< Jeremiah 3 >

1 “Bí ọkùnrin kan bá sì kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ tí obìnrin náà sì lọ fẹ́ ọkọ mìíràn, ǹjẹ́ ọkùnrin náà tún lè tọ̀ ọ́ wá? Ǹjẹ́ ilẹ̀ náà kò ní di aláìmọ́ bí? Ṣùgbọ́n ìwọ ti gbé pẹ̀lú onírúurú panṣágà gẹ́gẹ́ bí olùfẹ́, ṣé ìwọ yóò tún padà sọ́dọ̀ mi bí?” ni Olúwa wí.
Il est dit: Lorsqu’un homme répudie sa femme, et qu’après l’avoir quittée, elle devient la femme d’un autre, cet homme retournera-t-il encore vers elle? Cette terre ne serait-elle pas vraiment profanée? Et toi, tu t’es prostituée à de nombreux amants; et tu reviendras vers moi! — oracle de Yahweh.
2 “Gbé ojú rẹ sókè sí ibi gíga wọ̀n-ọn-nì, kí o sì wò ó ibi kan ha wà tí a kò bà ọ́ jẹ́? Ní ojú ọ̀nà, ìwọ jókòó de àwọn olólùfẹ́, bí i ará Arabia kan nínú aginjù, ìwọ sì ti ba ilẹ̀ náà jẹ́ pẹ̀lú ìwà àgbèrè àti ìwà búburú rẹ.
Lève les yeux vers les hauteurs et regarde: où n’as-tu pas été souillée?… Tu t’asseyais pour eux sur les routes, pareille à l’Arabe dans le désert! Et tu as profané le pays par tes prostitutions et par ta méchanceté;
3 Nítorí náà, a ti fa ọ̀wààrà òjò sẹ́yìn, kò sì ṣí òjò àrọ̀kúrò. Síbẹ̀ ìwọ ní ojú líle ti panṣágà, ìwọ sì kọ̀ láti ní ìtìjú.
les ondées de l’automne ont été retenues, les pluies du printemps ont manqué. Mais tu as eu un front de courtisane, tu n’as pas voulu rougir.
4 Ǹjẹ́ ìwọ kò ha a pè mí láìpẹ́ yìí pé, ‘Baba mi, ìwọ ọ̀rẹ́ mi láti ìgbà èwe mi.
Et maintenant, n’est-ce pas, tu me dis: « Mon père, ô vous, l’ami de ma jeunesse! Sera-t-il toujours irrité,
5 Ìwọ yóò ha máa bínú títí? Ìbínú rẹ yóò ha máa lọ títí láé?’ Báyìí ni o ṣe ń sọ̀rọ̀ ìwọ ṣe gbogbo ibi tí ìwọ le ṣe.”
gardera-t-il à jamais son courroux? » Voilà ce que tu dis, et tu commets le crime et tu le consommes.
6 Ní àkókò ìjọba Josiah ọba, Olúwa wí fún mi pé, “Ṣé o ti rí nǹkan tí àwọn Israẹli aláìnígbàgbọ́ ti ṣe? Wọ́n ti lọ sí àwọn òkè gíga àti sí abẹ́ àwọn igi, wọ́n sì ti ṣe àgbèrè níbẹ̀.
Yahweh me dit aux jours du roi Josias: As-tu vu ce qu’à fait Israël l’infidèle? Elle est allée sur toute montagne élevée et sous tout arbre vert, et s’y est prostituée.
7 Mo rò pé nígbà tí wọ́n ti ṣe èyí wọn yóò padà, wọn kò padà, Juda aláìgbàgbọ́ arábìnrin rẹ̀ náà sì rí i.
Et j’ai dit: Après avoir fait toutes ces choses, elle reviendra à moi! Mais elle n’est pas revenue. Et sa sœur, Juda la perfide, a vu cela;
8 Mo fún Israẹli aláìnígbàgbọ́ ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀, mo sì ké wọn kúrò nítorí gbogbo àgbèrè wọn. Síbẹ̀ mo rí pé Juda tí ó jẹ́ arábìnrin rẹ̀ kò bẹ̀rù, òun náà sì jáde lọ láti lọ ṣe àgbèrè.
