< Jeremiah 35 >
1 Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa ní ọjọ́ Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda wí pé:
The word that came to Jeremiah from Yahweh in the days of Jehoiakim son of Josiah king of Judah, saying,
2 “Lọ sí ilé àwọn ọmọ Rekabu, kí o sì bá wọn sọ̀rọ̀, kí o sì mú wọn wá sí ilé Olúwa, sí ọ̀kan nínú iyàrá wọ̀n-ọn-nì, kí o sì fún wọn ní ọtí wáìnì mu.”
“Go to the family of the Rekabites and speak with them. Then bring them to my house, into one of the rooms there, and give them wine to drink.”
3 Nígbà náà ni mo mu Jaaṣaniah ọmọ Jeremiah, ọmọ Habasiniah àti àwọn arákùnrin rẹ̀; àti gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀, àti gbogbo ilé àwọn ọmọ Rekabu.
So I took Jaazaniah son of Jeremiah son of Habazziniah and his brothers, all his sons, and all the family of the Rekabites.
4 Mo sì mú wọn wá sí ilé Olúwa sínú iyàrá Hanani ọmọ Igdaliah, ènìyàn Ọlọ́run, tí ó wà lẹ́bàá yàrá àwọn ìjòyè, tí ó wà ní òkè yàrá Maaseiah, ọmọ Ṣallumu olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà.
I took them to the house of Yahweh, into the rooms of the sons of Hanan son of Igdaliah, the man of God. These rooms were beside the room of the leaders, which was above the room of Maaseiah son of Shallum, the gatekeeper.
5 Mo sì gbé ìkòkò tí ó kún fún ọtí wáìnì pẹ̀lú ago ka iwájú àwọn ọmọ Rekabu. Mo sì wí fún wọn pé, “Mu ọtí wáìnì.”
Then I placed bowls and cups full of wine in front of the Rekabites and said to them, “Drink some wine.”
6 Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé, “Àwa kì yóò mu ọtí wáìnì nítorí Jonadabu ọmọ Rekabu, baba wa pàṣẹ fún wa pé: ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín láéláé.
But they said, “We will not drink any wine, for our ancestor, Jonadab son of Rekab, commanded us, 'Do not drink any wine, neither you nor your descendants, forever.
7 Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kọ́ ilé tàbí kí ẹ fúnrúgbìn, tàbí kí ẹ gbin ọgbà àjàrà. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ní ọ̀kankan nínú àwọn ohun wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ní gbogbo ọjọ́ yín ni ẹ̀yin ó máa gbé inú àgọ́; kí ẹ̀yin kí ó lè wá ní ọjọ́ púpọ̀ ní ilẹ̀ náà; níbi tí ẹ̀yin ti ń ṣe àtìpó.’
Also, do not build any houses, sow any seeds, or plant any vineyards; this is not for you. For you must live in tents all your days, so that you might live many days in the land where you are staying as foreigners.'
8 Báyìí ni àwa gba ohùn Jehonadabu ọmọ Rekabu baba wa gbọ́ nínú gbogbo èyí tí ó pàṣẹ fún wa, kí a má mu ọtí wáìnì ní gbogbo ọjọ́ ayé wa; àwa, àwọn aya wa, àwọn ọmọkùnrin wa, àti àwọn ọmọbìnrin wa.
We have obeyed the voice of Jonadab son of Rekab, our ancestor, in all that he commanded us, to never drink wine all of our days, we, our wives, our sons, and our daughters.
9 Àti kí a má kọ́ ilé láti gbé; bẹ́ẹ̀ ni àwa kò ní ọgbà àjàrà tàbí oko, tàbí ohun ọ̀gbìn.
We will never build houses to live in, and there will be no vineyard, field, or seed in our possession.
10 Ṣùgbọ́n àwa ń gbé inú àgọ́, a sì gbọ́rọ̀, a sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Jonadabu baba wa pàṣẹ fún wa.
We have lived in tents and we have obeyed and done all that Jonadab our ancestor commanded us.
