< Jeremiah 14 >

1 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Jeremiah nípa ti àjàkálẹ̀-ààrùn:
אשר היה דבר יהוה אל ירמיהו על דברי הבצרות
2 “Juda káàánú, àwọn ìlú rẹ̀ kérora wọ́n pohùnréré ẹkún fún ilẹ̀ wọn, igbe wọn sì gòkè lọ láti Jerusalẹmu.
אבלה יהודה ושעריה אמללו קדרו לארץ וצוחת ירושלם עלתה
3 Àwọn ọlọ́lá ènìyàn rán àwọn ìránṣẹ́ wọn lọ bu omi, wọ́n lọ sí ìdí àmù ṣùgbọ́n wọn kò rí omi. Wọ́n padà pẹ̀lú ìkòkò òfìfo; ìrẹ̀wẹ̀sì àti àìnírètí bá wọn, wọ́n sì bo orí wọn.
ואדריהם שלחו צעוריהם (צעיריהם) למים באו על גבים לא מצאו מים שבו כליהם ריקם--בשו והכלמו וחפו ראשם
4 Ilẹ̀ náà sán nítorí pé kò sí òjò ní ilẹ̀ náà; ìrètí àwọn àgbẹ̀ di òfo, wọ́n sì bo orí wọn.
בעבור האדמה חתה כי לא היה גשם בארץ בשו אכרים חפו ראשם
5 Kódà, abo àgbọ̀nrín tí ó wà lórí pápá fi ọmọ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀, torí pé kò sí koríko.
כי גם אילת בשדה ילדה ועזוב כי לא היה דשא
6 Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè òfìfo wọ́n sì ń mí ẹ̀fúùfù bí ìkookò ojú wọn kò ríran nítorí pé kò sí koríko jíjẹ.”
ופראים עמדו על שפים שאפו רוח כתנים כלו עיניהם כי אין עשב
7 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ́rìí lòdì sí wa, wá nǹkan kan ṣe sí i Olúwa, nítorí orúkọ rẹ. Nítorí ìpadàsẹ́yìn wa ti pọ̀jù, a ti ṣẹ̀ sí ọ.
אם עונינו ענו בנו--יהוה עשה למען שמך כי רבו משובתינו לך חטאנו
8 Ìrètí Israẹli; ìgbàlà rẹ lásìkò ìpọ́njú, èéṣe tí ìwọ dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà bí arìnrìn-àjò tí ó dúró fún bí òru ọjọ́ kan péré?
מקוה ישראל מושיעו בעת צרה--למה תהיה כגר בארץ וכארח נטה ללון
9 Èéṣe tí ìwọ dàbí ẹni tí a dààmú, bí jagunjagun tí kò le ran ni lọ́wọ́? Ìwọ wà láàrín wa, Olúwa, orúkọ rẹ ni a sì ń pè mọ́ wa; má ṣe fi wá sílẹ̀.
למה תהיה כאיש נדהם כגבור לא יוכל להושיע ואתה בקרבנו יהוה ושמך עלינו נקרא--אל תנחנו
10 Báyìí ni Olúwa sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí: “Wọ́n fẹ́ràn láti máa rìn kiri; wọn kò kó ọkàn wọn ní ìjánu. Nítorí náà Olúwa kò gbà wọ́n; yóò wá rántí ìwà búburú wọn báyìí, yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n.”
כה אמר יהוה לעם הזה כן אהבו לנוע--רגליהם לא חשכו ויהוה לא רצם--עתה יזכר עונם ויפקד חטאתם
11 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe gbàdúrà fún àlàáfíà àwọn ènìyàn wọ̀nyí.
ויאמר יהוה אלי אל תתפלל בעד העם הזה לטובה
12 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbààwẹ̀, èmi kò ní tẹ́tí sí igbe wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìyẹ̀fun, èmi ò nígbà wọ́n. Dípò bẹ́ẹ̀, èmi ó fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn pa wọ́n run.”
כי יצמו אינני שמע אל רנתם וכי יעלו עלה ומנחה אינני רצם כי בחרב וברעב ובדבר אנכי מכלה אותם
13 Ṣùgbọ́n mo sọ pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè. Àwọn wòlíì ń sọ fún wọn pé, ‘Ẹ kò ni rí idà tàbí ìyàn. Dájúdájú èmi ó fún yín ní àlàáfíà tí yóò tọ́jọ́ níbí yìí?’”
