< Jeremiah 25 >

1 Ọ̀rọ̀ sì tọ Jeremiah wá nípa àwọn ènìyàn Juda ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, èyí tí ó jẹ́ ọdún kìn-ín-ní Nebukadnessari ọba Babeli.
猶大王約史雅的兒子約雅金執政第四年, 巴比倫王拿步高元年,有關於全猶大人民的話,傳給耶肋米亞;
2 Nítorí náà, Jeremiah wòlíì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn Juda àti sí àwọn olùgbé Jerusalẹmu.
耶肋米亞先知便將這話轉告給全猶大人民,和耶路撒冷所有的居民說:「
3 Fún odidi ọdún mẹ́tàlélógún, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún kẹtàlá Josiah, ọmọ Amoni ọba Juda, títí di ọjọ́ yìí, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, mo sì ti sọ ọ́ fún un yín láti ìgbà dé ìgbà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetísílẹ̀.
自猶大王阿孟的兒子約史雅執政第十三魁,直到今日,已經二十三年,凡上主傳給我的話,我都急速告訴了你們,你們卻不聽。
4 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa ti rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn wòlíì sí i yín láti ìgbà dé ìgbà, ẹ̀yin kò fetísílẹ̀.
上主不斷給你們派來他所有的僕人──先知們,你們總是不聽,不願傾耳諦聽。
5 Wọ́n sì wí pé, “Ẹ yípadà olúkúlùkù yín kúrò ní inú ibi rẹ̀ àti ní ọ̀nà ibi rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì lè dúró ní ilẹ̀ tí Olúwa fún un yín àti àwọn baba yín títí láéláé.
他們說:你們應各自離棄自己的邪道,和自己的邪惡的行為,好能住在上主從永遠到永遠賜給了你們和你們祖先的地域裏;
6 Má ṣe tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn láti sìn wọ́n tàbí bọ wọ́n; ẹ má ṣe mú inú bí mi pẹ̀lú ohun tí ẹ ti fi ọwọ́ yín ṣe. Nígbà náà ni Èmi kò ní ṣe yín ní ibi.”
不要追隨其他的神祇,事奉朝拜,以你們手做的東西來激怒我,你們就不致遭遇災禍。
7 “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi,” ni Olúwa wí; “bẹ́ẹ̀ ni ẹ sì ti mú inú bí mi pẹ̀lú ohun tí ẹ fi ọwọ́ yín ṣe, ẹ sì ti mú ibi wá sórí ara yín.”
你們沒有聽從我──上主的斷語──竟以你們手做的東西來激怒我,自招禍患。
8 Nítorí náà, Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ èyí: “Nítorí wí pé ẹ̀yin kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi,
為此,萬軍的上主這樣說:由於你們不聽我的話,
9 Èmi yóò pe gbogbo àwọn ènìyàn àríwá, àti ìránṣẹ́ mi Nebukadnessari ọba Babeli,” ni Olúwa wí. “Èmi yóò sì mú wọn dìde lòdì sí ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé rẹ̀ àti sí gbogbo orílẹ̀-èdè àyíká rẹ̀. Èmi yóò pa wọ́n run pátápátá, Èmi yóò sọ wọ́n di nǹkan ẹ̀rù àti yẹ̀yẹ́ àti ìparun ayérayé.
看,我必遣人召來北方的一切種族──上主的斷語──和我的僕人巴比倫王拿步高來進攻這地方,和這地方的居民,以及四周所有的民族;我要徹底消滅,任其荒涼,永遠成為笑柄和羞辱的對象。
10 Èmi yóò sì mú ìró ayọ̀ àti inú dídùn kúrò lọ́dọ̀ wọn; ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó, ìró ọlọ òkúta àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà.
此外,我還要息滅他們中歡樂喜慶的歌聲,新郎和新娘的歡笑聲,磨聲和燈光。
11 Gbogbo orílẹ̀-èdè yìí yóò sì di ahoro, orílẹ̀-èdè yìí yóò sì sìn ọba Babeli ní àádọ́rin ọdún.
這地方要全變為淒涼野,這些民族要七十年服從巴比倫王。
12 “Ṣùgbọ́n, nígbà tí àádọ́rin ọdún náà bá pé, Èmi yóò fi ìyà jẹ ọba Babeli àti orílẹ̀-èdè rẹ, ilẹ̀ àwọn ará Babeli nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni Olúwa wí; “bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò sọ ọ́ di ahoro títí láé.
