< Jeremiah 26 >

1 Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìjọba ọba Jehoiakimu ọmọ Josiah tí ń ṣe ọba Juda, ọ̀rọ̀ yìí wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa:
בראשית ממלכות יהויקים בן יאשיהו--מלך יהודה היה הדבר הזה מאת יהוה לאמר
2 “Èyí ni ohun tí Olúwa wí, Dúró ní àgbàlá ilé Olúwa, kí o sì sọ fún gbogbo ènìyàn ilẹ̀ Juda tí ó ti wá láti wá jọ́sìn ní ilé Olúwa, sọ fún gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún ọ; má ṣaláìsọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà.
כה אמר יהוה עמד בחצר בית יהוה ודברת על כל ערי יהודה הבאים להשתחות בית יהוה את כל הדברים אשר צויתיך לדבר אליהם אל תגרע דבר
3 Bóyá gbogbo wọn máa gbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yóò kúrò nínú ìwà búburú wọn. Èmi ó yí ọkàn padà, n kò sì ní fi ibi tí mo ti rò sí wọn ṣe wọ́n.
אולי ישמעו--וישבו איש מדרכו הרעה ונחמתי אל הרעה אשר אנכי חשב לעשות להם מפני רע מעלליהם
4 Sọ fún wọn wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Tí ẹ kò bá fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò sì gbọ́ òfin mi, ti mo gbé kalẹ̀ níwájú yín,
ואמרת אליהם כה אמר יהוה אם לא תשמעו אלי ללכת בתורתי אשר נתתי לפניכם
5 àti tí ẹ kò bá gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì tí mo rán sí i yín léraléra (ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọ́),
לשמע על דברי עבדי הנבאים אשר אנכי שלח אליכם והשכם ושלח ולא שמעתם
6 nígbà náà ni èmi yóò ṣe ilé yìí bí Ṣilo, èmi yóò sì ṣe ìlú yìí ní ìfibú sí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.’”
ונתתי את הבית הזה כשלה ואת העיר הזאתה (הזאת) אתן לקללה לכל גוי הארץ
7 Àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo ènìyàn ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jeremiah tí ó sọ ní ilé Olúwa.
וישמעו הכהנים והנבאים וכל העם את ירמיהו מדבר את הדברים האלה בבית יהוה
8 Ṣùgbọ́n ní kété tí Jeremiah ti parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí Olúwa pàṣẹ láti sọ; àwọn àlùfáà, àti gbogbo ènìyàn dìímú, wọ́n sì wí pé, “Kíkú ni ìwọ yóò kú!
ויהי ככלות ירמיהו לדבר את כל אשר צוה יהוה לדבר אל כל העם ויתפשו אתו הכהנים והנביאים וכל העם לאמר--מות תמות
9 Kí ló dé tí ìwọ ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ Olúwa pé, ilé yìí yóò dàbí Ṣilo, orílẹ̀-èdè yìí yóò sì di ahoro tí kì yóò ní olùgbé.” Gbogbo àwọn ènìyàn sì kójọpọ̀ pẹ̀lú Jeremiah nínú ilé Olúwa.
מדוע נבית בשם יהוה לאמר כשלו יהיה הבית הזה והעיר הזאת תחרב מאין יושב ויקהל כל העם אל ירמיהו בבית יהוה
10 Nígbà tí àwọn aláṣẹ Juda gbọ́ nípa nǹkan wọ̀nyí, wọ́n lọ láti ààfin ọba sí ilé Olúwa, wọ́n sì mú ààyè wọn, wọ́n jókòó ní ẹnu-ọ̀nà tuntun ilé Olúwa.
וישמעו שרי יהודה את הדברים האלה ויעלו מבית המלך בית יהוה וישבו בפתח שער יהוה החדש
11 Àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì sọ fún àwọn aláṣẹ àti gbogbo ènìyàn pé, “Arákùnrin yìí gbọdọ̀ gba ìdájọ́ ikú nítorí pé ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórí ìlú yìí: bí ẹ̀yin ti fi etí yín gbọ́!”
ויאמרו הכהנים והנבאים אל השרים ואל כל העם לאמר משפט מות לאיש הזה כי נבא אל העיר הזאת כאשר שמעתם באזניכם
12 Nígbà náà ni Jeremiah sọ fún gbogbo àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn wí pé: “Olúwa rán mi láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé yìí àti ìlú yìí, gbogbo ohun tí ẹ ti gbọ́.
ויאמר ירמיהו אל כל השרים ואל כל העם לאמר יהוה שלחני להנבא אל הבית הזה ואל העיר הזאת את כל הדברים אשר שמעתם
13 Nísinsin yìí, tún ọ̀nà rẹ ṣe àti ìṣe rẹ, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run yín. Olúwa yóò yí ọkàn rẹ̀ padà, kò sì ní mú ohun gbogbo tí ó ti sọ jáde ní búburú ṣẹ lórí yín.