Et j’ai vu qu’à cause de tous ses adultères, j’ai répudié Israël l’infidèle, et que je lui ai donné sa lettre de divorce; et sa sœur, Juda la perfide, n’a pas été effrayée, et elle est allée se prostituer, elle aussi.
9 Nítorí ìwà èérí Israẹli kò jọ ọ́ lójú, ó ti ba ilẹ̀ jẹ́, ó sì ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú òkúta àti igi.
Par sa bruyante impudicité, elle a profané le pays, et elle a commis l’adultère avec le bois et la pierre.
10 Látàrí gbogbo nǹkan wọ̀nyí Juda arábìnrin rẹ̀ aláìgbàgbọ́ kò padà tọ̀ mí wá pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀, bí kò ṣe nípa fífarahàn bí olóòtítọ́,” ni Olúwa wí.
Et avec tout cela sa sœur, Juda la perfide, n’est pas revenue à moi de tout son cœur, mais avec mensonge, — oracle de Yahweh.
11 Olúwa wí fún mi pé, “Israẹli aláìnígbàgbọ́ ṣe òdodo ju Juda tí ó ní ìgbàgbọ́ lọ.
Et Yahweh me dit: Israël l’infidèle s’est montrée juste, en comparaison de Juda la perfide.
12 Lọ polongo ọ̀rọ̀ náà, lọ sí ìhà àríwá: “‘Yípadà, Israẹli aláìnígbàgbọ́,’ ni Olúwa wí. ‘Ojú mi kì yóò korò sí ọ mọ́, nítorí mo jẹ́ aláàánú, ni Olúwa wí. Èmi kì yóò sì bínú mọ́ títí láé.
Va, et crie ces paroles du côté du septentrion et dis: Reviens, infidèle Israël, — oracle de Yahweh; Je ne veux pas vous montrer un visage sévère, car je suis miséricordieux, — oracle de Yahweh, et je ne garde pas ma colère à toujours.
13 Sá à ti mọ ẹ̀bi rẹ, ìwọ ti ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ, ìwọ ti wá ojúrere rẹ lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjì lábẹ́ gbogbo igikígi tí ó gbilẹ̀, ẹ̀yin kò gba ohun mi gbọ́,’” ni Olúwa wí.
Seulement reconnais ta faute, car tu as été infidèle à Yahweh, ton Dieu, et tu as prodigué tes pas vers les étrangers, sous ton arbre vert, et vous n’avez pas écouté ma voix, — oracle de Yahweh.
14 “Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́,” ni Olúwa wí, “nítorí èmi ni ọkọ rẹ. Èmi ó yàn ọ́, ọ̀kan láti ìlú àti méjì láti ẹ̀yà. Èmi ó sì mú ọ wá sí Sioni.
Revenez, fils infidèles, — oracle de Yahweh, car je suis votre maître; et je vous prendrai, un d’une ville et deux d’une famille, et je vous amènerai dans Sion.
15 Lẹ́yìn èyí, èmi ó fún ọ ní àwọn olùṣọ́-àgùntàn láti inú ọkàn mi, tí wọn yóò ṣáájú yín pẹ̀lú òye àti ìmọ̀.
Et je vous donnerai des pasteurs selon mon cœur, qui vous paîtront avec intelligence et sagesse.
16 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, tí ẹ̀yin bá pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ náà,” ni Olúwa wí, “àwọn ènìyàn kò tún lè sọ pé, ‘Àpótí ẹ̀rí Olúwa.’ Kò ní wá sí ìrántí wọn mọ́, a kì yóò pàdánù rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò sì tún kan òmíràn mọ́.
Et quand vous aurez multiplié et fructifié dans le pays, en ces jours-là, — oracle de Yahweh, alors on ne dira plus: « L’arche de l’alliance de Yahweh! » elle ne reviendra plus à la pensée, on ne s’en souviendras plus, on ne la regrettera plus, et on n’en fera plus une autre.