ואמר אהה אדני יהוה הנה הנבאים אמרים להם לא תראו חרב ורעב לא יהיה לכם כי שלום אמת אתן לכם במקום הזה
14 Nígbà náà Olúwa sọ fún mi pé, “Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi. Èmi kò rán wọn, tàbí yàn wọ́n tàbí bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké ni wọ́n ń rí sí i yín. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fún un yín nípa ìran ìrírí, àfọ̀ṣẹ, ìbọ̀rìṣà àti ìtànjẹ ọkàn wọn.
ויאמר יהוה אלי שקר הנבאים נבאים בשמי--לא שלחתים ולא צויתים ולא דברתי אליהם חזון שקר וקסם ואלול (ואליל) ותרמות (ותרמית) לבם המה מתנבאים לכם
15 Nítorí náà, èyí ni Olúwa sọ nípa àwọn wòlíì tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ mi. Èmi kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n sì ń sọ pé, ‘Idà kan tàbí ìyàn, kì yóò dé ilẹ̀ yìí.’ Àwọn wòlíì kan náà yóò parẹ́ nípa idà àti ìyàn.
לכן כה אמר יהוה על הנבאים הנבאים בשמי ואני לא שלחתים והמה אמרים חרב ורעב לא יהיה בארץ הזאת בחרב וברעב יתמו הנבאים ההמה
16 Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ni a ó lé sí òpópónà Jerusalẹmu torí idà àti ìyàn. Wọn kò ní i rí ẹni tí yóò sìn wọ́n tàbí ìyàwó wọn, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn. Èmi yóò mú ìdààmú tí ó yẹ bá ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.
והעם אשר המה נבאים להם יהיו משלכים בחצות ירושלם מפני הרעב והחרב ואין מקבר להמה--המה נשיהם ובניהם ובנתיהם ושפכתי עליהם את רעתם
17 “Kí ìwọ kí ó sì sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn pé: “‘Jẹ́ kí ojú mi kí ó sun omijé ní ọ̀sán àti ní òru láìdá; nítorí tí a ti ṣá wúńdíá, ọmọ ènìyàn mi ní ọgbẹ́ ńlá pẹ̀lú lílù bolẹ̀.
ואמרת אליהם את הדבר הזה תרדנה עיני דמעה לילה ויומם ואל תדמינה כי שבר גדול נשברה בתולת בת עמי--מכה נחלה מאד
18 Bí mo bá lọ sí orílẹ̀-èdè náà, Èmi yóò rí àwọn tí wọ́n fi idà pa. Bí mo bá lọ sí ìlú ńlá, èmi rí àwọn tí ìyàn ti sọ di aláàrùn. Wòlíì àti Àlùfáà ti lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.’”
אם יצאתי השדה והנה חללי חרב ואם באתי העיר והנה תחלואי רעב כי גם נביא גם כהן סחרו אל ארץ ולא ידעו
19 Ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ pátápátá ni? Ṣé o ti ṣá Sioni tì? Èéṣe tí o fi pọ́n wa lójú tí a kò fi le wò wá sàn? A ń retí àlàáfíà ṣùgbọ́n ohun rere kan kò tí ì wá, ní àsìkò ìwòsàn ìpayà là ń rí.
המאס מאסת את יהודה אם בציון געלה נפשך--מדוע הכיתנו ואין לנו מרפא קוה לשלום ואין טוב ולעת מרפא והנה בעתה
20 Olúwa, a jẹ́wọ́ ìwà ibi wa àti àìṣedéédéé àwọn baba wa; lóòótọ́ ni a ti ṣẹ̀ sí ọ.
ידענו יהוה רשענו עון אבותינו כי חטאנו לך
21 Nítorí orúkọ rẹ má ṣe kórìíra wa; má ṣe sọ ìtẹ́ ògo rẹ di àìlọ́wọ̀. Rántí májẹ̀mú tí o bá wa dá kí o má ṣe dà á.
אל תנאץ למען שמך אל תנבל כסא כבודך זכר אל תפר בריתך אתנו
22 Ǹjẹ́ èyíkéyìí àwọn òrìṣà yẹ̀yẹ́ tí àwọn orílẹ̀-èdè le ṣe kí òjò rọ̀? Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ fúnra rẹ̀ rọ òjò bí? Rárá, ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run wa. Torí náà, ìrètí wa wà lọ́dọ̀ rẹ, nítorí pé ìwọ lo ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.
היש בהבלי הגוים מגשמים ואם השמים יתנו רבבים הלא אתה הוא יהוה אלהינו ונקוה לך--כי אתה עשית את כל אלה

< Jeremiah 14 >