< Jeremiah 30 >
1 Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, wí pé:
耶和华的话临到耶利米说:
2 “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí, pé: ‘Ìwọ kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti bá ọ sọ sínú ìwé kan.
“耶和华—以色列的 神如此说:你将我对你说过的一切话都写在书上。
3 Ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí ń ó mú àwọn ènìyàn mi, àwọn ọmọ Israẹli àti Juda kúrò nínú ìgbèkùn, tí n ó sì dá wọn padà sí orí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá wọn láti ní,’ ni Olúwa Ọlọ́run wí.”
耶和华说:日子将到,我要使我的百姓以色列和犹大被掳的人归回;我也要使他们回到我所赐给他们列祖之地,他们就得这地为业。这是耶和华说的。”
4 Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run sí Israẹli àti Juda:
以下是耶和华论到以色列和犹大所说的话:
5 “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “‘Igbe ẹ̀rù àti ìwárìrì ni a gbọ́ láìṣe igbe àlàáfíà.
耶和华如此说:我们听见声音, 是战抖惧怕而不平安的声音。
6 Béèrè kí o sì rí. Ǹjẹ́ ọkùnrin le dá ọmọ bí? Èéṣe tí mo fi ń rí àwọn alágbára ọkùnrin tí wọ́n fi ọwọ́ wọn mú inú wọn bí obìnrin tó ń rọbí, tí ojú gbogbo wọ́n sì fàro fún ìrora?
你们且访问看看, 男人有产难吗? 我怎么看见人人用手掐腰, 像产难的妇人, 脸面都变青了呢?
7 Ọjọ́ náà yóò ha ti burú tó! Kò sí ọjọ́ tí yóò dàbí rẹ̀, Ọjọ́ náà yóò jẹ́ àkókò ìdààmú fún Jakọbu ṣùgbọ́n yóò rí ìgbàlà kúrò nínú ìdààmú náà.
哀哉!那日为大, 无日可比; 这是雅各遭难的时候, 但他必被救出来。
8 “‘Ní ọjọ́ náà,’ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Èmi yóò gbé àjàgà kúrò lọ́rùn wọn, Èmi yóò sì tú ìdè wọn sọnù. Àwọn àjèjì kì yóò sì mú ọ sìn wọ́n mọ́.
万军之耶和华说:“到那日,我必从你颈项上折断仇敌的轭,扭开他的绳索;外邦人不得再使你作他们的奴仆。
9 Dípò bẹ́ẹ̀ wọn yóò máa sin Olúwa Ọlọ́run wọn àti Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba wọn, ẹni tí èmi yóò gbé dìde fún wọn.
你们却要事奉耶和华—你们的 神和我为你们所要兴起的王大卫。”
10 “‘Nítorí náà, má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi, má sì ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, ìwọ Israẹli,’ ni Olúwa wí. ‘Èmi yóò gbà ọ́ kúrò láti ọ̀nà jíjìn wá, àní àwọn ìran rẹ láti ilẹ̀ àtìpó wọn. Jakọbu yóò sì tún ní àlàáfíà àti ààbò rẹ̀ padà, kò sì ṣí ẹni tí yóò ṣẹ̀rù bà á mọ́.
故此,耶和华说: 我的仆人雅各啊,不要惧怕; 以色列啊,不要惊惶; 因我要从远方拯救你, 从被掳到之地拯救你的后裔; 雅各必回来得享平靖安逸, 无人使他害怕。
11 Èmi wà pẹ̀lú rẹ, n ó sì gbà ọ́,’ ni Olúwa wí. ‘Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run, nínú èyí tí mo ti fọ́n ọn yín ká, síbẹ̀ èmi kì yóò pa yín run pátápátá. Èmi yóò bá yín wí pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo nìkan; Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìjìyà.’
因我与你同在,要拯救你, 也要将所赶散你到的那些国灭绝净尽, 却不将你灭绝净尽,倒要从宽惩治你, 万不能不罚你。 这是耶和华说的。
12 “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “‘Ọgbẹ́ yín kò gbóògùn, bẹ́ẹ̀ ni egbò yín kọjá ìwòsàn.