17 Ní ìgbà náà, wọn yóò pe Jerusalẹmu ní ìtẹ́ Olúwa gbogbo orílẹ̀-èdè yóò péjọ sí Jerusalẹmu láti bọ̀wọ̀ fún orúkọ Olúwa, wọn kì yóò sì tún tẹ̀lé àyà líle búburú wọn mọ́.
En ce temps-là on appellera Jérusalem le trône de Yahweh! et toutes les nations s’y assembleront au nom de Yahweh, dans Jérusalem, et elles ne suivront plus l’obstination de leur mauvais cœur.
18 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ni ilé Juda yóò darapọ̀ mọ́ ilé Israẹli. Wọn yóò sì wá láti ilẹ̀ àríwá wá sí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá yín gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní.
En ces jours-là, la maison de Juda marchera avec la maison d’Israël, et elles viendront ensemble du pays du septentrion au pays que j’ai donné en héritage à vos pères.
19 “Èmi fúnra mi sọ wí pé, “‘Báwo ni inú mi yóò ti dùn tó, kí èmi kí ó tọ́ ọ bí ọmọkùnrin kí n sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó tó.’ Mo rò pé ìwọ yóò pè mí ní ‘Baba mi’ o kò sì ní ṣàì tọ̀ mí lẹ́yìn.
Et moi je disais: Comment te placerai-je parmi mes enfants; et te donnerai-je un pays de délices, le plus beau joyau des nations pour héritage. Et j’ai dit: Tu m’appelleras « Mon père », et tu ne cesseras pas de me suivre.
20 Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí aláìgbàgbọ́ obìnrin sí ọkọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ o jẹ́ aláìgbàgbọ́ sí mi. Ìwọ ilé Israẹli,” ni Olúwa wí.
Mais comme une femme trahit son amant, ainsi vous m’avez été infidèle, maison d’Israël, — oracle de Yahweh.
21 A gbọ́ ohùn àgàn láti ibi gíga, ẹkún àti ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli, nítorí wọ́n ti yí ọ̀nà wọn po, wọ́n sì ti gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn.
Une clameur se fait entendre sur les lieux élevés, les pleurs des enfants d’Israël demandant grâce; car ils ont perverti leur voie, oublié Yahweh leur Dieu:
22 “Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́, Èmi ó wo ìpadàsẹ́yìn kúrò ní ọ̀nà títọ́ rẹ sàn.” “Bẹ́ẹ̀, ni a ó wá sọ́dọ̀ rẹ nítorí ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run wa.
— Revenez, fils infidèles, et je guérirai vos infidélités. — « Nous voici, nous venons à vous, car vous êtes Yahweh notre Dieu.
23 Nítòótọ́, asán ni ìbọ̀rìṣà àti ìrúkèrúdò tí ó wà ní àwọn orí òkè kéékèèké àti àwọn òkè gíga, nítòótọ́, nínú Olúwa Ọlọ́run wa ni ìgbàlà Israẹli wà.
Oui, c’est en vain que retentissait sur les hauteurs, sur les montagnes le tumulte des fêtes idolâtres. Oui, c’est en Yahweh, notre Dieu, qu’est le salut d’Israël.
24 Láti ìgbà èwe wa ni àwọn òrìṣà ìtìjú ti jẹ èso iṣẹ́ àwọn baba wa run, ọ̀wọ́ ẹran wọn àti agbo ẹran wọn, ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.
La honte des idoles a dévoré dès notre jeunesse le produit du travail de nos pères, leurs brebis et leurs bœufs, leurs fils et leurs filles.
25 Jẹ́ kí a dùbúlẹ̀ nínú ìtìjú wa, kí ìtìjú wa bò wá mọ́lẹ̀. A ti ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa, àwa àti àwọn baba wa, láti ìgbà èwe wa títí di òní a kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa.”
Couchons-nous dans notre honte, et que notre opprobre nous couvre! Car c’est contre Yahweh, notre Dieu, que nous avons péché, nous et nos pères, dès notre jeunesse et jusqu’à ce jour; et nous n’avons pas écouté la voix de Yahweh notre Dieu ».

< Jeremiah 3 >