< Jeremiah 37 >
1 Sedekiah ọmọ Josiah sì jẹ ọba ní ipò Jehoiakini ọmọ Jehoiakimu ẹni tí Nebukadnessari ọba Babeli fi jẹ ọba ní ilẹ̀ Juda.
Et regnavit rex Sedecias filius Josiæ pro Jechonia filio Joakim, quem constituit regem Nabuchodonosor rex Babylonis in terra Juda:
2 Ṣùgbọ́n àti òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà kò fetísí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ nípa wòlíì Jeremiah.
et non obedivit ipse, et servi ejus, et populus terræ, verbis Domini, quæ locutus est in manu Jeremiæ prophetæ.
3 Sedekiah ọba sì rán Jehukali ọmọ Ṣelemiah àti Sefaniah ọmọ Maaseiah sí Jeremiah wòlíì wí pé, “Jọ̀wọ́ gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run wa fún wa.”
Et misit rex Sedecias Juchal filium Selemiæ, et Sophoniam filium Maasiæ, sacerdotem, ad Jeremiam prophetam, dicens: Ora pro nobis Dominum Deum nostrum.
4 Nígbà yìí Jeremiah sì ń wọlé, ó sì ń jáde láàrín àwọn ènìyàn nítorí wọ́n ti fi sínú túbú.
Jeremias autem libere ambulabat in medio populi: non enim miserant eum in custodiam carceris.
5 Àwọn ọmọ-ogun Farao ti jáde kúrò nílẹ̀ Ejibiti àti nígbà tí àwọn ará Babeli tó ń ṣàtìpó ní Jerusalẹmu gbọ́ ìròyìn nípa wọn, wọ́n kúrò ní Jerusalẹmu.
Igitur exercitus Pharaonis egressus est de Ægypto, et audientes Chaldæi qui obsidebant Jerusalem, hujuscemodi nuntium, recesserunt ab Jerusalem.
6 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wòlíì Ọlọ́run wá:
Et factum est verbum Domini ad Jeremiam prophetam, dicens:
7 “Èyí ni, ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Israẹli sọ fún ọba àwọn Juda tó rán ọ láti wádìí nípa mi. ‘Àwọn ọmọ-ogun Farao tó jáde láti kún ọ lọ́wọ́ yóò padà sílẹ̀ wọn sí Ejibiti.
Hæc dicit Dominus Deus Israël: Sic dicetis regi Juda, qui misit vos ad me interrogandum: Ecce exercitus Pharaonis, qui egressus est vobis in auxilium, revertetur in terram suam in Ægyptum:
8 Nígbà náà ni àwọn ará Babeli yóò padà láti gbógun ti ìlú. Wọn yóò mú wọn nígbèkùn, wọn yóò sì fi iná jó ìlú náà kanlẹ̀.’
et redient Chaldæi, et bellabunt contra civitatem hanc, et capient eam, et succendent eam igni.
9 “Èyí ni ohun tí Olúwa wí, ẹ má ṣe tan ara yín jẹ ní èrò wí pé, ‘Àwọn ará Babeli yóò fi wá sílẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú.’ Wọn kò ní ṣe bẹ́ẹ̀.
Hæc dicit Dominus: Nolite decipere animas vestras, dicentes: Euntes abibunt, et recedent a nobis Chaldæi: quia non abibunt.
10 Kódà tó bá ṣe pé wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọmọ-ogun Babeli tí ń gbóguntì yín àti àwọn tí ìjàǹbá ṣe, tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ní ibùdó wọn; wọn yóò jáde láti jó ìlú náà kanlẹ̀.”
Sed etsi percusseritis omnem exercitum Chaldæorum qui præliantur adversum vos, et derelicti fuerint ex eis aliqui vulnerati, singuli de tentorio suo consurgent, et incendent civitatem hanc igni.
11 Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ-ogun Babeli ti kúrò ní Jerusalẹmu nítorí àwọn ọmọ-ogun Farao.
Ergo cum recessisset exercitus Chaldæorum ab Jerusalem, propter exercitum Pharaonis,
12 Jeremiah múra láti fi ìlú náà sílẹ̀, láti lọ sí olú ìlú Benjamini láti gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ nínú ohun ìní láàrín àwọn ènìyàn tó wà níbẹ̀.
egressus est Jeremias de Jerusalem ut iret in terram Benjamin, et divideret ibi possessionem in conspectu civium.