11 Ó sì ṣe, nígbà tí Nebukadnessari ọba Babeli gòkè wá sí ilẹ̀ náà; àwa wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Jerusalẹmu, nítorí ìbẹ̀rù ogun àwọn ara Siria.’ Bẹ́ẹ̀ ni àwa sì ń gbé Jerusalẹmu.”
But when Nebuchadnezzar king of Babylon attacked the land, we said, 'Come, we must go to Jerusalem to escape from the Chaldean and Aramean armies.' So we are living in Jerusalem.”
12 Nígbà yìí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé:
Then the word of Yahweh came to Jeremiah, saying,
13 “Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí pé, lọ, kí o sì sọ fún àwọn ọkùnrin Juda, àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò ha gba ẹ̀kọ́ láti fetí sí ọ̀rọ̀ mi,’ ni Olúwa wí.
“Yahweh of hosts, God of Israel, says this, 'Go and say to the men of Judah and the inhabitants of Jerusalem, “Will you not receive correction and listen to my words? —this is Yahweh's declaration.
14 ‘Ọ̀rọ̀ Jehonadabu ọmọ Rekabu tí ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì, ni a mú ṣẹ, wọn kò sì mu ọtí wáìnì títí di òní yìí, nítorí tí wọ́n gba òfin baba wọn. Èmi sì ti ń sọ̀rọ̀ fún un yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi.
The words of Jonadab son of Rekab that he gave to his sons as a command, not to drink any wine, have been observed to this very day. They have obeyed their ancestor's command. But as for me, I myself have been making persistent proclamations to you, but you do not listen to me.
15 Èmi rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ àti àwọn wòlíì mí sí yín pẹ̀lú wí pé, “Ẹ yípadà nísinsin yìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín, kí ẹ sì tún ìṣe yín ṣe sí rere. Kí ẹ ma sì ṣe bọ òrìṣà tàbí sìn wọ́n; ẹ̀yin ó sì máa gbé ní ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín àti fún àwọn baba ńlá yín.” Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi.
I sent out to you all my servants, the prophets. I was persistent in sending them to say, 'Let each person turn from his wicked way and do good deeds; let no one walk any longer after other gods and worship them. Instead, come back to the land that I gave to you and your ancestors.' Yet you will not listen to me or pay attention to me.
16 Nítòótọ́, àwọn ọmọ Jehonadabu ọmọ Rekabu pa òfin baba wọn mọ́ tí ó pàṣẹ fún wọn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò pa òfin mi mọ́.’
For the descendants of Jonadab son of Rekab have observed the commands of their ancestor that he gave them, but this people refuses to listen to me.”'
17 “Nítorí náà, báyìí ni, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí, ‘Fetísílẹ̀! Èmi ó mú gbogbo ohun búburú tí èmi ti sọ wá sórí Juda, àti sórí gbogbo olùgbé Jerusalẹmu nítorí èmi ti bá wọn sọ̀rọ̀: Ṣùgbọ́n wọn kò sì dáhùn.’”
So Yahweh, God of hosts and God of Israel, says this, 'Look, I am bringing upon Judah and on everyone living in Jerusalem, all the disasters I pronounced against them because I spoke to them, but they did not listen; I called to them, but they did not answer.'”
18 Nígbà náà ni Jeremiah wí fún ìdílé Rekabu pé, “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí pé: ‘Nítorí tí ẹ̀yin gba òfin Jehonadabu baba yín, tí ẹ sì pa gbogbo rẹ̀ mọ́, tí ẹ sì ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó pàṣẹ fún un yín.’
Jeremiah said to the family of the Rekabites, “Yahweh of hosts, God of Israel, says this: You have listened to the commands of Jonadab your ancestor and have kept them all—you have obeyed all that he commanded you to do—
19 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí, pé: ‘Jonadabu ọmọ Rekabu kì yóò fẹ́ ọkùnrin kan kù láti sìn mí.’”
so Yahweh of hosts, God of Israel, says this, 'There will always be someone descended from Jonadab son of Rekab to serve me.'”