耶和华如此说: 你的损伤无法医治; 你的伤痕极其重大。
13 Kò sí ẹnìkan tí yóò bẹ̀bẹ̀ fún àìṣedéédéé yín, kò sí ètùtù fún ọgbẹ́ yín, a kò sì mú yín láradá.
无人为你分诉, 使你的伤痕得以缠裹; 你没有医治的良药。
14 Gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ ti gbàgbé rẹ, wọn kò sì náání rẹ mọ́ pẹ̀lú. Mo ti nà ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá rẹ yóò ti nà ọ, mo sì bá a ọ wí gẹ́gẹ́ bí ìkà, nítorí tí ẹ̀bi rẹ pọ̀ púpọ̀, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò sì lóǹkà.
你所亲爱的都忘记你, 不来探问你。 我因你的罪孽甚大,罪恶众多, 曾用仇敌加的伤害伤害你, 用残忍者的惩治惩治你。
15 Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń kígbe nítorí ọgbẹ́ yín, ìrora yín èyí tí kò ní oògùn? Nítorí ọ̀pọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ẹ̀bi yín tó ga ni mo fi ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí i yín.
你为何因损伤哀号呢? 你的痛苦无法医治。 我因你的罪孽甚大,罪恶众多, 曾将这些加在你身上。
16 “‘Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe yín ní ibi ni ibi yóò bá, àní gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni a ó sọ di àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì; gbogbo àwọn tí wọ́n bà yín jẹ́ ni a ó bàjẹ́.
故此,凡吞吃你的必被吞吃; 你的敌人个个都被掳去; 掳掠你的必成为掳物; 抢夺你的必成为掠物。
17 Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìlera fún yín, èmi yóò sì wo ọ̀gbẹ́ yín sàn,’ ni Olúwa wí, ‘nítorí tí a pè yín ní alárìnkiri, Sioni tí gbogbo ènìyàn dágunlá sí.’
耶和华说:我必使你痊愈, 医好你的伤痕, 都因人称你为被赶散的, 说:这是锡安,无人来探问的!
18 “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “‘Èmi yóò dá gbogbo ìre àgọ́ Jakọbu padà, èmi yóò sì ṣe àánú fún olùgbé àgọ́ rẹ̀; ìlú náà yóò sì di títúnṣe tí ààfin ìlú náà yóò sì wà ní ipò rẹ̀.
耶和华如此说: 我必使雅各被掳去的帐棚归回, 也必顾惜他的住处。 城必建造在原旧的山冈; 宫殿也照旧有人居住。
19 Láti ẹnu wọn ni orin ọpẹ́ àti ìyìn yóò sì ti máa jáde. Èmi yóò sọ wọ́n di púpọ̀, wọn kì yóò sì dínkù ní iye, Èmi yóò fi ọlá fún wọn, wọn kò sì ní di ẹni àbùkù.
必有感谢和欢乐的声音从其中发出, 我要使他们增多,不致减少; 使他们尊荣,不致卑微。
20 Ọmọ ọmọ wọn yóò wà bí i ti ìgbàanì níwájú mi ni wọn yóò sì tẹ àwùjọ wọn dúró sí. Gbogbo ẹni tó bá ni wọ́n lára, ni èmi yóò fì ìyà jẹ.
他们的儿女要如往日; 他们的会众坚立在我面前; 凡欺压他们的,我必刑罚他。
21 Ọ̀kan nínú wọn ni yóò jẹ́ olórí wọn, ọba wọn yóò dìde láti àárín wọn. Èmi yóò mú un wá sí ọ̀dọ̀ mi, òun yóò sì súnmọ́ mi, nítorí ta ni ẹni náà tí yóò fi ara rẹ̀ jì láti súnmọ́ mi?’ ni Olúwa wí.
他们的君王必是属乎他们的; 掌权的必从他们中间而出。 我要使他就近我, 他也要亲近我; 不然,谁有胆量亲近我呢? 这是耶和华说的。
22 ‘Nítorí náà, ẹ̀yin yóò jẹ́ ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín.’”
你们要作我的子民, 我要作你们的 神。
23 Wò ó, ìbínú Olúwa yóò tú jáde, ìjì líle yóò sì sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn ènìyàn búburú.
看哪,耶和华的忿怒 好像暴风已经发出; 是扫灭的暴风, 必转到恶人的头上。
24 Ìbínú ńlá Olúwa kò ní dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn ìkà títí yóò fi mú èrò ọkàn rẹ̀ ṣẹ. Ní àìpẹ́ ọjọ́, òye rẹ̀ yóò yé e yín.
耶和华的烈怒必不转消, 直到他心中所拟定的成就了; 末后的日子你们要明白。