún ọ; yóò sì dára fún ọ, ẹ̀mí rẹ yóò sì wà.
Et Jérémie dit: On ne te livrera point; écoute, je te prie, la voix de l’Éternel dans ce que je te dis, et tout ira bien pour toi, et ton âme vivra.
21 Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá kọ̀ láti jọ̀wọ́ ara rẹ, èyí ni ohun tí Olúwa ti fihàn mí.
Mais si tu refuses de sortir, voici la parole que l’Éternel m’a fait voir:
22 Gbogbo àwọn obìnrin tókù ní ààfin ọba Juda ni wọn yóò kó jáde fún àwọn ìjòyè ọba Babeli. Àwọn obìnrin náà yóò sì sọ fún ọ pé: “‘Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì borí rẹ. Ẹsẹ̀ rẹ rì sínú ẹrọ̀fọ̀; àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti fi ọ́ sílẹ̀.’
Voici, toutes les femmes qui sont de reste dans la maison du roi de Juda seront menées dehors vers les princes du roi de Babylone, et elles diront: Tes familiers t’ont entraîné, ils ont prévalu sur toi; tes pieds se sont enfoncés dans le bourbier, ils ont glissé en arrière.
23 “Wọn yóò kó àwọn ìyàwó àti ọmọ rẹ wá sí Babeli. Ìwọ gan an kò ní bọ́ níbẹ̀, ọba Babeli yóò mú ọ, wọn yóò sì jó ìlú yìí kanlẹ̀.”
Et toutes tes femmes et tes fils, on les mènera dehors vers les Chaldéens, et toi tu n’échapperas pas à leur main; car tu seras pris par la main du roi de Babylone, et tu feras que cette ville sera brûlée par le feu.
24 Nígbà náà ni Sedekiah sọ fún Jeremiah pé, “Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí, tàbí kí o kú.
Et Sédécias dit à Jérémie: Que personne ne sache rien de ces paroles, et tu ne mourras pas;
25 Tí àwọn ìjòyè bá mọ̀ pé mo bá ọ sọ̀rọ̀, tí wọ́n bá wá bá ọ wí pé, ‘Sọ fún wa ohun tí o bá ọba sọ tàbí ohun tí ọba sọ fún ọ; má ṣe fi pamọ́ fún wa tàbí kí a pa ọ́,’
et si les princes entendent que j’ai parlé avec toi, et qu’ils viennent vers toi et te disent: Déclare-nous donc ce que tu as dit au roi; ne nous le cache pas, et nous ne te ferons point mourir; et que t’a dit le roi?
26 nígbà náà kí o sọ fún wọn, ‘Mò ń bẹ ọba láti má jẹ́ kí n padà lọ sí ilé Jonatani láti lọ kú síbẹ̀.’”
tu leur diras: J’ai présenté ma requête devant le roi, qu’on ne me fasse pas retourner dans la maison de Jonathan pour y mourir. –
27 Gbogbo àwọn olóyè sì wá sí ọ̀dọ̀ Jeremiah láti bi í léèrè, ó sì sọ gbogbo ohun tí ọba ní kí ó sọ. Wọn kò sì sọ ohunkóhun mọ́, nítorí kò sí ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí òun àti ọba jọ sọ.
Et tous les princes vinrent vers Jérémie, et l’interrogèrent; et il leur rapporta [la chose] selon toutes ces paroles que le roi avait commandées; et ils se turent et le laissèrent, car l’affaire ne s’ébruita pas.
28 Jeremiah wà nínú àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́ títí di ọjọ́ tí wọ́n fi kó Jerusalẹmu:
Et Jérémie habita dans la cour de la prison jusqu’au jour où Jérusalem fut prise. Et il arriva, lorsque Jérusalem fut prise,

< Jeremiah 38 >