< Jeremiah 22 >

1 Báyìí ni Olúwa wí, “Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ààfin ọba Juda, kí o sì sọ ọ̀rọ̀ yìí níbẹ̀:
כה אמר יהוה רד בית מלך יהודה ודברת שם את הדבר הזה׃
2 ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ìwọ ọba Juda, tí ó jókòó ní ìtẹ́ Dafidi, ìwọ, àwọn ènìyàn rẹ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí ó wọlé láti ẹnu ibodè wọ̀nyí.
ואמרת שמע דבר יהוה מלך יהודה הישב על כסא דוד אתה ועבדיך ועמך הבאים בשערים האלה׃
3 Báyìí ni Olúwa wí: Ṣé ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ tí ó sì yẹ, kí o sì gba ẹni tí a fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú kúrò lọ́wọ́ aninilára. Kí ó má ṣe fi agbára àti ìkà lé àlejò, aláìní baba, tàbí opó, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ níbí yìí.
כה אמר יהוה עשו משפט וצדקה והצילו גזול מיד עשוק וגר יתום ואלמנה אל תנו אל תחמסו ודם נקי אל תשפכו במקום הזה׃
4 Nítorí bí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, nígbà náà ni àwọn ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi yóò gba inú ààfin láti ẹnu-ọ̀nà, wọn yóò gun kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin, àwọn àti ìránṣẹ́ wọn àti àwọn ènìyàn wọn.
כי אם עשו תעשו את הדבר הזה ובאו בשערי הבית הזה מלכים ישבים לדוד על כסאו רכבים ברכב ובסוסים הוא ועבדו ועמו׃
5 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, mo búra fúnra mi pé ààfin yìí yóò di ìparun ni Olúwa wí.’”
ואם לא תשמעו את הדברים האלה בי נשבעתי נאם יהוה כי לחרבה יהיה הבית הזה׃
6 Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa ààfin ọba Juda, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ dàbí Gileadi sí mi, gẹ́gẹ́ bí góńgó òkè Lebanoni, dájúdájú Èmi yóò sọ ọ́ di aṣálẹ̀, àní gẹ́gẹ́ bí ìlú tí a kò gbé inú wọn.
כי כה אמר יהוה על בית מלך יהודה גלעד אתה לי ראש הלבנון אם לא אשיתך מדבר ערים לא נושבה׃
7 Èmi ó ya àwọn apanirun sọ́tọ̀ fún ọ, olúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀, wọn yóò sì gé àṣàyàn igi kedari rẹ lulẹ̀, wọn ó sì kó wọn jù sínú iná.
וקדשתי עליך משחתים איש וכליו וכרתו מבחר ארזיך והפילו על האש׃
8 “Àwọn ènìyàn láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò rékọjá lẹ́bàá ìlú yìí wọn yóò sì máa bi ara wọn léèrè pé, ‘Èéṣe tí Olúwa ṣe irú èyí sí ìlú ńlá yìí?’
ועברו גוים רבים על העיר הזאת ואמרו איש אל רעהו על מה עשה יהוה ככה לעיר הגדולה הזאת׃
9 Ìdáhùn wọn yóò sì jẹ́: ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, wọn ti ń fi orí balẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn, wọ́n sì sìn wọ́n.’”
ואמרו על אשר עזבו את ברית יהוה אלהיהם וישתחוו לאלהים אחרים ויעבדום׃
10 Nítorí náà má ṣe sọkún nítorí ọba tí ó ti kú tàbí ṣọ̀fọ̀ fún àdánù rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ sọkún kíkorò fún ẹni tí a lé kúrò nílùú nítorí kì yóò padà wá mọ́ tàbí fi ojú rí ilẹ̀ tí a ti bí i.
אל תבכו למת ואל תנדו לו בכו בכו להלך כי לא ישוב עוד וראה את ארץ מולדתו׃
11 Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa Ṣallumu ọmọ Josiah ọba Juda tí ó jẹ ọba lẹ́yìn baba rẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó jáde kúrò níhìn-ín: “Òun kì yóò padà wá mọ́.
