< Jeremiah 18 >
1 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremiah wá wí pe:
La palabra que fue a Jeremías de Jehová, diciendo:
2 “Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀ ni èmi yóò ti bá ọ sọ̀rọ̀.”
Levántate, y vete a casa del ollero, y allí te haré que oigas mis palabras.
3 Nígbà náà ni mo lọ sí ilé amọ̀kòkò mo sì rí i tí ó ń ṣiṣẹ́ kan lórí kẹ̀kẹ́.
Y descendí en casa del ollero, y he aquí que él hacía obra sobre una rueda.
4 Ṣùgbọ́n ìkòkò tí ó ń mọ láti ara amọ̀ bàjẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀, nítorí náà ni amọ̀kòkò fi ṣe ìkòkò mìíràn, ó mọ ọ́n bí èyí tí ó dára jù ní ojú rẹ̀.
Y el vaso que él hacía de barro se quebró en la mano del ollero; y tornó, e hízolo otro vaso según que al ollero pareció mejor hacerlo.
5 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé:
Y fue a mí palabra de Jehová, diciendo:
6 “Ẹyin ilé Israẹli, èmi kò ha lè ṣe fún un yín gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe?” ni Olúwa wí. “Gẹ́gẹ́ bí amọ̀ ní ọwọ́ amọ̀kòkò bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin rí ní ọwọ́ mi, ẹ̀yin ilé Israẹli.
¿No podré yo hacer de vosotros como este ollero, o! casa de Israel, dice Jehová? He aquí que como el barro en la mano del ollero, así sois vosotros en mi mano, o! casa de Israel.
7 Bí ó bá jẹ́ ìgbà kan, tí èmi kéde kí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan di fífà tu láti dojúdé àti láti parun,
En un instante hablaré contra naciones, y contra reinos, para arrancar, y disipar, y perder:
8 tí orílẹ̀-èdè ti mo kìlọ̀ fún bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú wọn, nígbà náà ni Èmi yóò yí ọkàn mi padà nínú àjálù tí mo ti rò láti ṣe sí wọn.
Empero si esas naciones se convirtieren de su maldad, contra el cual mal yo hablé, yo me arrepentiré del mal que había pensado de les hacer.
9 Ní ìgbà mìíràn tí èmi bá tún kéde láti tẹ̀dó tàbí gbin orílẹ̀-èdè kan tàbí ìjọba kan.
Y en un instante hablaré de la nación, y del reino, para edificar y para plantar:
10 Bí ó bá sì ṣe búburú níwájú mi, tí kò sì gba ohùn mi gbọ́, nígbà náà ni èmi yóò yí ọkàn mi padà ní ti rere, èyí tí mo wí pé, èmi ó ṣe fún wọn.
Y si hiciere lo malo delante de mis ojos, no oyendo mi voz, arrepentirme he del bien que había determinado de le hacer.
11 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, sọ fún àwọn ènìyàn Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa wí: Wò ó! Èmi ń gbèrò ibi sí yin, èmi sì ń ṣe ìpinnu kan lórí yín. Nítorí náà ẹ yípadà kúrò lọ́nà búburú yín kí olúkúlùkù yín sì tún ọ̀nà àti ìṣe rẹ̀ ṣe.’
Ahora pues, habla ahora a todo hombre de Judá, y a los moradores de Jerusalem, diciendo: Así dijo Jehová: He aquí que yo compongo mal contra vosotros, y pienso contra vosotros pensamientos: conviértase ahora cada uno de su mal camino, y mejorád vuestros caminos, y vuestras obras.
12 Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Kò ṣe nǹkan kan, àwa yóò tẹ̀síwájú nínú èrò wa, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, yóò hùwà agídí ọkàn búburú rẹ̀.’”
Y dijeron: Es por demás, porque en pos de nuestras imaginaciones hemos de ir; y cada uno el pensamiento de su malvado corazón hemos de hacer.
13 Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí: “Ẹ béèrè nínú orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá ti gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí ri? Ohun tí ó burú gidi ni wúńdíá Israẹli ti ṣe.
Por tanto así dijo Jehová: Ahora preguntád a las naciones: ¿Quién oyó tal? Gran fealdad hizo la virgen de Israel.
14 Ǹjẹ́ omi ojo dídì Lebanoni yóò ha dá láti máa sàn láti ibi àpáta? Tàbí odò tí ó jìnnà, tí ó tútù, tí ó ń sàn, yóò ha gbẹ bí?
