< Jeremiah 15 >

1 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé: “Kódà kí Mose àti Samuẹli dúró níwájú mi, ọkàn mi kì yóò lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Mú wọn kúrò níwájú mi! Jẹ́ kí wọn ó lọ!
Then YHWH said to me, "Though Moses and Samuel stood before me, yet my mind would not be toward this people: cast them out of my sight, and let them go forth.
2 Tí wọ́n bá sì bi ọ́ pé, ‘Níbo ni kí a lọ?’ Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: “‘Àwọn tí a kọ ikú mọ́, sí ikú; àwọn tí a kọ idà mọ́, sí idà; àwọn tí a kọ ìyàn mọ́, sí ìyàn; àwọn tí a kọ ìgbèkùn mọ́ sí ìgbèkùn.’
It shall happen, when they tell you, 'Where shall we go forth?' Then you shall tell them, 'Thus says YHWH: "Such as are for death, to death; and such as are for the sword, to the sword; and such as are for the famine, to the famine; and such as are for captivity, to captivity.
3 “Èmi yóò rán oríṣìí ìjìyà mẹ́rin láti kọlù wọ́n,” ni Olúwa wí, “Idà láti pa, àwọn ajá láti wọ́ wọn lọ, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko orí ilẹ̀ láti jẹ àti láti parun.
I will appoint over them four kinds, says YHWH: the sword to kill, and the dogs to tear, and the birds of the sky, and the animals of the earth, to devour and to destroy.
4 N ó sọ wọ́n di ẹni ìkórìíra níwájú gbogbo ìjọba ayé torí ohun tí Manase ọmọ Hesekiah ọba Juda ṣe ní Jerusalẹmu.
I will cause them to be tossed back and forth among all the kingdoms of the earth, because of Manasseh, the son of Hezekiah, king of Judah, for that which he did in Jerusalem.
5 “Ta ni yóò ṣàánú rẹ, ìwọ Jerusalẹmu? Ta ni yóò dárò rẹ? Ta ni yóò dúró béèrè àlàáfíà rẹ?
For who will have pity on you, Jerusalem? Or who will bemoan you? Or who will turn aside to ask of your welfare?
6 O ti kọ̀ mí sílẹ̀,” ni Olúwa wí, “Ìwọ sì wà nínú ìpadàsẹ́yìn. Nítorí náà, Èmi yóò dáwọ́lé ọ, èmi ó sì pa ọ́ run, Èmi kò sì ní fi ojú àánú wò ọ́ mọ́.
'You have rejected me,' says YHWH, 'you have gone backward:' therefore have I stretched out my hand against you, and destroyed you; I am weary with repenting.
7 Èmi kò tún lè fi ìfẹ́ hàn si ọ, Èmi yóò fi àtẹ fẹ́ wọn sí ẹnu-ọ̀nà ìlú náà. Èmi yóò mú ìṣọ̀fọ̀ àti ìparun bá àwọn ènìyàn mi nítorí pé wọn kò tí ì yípadà kúrò lọ́nà wọn.
I have winnowed them with a fan in the gates of the land; I have bereaved them of children, I have destroyed my people; they did not return from their ways.
8 Èmi yóò jẹ́ kí àwọn opó wọn pọ̀ ju yanrìn Òkun lọ. Ní ọjọ́-kanrí ni èmi ó mú apanirun kọlu àwọn ìyá ọmọkùnrin wọn. Lójijì ni èmi yóò mú ìfòyà àti ìbẹ̀rù bá wọn.
Their widows are increased to me above the sand of the seas; I have brought on them against the mother of the young men a destroyer at noonday; I have made anguish and terror to fall on them suddenly.
9 Ìyá ọlọ́mọ méje yóò dákú, yóò sì mí ìmí ìgbẹ̀yìn. Òòrùn rẹ yóò wọ̀ lọ́sàn án gangan, yóò di ẹni ẹ̀tẹ́ òun àbùkù. Èmi yóò fi àwọn tí ó bá yè síwájú àwọn ọ̀tá wọn tí idà wà lọ́wọ́ wọn,” ni Olúwa wí.
She who has borne seven languishes; she has given up the spirit; her sun is gone down while it was yet day; she has been disappointed and confounded: and their residue will I deliver to the sword before their enemies," says YHWH.