כי כה אמר יהוה אל שלם בן יאשיהו מלך יהודה המלך תחת יאשיהו אביו אשר יצא מן המקום הזה לא ישוב שם עוד׃
12 Yóò kú ni ibi tí a mú u ní ìgbèkùn lọ, kì yóò sì rí ilẹ̀ yìí mọ́.”
כי במקום אשר הגלו אתו שם ימות ואת הארץ הזאת לא יראה עוד׃
13 “Ègbé ni fún ẹni tí a kọ́ ààfin rẹ̀ lọ́nà àìṣòdodo, àti àwọn yàrá òkè rẹ̀ lọ́nà àìtọ́ tí ó mú kí àwọn ará ìlú rẹ ṣiṣẹ́ lásán láìsan owó iṣẹ́ wọn fún wọn.
הוי בנה ביתו בלא צדק ועליותיו בלא משפט ברעהו יעבד חנם ופעלו לא יתן לו׃
14 Ó wí pé, ‘Èmi ó kọ́ ààfin ńlá fún ara mi àwọn yàrá òkè tí ó fẹ̀, ojú fèrèsé rẹ̀ yóò tóbi.’ A ó sì fi igi kedari bò ó, a ó fi ohun aláwọ̀ pupa ṣe é ní ọ̀ṣọ́.
האמר אבנה לי בית מדות ועליות מרוחים וקרע לו חלוני וספון בארז ומשוח בששר׃
15 “Ìwọ ó ha jẹ ọba kí ìwọ kí ó lè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kedari? Baba rẹ kò ha ní ohun jíjẹ àti mímu? Ó ṣe ohun tí ó tọ́ àti òdodo, nítorí náà ó dára fún un.
התמלך כי אתה מתחרה בארז אביך הלוא אכל ושתה ועשה משפט וצדקה אז טוב לו׃
16 Ó gbèjà òtòṣì àti aláìní, ohun gbogbo sì dára fún un. Bí a ti mọ̀ mí kọ́ ni èyí?” ni Olúwa wí.
דן דין עני ואביון אז טוב הלוא היא הדעת אתי נאם יהוה׃
17 “Ṣùgbọ́n ojú rẹ àti ọkàn rẹ wà lára èrè àìṣòótọ́ láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ìnilára àti ìlọ́nilọ́wọ́gbà.”
כי אין עיניך ולבך כי אם על בצעך ועל דם הנקי לשפוך ועל העשק ועל המרוצה לעשות׃
18 Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí, nípa Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda: “Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un: wí pé, ‘Ó ṣe, arákùnrin mi! Ó ṣe, arábìnrin mi!’ Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un: wí pé, ‘Ó ṣe, olúwa tàbí ó ṣe ọlọ́lá!’
לכן כה אמר יהוה אל יהויקים בן יאשיהו מלך יהודה לא יספדו לו הוי אחי והוי אחות לא יספדו לו הוי אדון והוי הדה׃
19 A ó sin òkú rẹ̀ bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí a wọ́ sọnù láti ẹnu ibodè Jerusalẹmu.”
קבורת חמור יקבר סחוב והשלך מהלאה לשערי ירושלם׃
20 “Gòkè lọ sí Lebanoni, kígbe síta, kí a sì gbọ́ ohùn rẹ ní Baṣani, kí o kígbe sókè láti Abarimu, nítorí a ti ṣẹ́ gbogbo olùfẹ́ rẹ túútúú.
עלי הלבנון וצעקי ובבשן תני קולך וצעקי מעברים כי נשברו כל מאהביך׃
21 Èmi ti kìlọ̀ fún ọ nígbà tí o rò pé kò séwu, ṣùgbọ́n o sọ pé, ‘Èmi kì yóò fetísílẹ̀!’ Èyí ni iṣẹ́ rẹ láti ìgbà èwe rẹ, ìwọ kò fìgbà kan gba ohùn mi gbọ́.