¿Dejará alguno la nieve de la piedra del campo que corre del Líbano? dejarán las aguas extrañas, frías y corrientes?
15 Nítorí àwọn ènìyàn mi gbàgbé mi, wọ́n sun tùràrí fún òrìṣà asán, tí ó mú wọn kọsẹ̀ ní ọ̀nà wọn, àti ọ̀nà wọn àtijọ́. Wọ́n mú wọn rìn ní ọ̀nà àtijọ́, àti ní ojú ọ̀nà ti a kò ṣe.
Porque mi pueblo me olvidaron, incensando a la vanidad; y hácenlos tropezar en sus caminos, en las sendas antiguas, para que caminen por sendas, por camino no hollado:
16 Ilẹ̀ wọn yóò wà lásán yóò sì di nǹkan ẹ̀gàn títí láé, gbogbo àwọn tí ó ń kọjá yóò bẹ̀rù, wọn yóò sì mi orí wọn.
Para poner su tierra en admiración, y en silbos perpetuos: todo aquel que pasare por ella se maravillará, y meneará su cabeza.
17 Gẹ́gẹ́ bí afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn, Èmi yóò tú wọn ká lójú àwọn ọ̀tá wọn. Èmi yóò sì kọ ẹ̀yìn sí wọn, n kì yóò kọjú sí wọn ní ọjọ́ àjálù wọn.”
Como viento solano los esparciré delante del enemigo: la cerviz, y no el rostro, les mostraré en el día de su perdición.
18 Wọ́n sọ wí pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ ṣọ̀tẹ̀ sí Jeremiah, nítorí òfin ìkọ́ni láti ẹnu àwọn àlùfáà kì yóò jásí asán, tàbí ìmọ̀ràn fún àwọn ọlọ́gbọ́n tàbí ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì. Nítorí náà wá, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú pẹ̀lú ahọ́n wa, kí a má sì ṣe tẹ́tí sí ohunkóhun tí ó bá sọ.”
Y dijeron: Veníd, y maquinemos maquinaciones contra Jeremías; porque la ley no faltará del sacerdote, ni consejo del sabio, ni palabra del profeta. Veníd, e hirámosle de lengua, y no miremos a todas sus palabras.
19 Dẹtí sí ọ̀rọ̀ mi Olúwa, gbọ́ ohun tí àwọn tí ó fi mí sùn ń sọ.
Jehová mira por mí, y oye la voz de los que contienden conmigo.
20 Ṣe kí a fi rere san búburú? Síbẹ̀ wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún mi. Rántí pé mo dúró níwájú rẹ, mo sì sọ̀rọ̀ nítorí wọn, láti yí ìbínú rẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.
¿Dáse mal por bien, que cavaron hoyo a mi alma? Acuérdate que me puse delante de ti, para hablar bien por ellos, para apartar de ellos tu ira.
21 Nítorí náà, jẹ́ kí ìyàn mú ọmọ wọn jọ̀wọ́ wọn fún ọwọ́ idà jẹ́ kí ìyàwó wọn kí ó di aláìlọ́mọ àti opó jẹ́ kí a pa àwọn ọkùnrin wọn kí a sì fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn lójú ogun.
Por tanto entrega sus hijos a hambre, y házlos escurrir por manos de espada; y sus mujeres queden sin hijos, y viudas; y sus maridos muertos de muerte; y sus mancebos sean heridos a espada en la guerra.
22 Jẹ́ kí a gbọ́ ohùn ẹkún láti ilé wọn nígbà tí ó bá mu àwọn jagunjagun kọlù wọ́n lójijì nítorí wọ́n ti gbẹ́ kòtò láti mú mi. Wọ́n ti dẹ okùn fún ẹsẹ̀ mi.
De sus casas se oiga clamor, cuando trajeres sobre ellos ejército de repente; porque cavaron hoyo para tomarme, y escondieron lazos a mis pies.
23 Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa mọ gbogbo ète wọn láti pa mí, má ṣe dárí ẹ̀bi wọn jì wọ́n bẹ́ẹ̀ ni má ṣe pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúrò lójú rẹ. Jẹ́ kí wọn kí ó ṣubú níwájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì ṣe sí wọn nígbà ìbínú rẹ.
Mas tú, o! Jehová, conoces todo su consejo contra mí que es para muerte: no perdones su maldad, ni raigas su pecado de delante de tu rostro; y tropiecen delante de ti: haz con ellos en el tiempo de tu furor.