13 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ẹnu ibodè Benjamini, olórí àwọn olùṣọ́ tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Irijah ọmọ Ṣelemiah ọmọ Hananiah mú un, ó wí pé, “Ìwọ ń fi ara mọ́ àwọn ará Babeli.”
Cumque pervenisset ad portam Benjamin, erat ibi custos portæ per vices, nomine Jerias filius Selemiæ filii Hananiæ: et apprehendit Jeremiam prophetam, dicens: Ad Chaldæos profugis.
14 Jeremiah sọ wí pé, “Èyí kì í ṣe òtítọ́! Èmi kò yapa sí àwọn ará Babeli.” Ṣùgbọ́n Irijah ko gbọ́ tirẹ̀, dípò èyí a mú Jeremiah, ó sì mú un lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ìjòyè.
Et respondit Jeremias: Falsum est: non fugio ad Chaldæos. Et non audivit eum, sed comprehendit Jerias Jeremiam, et adduxit eum ad principes:
15 Nítorí náà ni àwọn ìjòyè ṣe bínú sí Jeremiah, wọ́n jẹ ẹ́ ní yà, wọ́n tún fi sí túbú nílé Jonatani akọ̀wé nítorí wọ́n ti fi èyí ṣe ilé túbú.
quam ob rem irati principes contra Jeremiam, cæsum eum miserunt in carcerem qui erat in domo Jonathan scribæ: ipse enim præpositus erat super carcerem.
16 Wọ́n fi Jeremiah sínú túbú tí ó ṣókùnkùn biribiri; níbi tí ó wà fún ìgbà pípẹ́.
Itaque ingressus est Jeremias in domum laci et in ergastulum: et sedit ibi Jeremias diebus multis.
17 Nígbà náà ni ọba Sedekiah ránṣẹ́ sí i, tí ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú wá sí ààfin níbi tí ó ti bi í ní ìkọ̀kọ̀ pé, “Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ kan wà láti ọ̀dọ̀ Olúwa?” Jeremiah fèsì pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, wọn ó fi ọ́ lé ọwọ́ ọba Babeli.”
Mittens autem Sedecias rex, tulit eum: et interrogavit eum in domo sua abscondite, et dixit: Putasne est sermo a Domino? Et dixit Jeremias: Est: et ait: In manus regis Babylonis traderis.
18 Nígbà náà, Jeremiah sọ fún ọba Sedekiah pé, “Irú ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ yín, àwọn ìjòyè yín pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ẹ fi sọ mí sínú túbú?
Et dixit Jeremias ad regem Sedeciam: Quid peccavi tibi, et servis tuis, et populo tuo, quia misisti me in domum carceris?
19 Níbo ni àwọn wòlíì yín tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún un yín wí pé ọba Babeli kò ní gbóguntì yín wá?
ubi sunt prophetæ vestri, qui prophetabant vobis, et dicebant: Non veniet rex Babylonis super vos, et super terram hanc?
20 Ṣùgbọ́n ní báyìí, olúwa mi ọba, èmí bẹ̀ ọ. Jẹ́ kí n mú ẹ̀dùn ọkàn mi tọ̀ ọ́ wá; má ṣe rán mi padà sí ilé Jonatani akọ̀wé, àfi kí n kú síbẹ̀.”
Nunc ergo audi, obsecro, domine mi rex: valeat deprecatio mea in conspectu tuo, et ne me remittas in domum Jonathan scribæ, ne moriar ibi.
21 Ọba Sedekiah wá pàṣẹ pé kí wọ́n fi Jeremiah sínú àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́, àti kí wọn sì fún ní àkàrà ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan títí tí àkàrà tó wà ní ìlú yóò fi tán; bẹ́ẹ̀ ni Jeremiah wà nínú àgbàlá náà.
Præcepit ergo rex Sedecias ut traderetur Jeremias in vestibulo carceris, et daretur ei torta panis quotidie, excepto pulmento, donec consumerentur omnes panes de civitate: et mansit Jeremias in vestibulo carceris.