但是,一滿了七十年,我必要懲罰巴比倫王和這民族的罪惡──上主的斷語──以及加色丁人的國土,使它永遠成為荒野。
13 Èmi yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ wọ̀nyí wá sórí ilẹ̀ náà, gbogbo ohun tí a ti sọ àní gbogbo èyí tí a ti kọ sínú ìwé yìí, èyí tí Jeremiah ti sọtẹ́lẹ̀ sí gbogbo orílẹ̀-èdè.
對這國土,我要執行我論它所說,在這書上所記載先知耶肋米亞論及萬民所預言的一切話,
14 Àwọn fúnra wọn yóò sì sin orílẹ̀-èdè púpọ̀ àti àwọn ọba ńlá. Èmi yóò sì sán fún oníkálùkù gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti iṣẹ́ ọwọ́ wọn.”
因為強盛的民族和有力的君王,要使他們成為自己的奴隸;我必依照他的作為和他們雙手所行的事,報復他們。
15 Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí fún mi: “Gba ago yìí ní ọwọ́ mí tí ó kún fún ọtí wáìnì ìbínú mi, kí o sì mú gbogbo orílẹ̀-èdè ti mo rán ọ sí mu ún.
上主,以色列的天主這樣對我說:「你從我手中接過這杯忿怒酒去,讓我派你所到的各民族喝。
16 Nígbà tí wọ́n bá mu ún, wọn yóò ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n: bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n di aṣiwèrè nítorí idà tí yóò ránṣẹ́ sí àárín wọn.”
他們必要喝,必要在我給他們派來的刀劍前,蹣跚發狂。」
17 Mo sì gba ago náà lọ́wọ́ Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni mo sì mú gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó rán mi sí mu ún.
我便從上主手中接過杯來,給了上主派我所到的各民族喝:使她們荒蕪淒涼,
18 Jerusalẹmu àti àwọn ìlú Juda, àwọn ọba wọn pẹ̀lú àwọn aláṣẹ wọn, láti sọ wọ́n di ohun ìparun, ohun ẹ̀rù, ẹ̀sìn àti ègún, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti rí lónìí yìí.
受人嘲笑詛咒,像今日一樣;
19 Farao ọba Ejibiti, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn aláṣẹ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀.
給埃及王法郎和他們的臣僕王侯並全體人民;
20 Àti gbogbo àwọn ènìyàn àjèjì tí ó wà níbẹ̀; gbogbo àwọn ọba Usi, gbogbo àwọn ọba Filistini, gbogbo àwọn ti Aṣkeloni, Gasa, Ekroni àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó kù sí Aṣdodu.
給所有的雜族,胡茲地和培肋舍特地的眾君王;給阿市刻隆、迦薩、厄刻龍和阿市多得的遺民;
21 Edomu, Moabu àti Ammoni;
給厄東、摩阿布和阿孟子民;
22 gbogbo àwọn ọba Tire àti Sidoni; gbogbo àwọn ọba erékùṣù wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ìkọjá Òkun.
給提洛、漆冬和海外島嶼的眾君王;
23 Dedani, Tema, Busi àti gbogbo àwọn tí ń gbé lọ́nà jíjìn réré.
給德丹、特瑪、步次和凡剃除鬢髮的人;
24 Gbogbo àwọn ọba Arabia àti àwọn ọba àwọn àjèjì ènìyàn tí ń gbé inú aginjù.
給阿剌伯和在沙漠居住的雜族的眾君王;
25 Gbogbo àwọn ọba Simri, Elamu àti Media.
給齊默黎、厄藍和瑪待的眾君王;
26 Àti gbogbo àwọn ọba àríwá ní tòsí àti lọ́nà jíjìn, ẹnìkínní lẹ́yìn ẹnìkejì; gbogbo àwọn ìjọba lórí orílẹ̀ ayé. Àti gbogbo wọn, ọba Ṣeṣaki náà yóò sì mu.
給北方彼此相離或遠或近的眾君王,以及地面上所有的王國喝;最後喝的,是舍沙客的君王。
27 “Nígbà náà, sọ fún wọn, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára Israẹli wí. Mu, kí o sì mú àmuyó kí o sì bì, bẹ́ẹ̀ ni kí o sì ṣubú láì dìde mọ́ nítorí idà tí n ó rán sí àárín yín.
