< Jeremiah 2 >

1 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé:
ויהי דבר יהוה אלי לאמר
2 “Lọ kí o sì kéde sí etí Jerusalẹmu pé: “Báyìí ni Olúwa wí, “‘Èmi rántí ìṣeun ìgbà èwe rẹ, ìfẹ́ ìgbéyàwó rẹ àti nígbà tí ìwọ tẹ̀lé mi nínú ijù, nínú ìyàngbẹ ilẹ̀.
הלך וקראת באזני ירושלם לאמר כה אמר יהוה זכרתי לך חסד נעוריך אהבת כלולתיך--לכתך אחרי במדבר בארץ לא זרועה
3 Israẹli jẹ́ mímọ́ sí Olúwa, àkọ́kọ́ èso ìkórè rẹ̀, gbogbo ẹnikẹ́ni tí ó jẹ run ni a ó dá lẹ́bi, ibi yóò sì wá sí orí wọn,’” bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.
קדש ישראל ליהוה ראשית תבואתה כל אכליו יאשמו רעה תבא אליהם נאם יהוה
4 Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ìdílé Jakọbu àti gbogbo ẹ̀yin ará ilé Israẹli.
שמעו דבר יהוה בית יעקב וכל משפחות בית ישראל
5 Báyìí ni Olúwa wí: “Irú àìṣedéédéé wo ni baba yín rí lọ́wọ́ mi, tí wọ́n fi jìnnà sí mi? Wọ́n tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán, àwọn fúnra wọn sì di asán.
כה אמר יהוה מה מצאו אבותיכם בי עול--כי רחקו מעלי וילכו אחרי ההבל ויהבלו
6 Wọn kò béèrè, ‘Níbo ni Olúwa wà, tí ó mú wa jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá, tí ó mú wa la aginjù já, tí ó mú wa la àárín pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ihò, ìyàngbẹ ilẹ̀ àti òkùnkùn biribiri, ilẹ̀ ibi tí ẹnikẹ́ni kò là kọjá, tí ẹnikẹ́ni kò sì tẹ̀dó sí?’
ולא אמרו--איה יהוה המעלה אתנו מארץ מצרים המוליך אתנו במדבר בארץ ערבה ושוחה בארץ ציה וצלמות--בארץ לא עבר בה איש ולא ישב אדם שם
7 Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ ọlọ́ràá láti máa jẹ èso ibẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin wọ inú rẹ̀, ẹ sì bà á jẹ́, ẹ sì sọ ogún mi di ohun ìríra.
ואביא אתכם אל ארץ הכרמל לאכל פריה וטובה ותבאו ותטמאו את ארצי ונחלתי שמתם לתועבה
8 Àwọn àlùfáà kò béèrè wí pé, ‘Níbo ni Olúwa wà?’ Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òfin kò si mọ̀ mí, àwọn olùṣọ́ sì ṣẹ̀ sí mi. Àwọn wòlíì sì ń sọtẹ́lẹ̀ nípa òrìṣà Baali, wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán.
הכהנים לא אמרו איה יהוה ותפשי התורה לא ידעוני והרעים פשעו בי והנבאים נבאו בבעל ואחרי לא יועלו הלכו
9 “Nítorí náà, mo fi ẹ̀sùn kàn yín lẹ́ẹ̀kan sí i,” ni Olúwa wí. “Èmi ó sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ọwọ́ rẹ.
לכן עד אריב אתכם--נאם יהוה ואת בני בניכם אריב
10 Rékọjá lọ sí erékùṣù àwọn ara Kittimu, kí ẹ sì wò ó, ránṣẹ́ lọ sí ìlú Kedari, kí ẹ sì kíyèsi gidigidi; kí ẹ wò bí irú nǹkan báyìí bá ń bẹ níbẹ̀?
כי עברו איי כתיים וראו וקדר שלחו והתבוננו מאד וראו הן היתה כזאת
11 Orílẹ̀-èdè kan ha á pa ọlọ́run rẹ̀ dà? (Síbẹ̀, wọ́n kì í ṣe iṣẹ́ ọlọ́run.) Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi ti pààrọ̀ Ọlọ́run ògo wọn fún àwọn ère tí kò níyì.
ההימיר גוי אלהים והמה לא אלהים ועמי המיר כבודו בלוא יועיל
12 Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì kí ẹ sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù ńlá,” ni Olúwa wí.
שמו שמים על זאת ושערו חרבו מאד נאם יהוה
13 “Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì, wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, Èmi orísun omi ìyè, wọ́n sì ti ṣe àmù, àmù fífọ́ tí kò lè gba omi dúró.