דברתי אליך בשלותיך אמרת לא אשמע זה דרכך מנעוריך כי לא שמעת בקולי׃
22 Ẹ̀fúùfù yóò lé gbogbo àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ̀ lọ, gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ yóò lọ sí ìgbèkùn, nígbà náà ni a ó kẹ́gàn rẹ, ojú yóò tì ọ́ nítorí gbogbo ìwà búburú rẹ.
כל רעיך תרעה רוח ומאהביך בשבי ילכו כי אז תבשי ונכלמת מכל רעתך׃
23 Ìwọ tí ń gbé ‘Lebanoni,’ tí ó tẹ́ ìtẹ́ sí orí igi kedari, ìwọ yóò ti kérora pẹ́ tó, nígbà tí ìrora bá dé bá ọ, ìrora bí i ti obìnrin tí ń rọbí!
ישבתי בלבנון מקננתי בארזים מה נחנת בבא לך חבלים חיל כילדה׃
24 “Dájúdájú bí èmi ti wà láààyè,” ni Olúwa wí, “Bí Koniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda tilẹ̀ jẹ́ òrùka èdìdì lọ́wọ́ ọ̀tún mi, síbẹ̀ èmi ó fà ọ́ tu kúrò níbẹ̀.
חי אני נאם יהוה כי אם יהיה כניהו בן יהויקים מלך יהודה חותם על יד ימיני כי משם אתקנך׃
25 Èmi ó sì fà ọ́ lé ọwọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí rẹ, àwọn tí ìwọ bẹ̀rù, àní lé ọwọ́ Nebukadnessari, ọba Babeli àti ọwọ́ àwọn ará Babeli.
ונתתיך ביד מבקשי נפשך וביד אשר אתה יגור מפניהם וביד נבוכדראצר מלך בבל וביד הכשדים׃
26 Èmi ó fi ìwọ àti ìyá tí ó bí ọ sọ̀kò sí ilẹ̀ mìíràn, níbi tí a kò bí ẹnikẹ́ni nínú yín sí. Níbẹ̀ ni ẹ̀yin méjèèjì yóò kú sí.
והטלתי אתך ואת אמך אשר ילדתך על הארץ אחרת אשר לא ילדתם שם ושם תמותו׃
27 Ẹ̀yin kì yóò padà sí ilẹ̀ tí ẹ̀yin fẹ́ mọ́ láéláé.”
ועל הארץ אשר הם מנשאים את נפשם לשוב שם שמה לא ישובו׃
28 Ǹjẹ́ Jehoiakini ẹni ẹ̀gàn yàtọ̀ sí ìkòkò òfìfo, ohun èlò tí ẹnìkan kò fẹ́? Èéṣe tí a fi òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sókè sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.
העצב נבזה נפוץ האיש הזה כניהו אם כלי אין חפץ בו מדוע הוטלו הוא וזרעו והשלכו על הארץ אשר לא ידעו׃
29 Ìwọ ilẹ̀, ilẹ̀, ilẹ̀, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa!
ארץ ארץ ארץ שמעי דבר יהוה׃
30 Báyìí ni Olúwa wí: “Kọ àkọsílẹ̀ ọkùnrin yìí sínú ìwé gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́mọ, ẹni tí kì yóò ṣe rere ní ọjọ́ ayé rẹ̀; nítorí ọ̀kan nínú irú-ọmọ rẹ̀ kì yóò ṣe rere, èyíkéyìí wọn kì yóò jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi tàbí jẹ ọba ní Juda mọ́.”
כה אמר יהוה כתבו את האיש הזה ערירי גבר לא יצלח בימיו כי לא יצלח מזרעו איש ישב על כסא דוד ומשל עוד ביהודה׃

< Jeremiah 22 >