你應對他們說:「萬軍的上主,以色列的天主這樣說:你們要喝,喝醉,嘔吐,倒在我給你們派來的刀劍前,再不起來。
28 Ṣùgbọ́n bí wọ́n ba kọ̀ láti gba ago náà ní ọwọ́ rẹ kí wọ́n sì mu ún, sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ: Ẹyin gbọdọ̀ mu ún!
假使他們不肯從你手中取過杯去喝,你就對他們說:萬軍的上主這樣說:你必須喝。
29 Wò ó, èmi ń mú ibi bọ̀ sí orí orílẹ̀-èdè tí ó ń jẹ́ orúkọ mi; ǹjẹ́ yóò ha a lè lọ láìjìyà? Ẹ̀yin ń pe idà sọ̀kalẹ̀ sórí gbogbo àwọn olùgbé ayé, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ.’
因為,看,我開始降罰歸我名下的城市,而你們竟想全然免罰嗎﹖你們決不能免罰,因為我要給地上所有的居民招來刀劍──萬軍上主的斷語。
30 “Nísinsin yìí, sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nípa wọn: “‘Kí o sì sọ pé, Olúwa yóò bú láti òkè wá, yóò sì bú kíkankíkan sí ilẹ̀ náà. Yóò parí gbogbo olùgbé ayé, bí àwọn tí ń tẹ ìfúntí.
你應給他們預言這一切話,對他們說:上主從高處作獅吼,從他的聖所發出他的聲音,對自己的牧場厲聲怒號,對地上所有的居民,像榨葡萄的人一樣喊叫。
31 Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ yóò wà títí dé òpin ilẹ̀ ayé, nítorí pé Olúwa yóò mú ìdààmú wá sí orí àwọn orílẹ̀-èdè náà, yóò mú ìdájọ́ wá sórí gbogbo ènìyàn, yóò sì fi àwọn olùṣe búburú fún idà,’” ni Olúwa wí.
一陣喧嘩嘈雜,直至地極,因為上主與萬民有了爭訟,與一切有血肉的人,進行審判,將惡人交給刀劍──上主的斷語──
32 Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Wò ó! Ibi ń tànkálẹ̀ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn; ìjì ńlá yóò sì ru sókè láti òpin ayé.”
萬軍的上主這樣說:看,各國相繼發生災禍,由地極捲來強烈的風暴。
33 Nígbà náà, àwọn tí Olúwa ti pa yóò wà ní ibi gbogbo, láti ìpẹ̀kun kan sí òmíràn. A kì yóò ṣọ̀fọ̀ wọn, a kì yóò kó wọn jọ tàbí sin wọ́n; ṣùgbọ́n wọn yóò dàbí ààtàn lórí ilẹ̀.
到了那一天,從地極到地極,遍是上主戮的人,沒有人哀悼、收殮、埋葬,有如地面上的糞土。
34 Ké, kí ẹ sì pohùnréré ẹkún ẹ̀yin olùṣọ́-àgùntàn, ẹ yí nínú eruku, ẹ̀yin olùdarí agbo ẹran. Nítorí pé ọjọ́ àti pa yín ti dé, ẹ̀yin ó sì ṣubú bí ohun èlò iyebíye.
為人牧者,你們應哭泣哀號! 為羊群領導者,你們應在灰塵中輾轉! 因為們的日期已滿,你們要被宰割,像精選的公羊。
35 Àwọn olùṣọ́-àgùntàn kì yóò rí ibi sálọ kì yóò sì ṣí àsálà fún olórí agbo ẹran.
為人牧者,無路可逃;為羊群領導者,無法脫身。
36 Gbọ́ igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn, àti ìpohùnréré ẹkún àwọn olórí agbo ẹran; nítorí pé Olúwa ń pa pápá oko tútù wọn run.
聽啊! 為人牧者在哀號,為羊群領導者在哭泣,因為上主摧毀了他們的牧場。
37 Ibùgbé àlàáfíà yóò di ahoro, nítorí ìbínú ńlá Olúwa.
寧靜的草場,因上主的怒燄,已成一片荒涼。
38 Gẹ́gẹ́ bí kìnnìún yóò fi ibùba rẹ̀ sílẹ̀, ilẹ̀ wọn yóò sì di ahoro, nítorí idà àwọn aninilára, àti nítorí ìbínú ńlá Olúwa.
獅子離棄了自己的巢穴,因為他們的土地,由於刀劍的無情和上主的盛怒,已成了荒野。

< Jeremiah 25 >