כי שתים רעות עשה עמי אתי עזבו מקור מים חיים לחצב להם בארות--בארת נשברים אשר לא יכלו המים
14 Israẹli ha á jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ ẹrú nípa ìbí? Kí ló ha a dé tí ó fi di ìkógun?
העבד ישראל--אם יליד בית הוא מדוע היה לבז
15 Àwọn kìnnìún ké ramúramù; wọ́n sì ń bú mọ́ wọn. Wọ́n ti fi ilẹ̀ rẹ̀ ṣòfò; ìlú rẹ̀ ti di jíjóná, ó sì ti di ìkọ̀sílẹ̀.
עליו ישאגו כפרים נתנו קולם וישיתו ארצו לשמה עריו נצתה (נצתו) מבלי ישב
16 Bákan náà, àwọn ọkùnrin Memfisi àti Tafanesi wọ́n ti fa adé orí rẹ yọ.
גם בני נף ותחפנס (ותחפנחס) ירעוך קדקד
17 Ẹ̀yin kò ha a ti fa èyí sórí ara yín nípa kíkọ Olúwa Ọlọ́run sílẹ̀ nígbà tí ó tọ́ ọ lójú ọ̀nà?
הלוא זאת תעשה לך עזבך את יהוה אלהיך בעת מולכך בדרך
18 Kí ló dé tí o ṣe wá lọ Ejibiti láti lọ mu omi ní Ṣihori? Kí ló dé tí o sì fi lọ sí Asiria láti lọ mú omi ni odò Eufurate náà?
ועתה מה לך לדרך מצרים לשתות מי שחור ומה לך לדרך אשור לשתות מי נהר
19 Iṣẹ́ búburú yín yóò fìyà jẹ yín ìpadàsẹ́yìn rẹ yóò sì bá ọ wí mọ̀ kí o sì rí i wí pé ibi àti ohun búburú yóò sì jẹ́ tìrẹ nígbà tí o ti kọ Olúwa Ọlọ́run sílẹ̀, ẹ kò sì ní ìbẹ̀rù fún mi,” ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
תיסרך רעתך ומשבותיך תוכחך ודעי וראי כי רע ומר עזבך את יהוה אלהיך ולא פחדתי אליך נאם אדני יהוה צבאות
20 “Nígbà àtijọ́, o ti fọ́ àjàgà rẹ sọnù, ìwọ sì já ìdè rẹ; ìwọ wí pé, ‘Èmi kì yóò sìn ọ́!’ Lóòtítọ́, lórí gbogbo òkè gíga ni àti lábẹ́ igi tí ó tànkálẹ̀ ni ìwọ dùbúlẹ̀ sí gẹ́gẹ́ bí panṣágà.
כי מעולם שברתי עלך נתקתי מוסרותיך ותאמרי לא אעבוד (אעבור) כי על כל גבעה גבהה ותחת כל עץ רענן את צעה זנה
21 Èmi ti gbìn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àjàrà ọ̀tọ̀, gẹ́gẹ́ bí ìṣúra ọlọ́lá. Báwo wá ni ìwọ ṣe yípadà sí mi di àjàrà búburú àti aláìmọ́?
ואנכי נטעתיך שורק כלה זרע אמת ואיך נהפכת לי סורי הגפן נכריה
22 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o wẹ ara rẹ pẹ̀lú sódà tí o sì lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọṣẹ síbẹ̀síbẹ̀ èérí ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ níwájú,” ni Olúwa Olódùmarè wí.
כי אם תכבסי בנתר ותרבי לך ברית--נכתם עונך לפני נאם אדני יהוה
23 “Báwo ni ìwọ ṣe wí pé, ‘Èmi kò ṣe aláìmọ́, Èmi kò sá à tẹ̀lé àwọn Baali’? Wo bí o ṣe hùwà ní àfonífojì; wo ohun tí o ṣe. Ìwọ jẹ́ abo ìbákasẹ tí ń sá síyìn-ín sọ́hùn-ún.
איך תאמרי לא נטמאתי אחרי הבעלים לא הלכתי--ראי דרכך בגיא דעי מה עשית בכרה קלה משרכת דרכיה
24 Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń gbé aginjù tí ń fa ẹ̀fúùfù ìfẹ́ sí i mu rẹ, ta ni ó le è mú dúró ní àkókò rẹ̀? Kí gbogbo àwọn akọ ẹran tí o wá a kiri kì ó má ṣe dá ara wọn lágara, nítorí wọn yóò rí ní àkókò oṣù rẹ̀.
פרה למד מדבר באות נפשו (נפשה) שאפה רוח--תאנתה מי ישיבנה כל מבקשיה לא ייעפו בחדשה ימצאונה
25 Dá ẹsẹ̀ dúró láìwọ bàtà, àti ọ̀fun rẹ nínú òǹgbẹ. Ṣùgbọ́n ìwọ wí pé, ‘Asán ni! Èmi fẹ́ràn àwọn ọlọ́run àjèjì, àwọn ni èmi yóò tọ̀ lẹ́yìn.’