ועתה היטיבו דרכיכם ומעלליכם ושמעו בקול יהוה אלהיכם וינחם יהוה--אל הרעה אשר דבר עליכם
14 Bí ó bá ṣe tèmi ni, èmi wà ní ọwọ́ yín, ẹ ṣe ohun tí ẹ̀yin bá rò pé ó dára, tí ó sì tọ́ lójú yín fún mi.
ואני הנני בידכם עשו לי כטוב וכישר בעיניכם
15 Ẹ mọ̀ dájú pé tí ẹ bá pa mí, ẹ ó mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ wá sórí ara yín, sórí ìlú yìí àti àwọn olùgbé inú rẹ̀; nítorí pé nítòótọ́ ni Olúwa ti rán mi láti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un yín.”
אך ידע תדעו כי אם ממתים אתם אתי--כי דם נקי אתם נתנים עליכם ואל העיר הזאת ואל ישביה כי באמת שלחני יהוה עליכם לדבר באזניכם את כל הדברים האלה
16 Nígbà náà ni àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì pé, “Ẹ má ṣe pa ọkùnrin yìí nítorí ó ti bá wa sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.”
ויאמרו השרים וכל העם אל הכהנים ואל הנביאים אין לאיש הזה משפט מות כי בשם יהוה אלהינו דבר אלינו
17 Lára àwọn àgbàgbà ilẹ̀ náà sì sún síwájú, wọ́n sì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà wí pé,
ויקמו אנשים מזקני הארץ ויאמרו אל כל קהל העם לאמר
18 “Mika ti Moreṣeti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ọjọ́ Hesekiah ọba Juda. Ó sọ fún gbogbo ènìyàn Juda pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “‘A ó sì fa Sioni tu bí oko Jerusalẹmu yóò di òkìtì àlàpà àti òkè ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ibi gíga igbó.’
מיכיה (מיכה) המורשתי היה נבא בימי חזקיהו מלך יהודה ויאמר אל כל עם יהודה לאמר כה אמר יהוה צבאות ציון שדה תחרש וירושלים עיים תהיה והר הבית לבמות יער
19 Ǹjẹ́ Hesekiah ọba Juda tàbí ẹnikẹ́ni ní Juda pa á bí? Ǹjẹ́ Hesekiah kò bẹ̀rù Olúwa tí ó sì wá ojúrere rẹ̀? Ǹjẹ́ Olúwa kò ha a sì yí ìpinnu rẹ̀ padà, tí kò sì mú ibi tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ yẹ̀ kúrò lórí wọn? Ibi ni a fẹ́ mú wá sórí ara wa yìí.”
ההמת המתהו חזקיהו מלך יהודה וכל יהודה הלא ירא את יהוה--ויחל את פני יהוה וינחם יהוה אל הרעה אשר דבר עליהם ואנחנו עשים רעה גדולה--על נפשותינו
20 (Bákan náà Uriah ọmọ Ṣemaiah láti Kiriati-Jearimu jẹ́ ọkùnrin mìíràn tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan náà ní orúkọ Olúwa. Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan náà sí ìlú náà àti ilẹ̀ yín bí Jeremiah ti ṣe.
וגם איש היה מתנבא בשם יהוה אוריהו בן שמעיהו מקרית היערים וינבא על העיר הזאת ועל הארץ הזאת ככל דברי ירמיהו
21 Nígbà tí ọba Jehoiakimu àti gbogbo àwọn aláṣẹ gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọba ń wá láti pa á: ṣùgbọ́n Uriah gbọ́ èyí, ẹ̀rù bà á, ó sì sálọ sí Ejibiti.
וישמע המלך יהויקים וכל גבוריו וכל השרים את דבריו ויבקש המלך המיתו וישמע אוריהו וירא ויברח ויבא מצרים
22 Ọba Jehoiakimu rán Elnatani ọmọ Akbori lọ sí Ejibiti pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mìíràn.
וישלח המלך יהויקים אנשים--מצרים את אלנתן בן עכבור ואנשים אתו אל מצרים
23 Wọ́n sì mú Uriah láti Ejibiti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Jehoiakimu; ẹni tí ó fi idà pa, ó sì sọ òkú rẹ̀ sí inú isà òkú àwọn ènìyàn lásán.)
ויוציאו את אוריהו ממצרים ויבאהו אל המלך יהויקים ויכהו בחרב וישלך את נבלתו אל קברי בני העם
24 Ahikamu ọmọ Ṣafani ń bẹ pẹ̀lú Jeremiah, wọn kò sì fi í lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti pa á.
אך יד אחיקם בן שפן היתה את ירמיהו--לבלתי תת אתו ביד העם להמיתו

< Jeremiah 26 >