10 Háà! Ó ṣe tí ìyá mi bí mi, ọkùnrin tí gbogbo ilẹ̀ dojúkọ tí wọ́n sì bá jà! Èmi kò wínni, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yá lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, síbẹ̀, gbogbo ènìyàn ló ń fi mí ré.
"Woe is me, my mother, that you have borne me a man of strife and a man of contention to the whole earth. I have not lent, neither have men lent to me; yet everyone of them curses me."
11 Olúwa sọ pé, “Dájúdájú èmi ò dá ọ sí fún ìdí kan pàtó; dájúdájú mo mú kí àwọn ọ̀tá rẹ tẹríba níwájú rẹ nígbà ibi àti ìpọ́njú.
YHWH said, "Most certainly I will strengthen you for good; most certainly I will cause the enemy to make petition to you in the time of evil and in the time of distress.
12 “Ǹjẹ́ ẹnìkan lè fi ọwọ́ ṣẹ́ irin irin láti àríwá tàbí idẹ?
Can one break iron, even iron from the north, and bronze?
13 “Gbogbo ọlá àti ìṣúra rẹ ni èmi ó fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun láìgba nǹkan kan nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jákèjádò orílẹ̀-èdè rẹ.
Your substance and your treasures will I give for a spoil without price, and that for all your sins, even in all your borders.
14 Èmi yóò fi ọ́ ṣẹrú fún àwọn ọ̀tá rẹ ní ìlú tí ìwọ kò mọ̀ nítorí ìbínú mi yóò rán iná tí yóò jó ọ.”
I will make you serve your enemies in a land which you do not know; for a fire is kindled in my anger, which shall burn on you."
15 Ó yé ọ, ìwọ Olúwa; rántí mi kí o sì ṣe ìtọ́jú mi. Gbẹ̀san mi lára àwọn tó dìtẹ̀ mi. Ìwọ ti jìyà fún ìgbà pípẹ́, má ṣe mú mi lọ; nínú bí mo ṣe jìyà nítorí tìrẹ.
"YHWH, you know; remember me, and visit me, and avenge me of my persecutors; do not take me away in your longsuffering: know that for your sake I have suffered reproach.
16 Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ dé, mo jẹ wọ́n, àwọn ni ìdùnnú àti ayọ̀ ọkàn mi, nítorí pé orúkọ rẹ ni a fi ń pè mí, Ìwọ Olúwa Ọlọ́run Alágbára.
Your words were found, and I ate them; and your words were to me a joy and the rejoicing of my heart: for I am called by your name, YHWH, the God of hosts.
17 Èmi kò fìgbà kan jókòó láàrín àwọn ẹlẹ́gàn, n ko bá wọn yọ ayọ̀ pọ̀; mo dá jókòó torí pé ọwọ́ rẹ wà lára mi, ìwọ sì ti fi ìbínú rẹ kún inú mi.
I did not sit in the assembly of those who make merry, nor rejoiced; I sat alone because of your hand; for you have filled me with indignation.
18 Èéṣe tí ìrora mi kò lópin, tí ọgbẹ́ mi kò sì ṣe é wòsàn? Ní òtítọ́ ìwọ yóò dàbí kànga ẹ̀tàn sí mi, gẹ́gẹ́ bí ìsun tó kọ̀ tí kò sun?
Why is my pain perpetual, and my wound incurable, which refuses to be healed? Will you indeed be to me as a deceitful brook, as waters that fail?"
19 Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí, “Tí o bá ronúpìwàdà, Èmi ó dá ọ padà wá kí o lè máa sìn mí; tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ tó dára, ìwọ yóò di agbẹnusọ mi. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí kọjú sí ọ; ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọjú sí wọn.
Therefore thus says YHWH, "If you return, then will I bring you again, that you may stand before me; and if you take forth the precious from the vile, you shall be as my mouth: they shall return to you, but you shall not return to them.
20 Èmi fi ọ́ ṣe odi idẹ tí ó lágbára, sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí; wọn ó bá ọ jà ṣùgbọ́n wọn kò ní lè borí rẹ, nítorí pé, mo wà pẹ̀lú rẹ láti gbà ọ́ là, kí n sì dáàbò bò ọ́,” ni Olúwa wí.
I will make you to this people a fortified bronze wall; and they shall fight against you, but they shall not prevail against you; for I am with you to save you and to deliver you," says YHWH.
21 “Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ìkà ènìyàn, Èmi yóò sì rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.”
"I will deliver you out of the hand of the wicked, and I will redeem you out of the hand of the terrible."

< Jeremiah 15 >