מנעי רגלך מיחף וגורנך (וגרונך) מצמאה ותאמרי נואש--לוא כי אהבתי זרים ואחריהם אלך
26 “Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń dójútì olè nígbà tí a bá mú u, bẹ́ẹ̀ náà ni ojú yóò ti ilé Israẹli— àwọn ọba àti àwọn ìjòyè wọn, àwọn àlùfáà àti wòlíì wọn pẹ̀lú.
כבשת גנב כי ימצא כן הבישו בית ישראל המה מלכיהם שריהם וכהניהם ונביאיהם
27 Wọ́n sọ fún igi pé, ‘Ìwọ ni baba mi,’ àti sí òkúta wí pé, ‘Ìwọ ni ó bí mi,’ wọ́n ti kọ ẹ̀yìn wọn sí mi, wọn kò kọ ojú sí mi síbẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro, wọn yóò wí pé, ‘Wá kí o sì gbà wá!’
אמרים לעץ אבי אתה ולאבן את ילדתני (ילדתנו) כי פנו אלי ערף ולא פנים ובעת רעתם יאמרו קומה והושיענו
28 Níbo wá ni àwọn ọlọ́run tí ẹ ṣe fúnra yín ha a wà? Jẹ́ kí wọ́n wá kí wọ́n sì gbà yín nígbà tí ẹ bá wà nínú ìṣòro! Nítorí pé ẹ̀yin ní àwọn ọlọ́run púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ni àwọn ìlú, ìwọ Juda.
ואיה אלהיך אשר עשית לך--יקומו אם יושיעוך בעת רעתך כי מספר עריך היו אלהיך יהודה
29 “Kí ló dé tí o ṣe wá ń fi ẹ̀sùn kàn mí? Gbogbo yín ni ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi,” ni Olúwa wí.
למה תריבו אלי כלכם פשעתם בי נאם יהוה
30 “Nínú asán mo fìyà jẹ àwọn ènìyàn yín, wọn kò sì gba ìbáwí. Idà yín ti pa àwọn wòlíì yín run, gẹ́gẹ́ bí kìnnìún tí ń bú ramúramù.
לשוא הכיתי את בניכם מוסר לא לקחו אכלה חרבכם נביאיכם כאריה משחית
31 “Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ kíyèsi ọ̀rọ̀ Olúwa: “Mo ha ti di aginjù sí Israẹli tàbí mo jẹ ilẹ̀ olókùnkùn biribiri? Èéṣe tí àwọn ènìyàn mi ṣe wí pé, ‘A ní àǹfààní láti máa rìn kiri; àwa kì yóò tọ̀ ọ́ wá mọ́?’
הדור אתם ראו דבר יהוה המדבר הייתי לישראל אם ארץ מאפליה מדוע אמרו עמי רדנו--לוא נבוא עוד אליך
32 Wúńdíá ha le gbàgbé ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀, tàbí ìyàwó ohun ọ̀ṣọ́ ìgbéyàwó rẹ̀? Síbẹ̀, àwọn ènìyàn mi ti gbàgbé mi ní ọjọ́ àìníye.
התשכח בתולה עדיה כלה קשריה ועמי שכחוני ימים אין מספר
33 Ìwọ ti jẹ́ ọlọ́gbọ́n tó nípa ọ̀rọ̀ ìfẹ́! Àwọn obìnrin búburú yóò kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà rẹ.
מה תיטבי דרכך לבקש אהבה לכן גם את הרעות למדתי (למדת) את דרכיך
34 Lórí aṣọ rẹ ni wọ́n bá ẹ̀jẹ̀ àwọn tálákà aláìṣẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò ká wọn mọ́ níbi tí wọ́n ti ń rùn wọlé. Síbẹ̀ nínú gbogbo èyí
גם בכנפיך נמצאו דם נפשות אביונים נקיים לא במחתרת מצאתים כי על כל אלה
35 ìwọ sọ wí pé, ‘Èmi jẹ́ aláìṣẹ̀; kò sì bínú sí mi.’ Èmi yóò mú ìdájọ́ mi wá sórí rẹ nítorí pé ìwọ wí pé, ‘Èmi kò dẹ́ṣẹ̀.’
ותאמרי כי נקיתי אך שב אפו ממני הנני נשפט אותך על אמרך לא חטאתי
36 Èéṣe tí ìwọ fi ń lọ káàkiri láti yí ọ̀nà rẹ padà? Ejibiti yóò dójútì ọ́ gẹ́gẹ́ bí i ti Asiria.
מה תזלי מאד לשנות את דרכך גם ממצרים תבשי כאשר בשת מאשור
37 Ìwọ yóò sì fi ibẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú kíkáwọ́ rẹ lé orí rẹ, nítorí pé Olúwa ti kọ̀ àwọn tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé sílẹ̀, kì yóò sí ìrànlọ́wọ́ kankan fún ọ láti ọ̀dọ̀ wọn.
גם מאת זה תצאי וידיך על ראשך כי מאס יהוה במבטחיך ולא תצליחי להם

< Jeremiah 2 >