< Jeremiah 10 >

1 Gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ fún yín ẹ̀yin ilé Israẹli.
שמעו את הדבר אשר דבר יהוה עליכם--בית ישראל
2 Báyìí ni Olúwa wí: “Má ṣe kọ́ ìwà àwọn kèfèrí, kí àmì ọ̀run kí ó má sì dààmú yín, nítorí pé wọ́n ń dààmú orílẹ̀-èdè.
כה אמר יהוה אל דרך הגוים אל תלמדו ומאתות השמים אל תחתו כי יחתו הגוים מהמה
3 Nítorí pé asán ni àṣà àwọn ènìyàn, wọ́n gé igi láti inú igbó, oníṣọ̀nà sì gbẹ́ ẹ pẹ̀lú àáké rẹ̀.
כי חקות העמים הבל הוא כי עץ מיער כרתו מעשה ידי חרש במעצד
4 Wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́. Wọ́n fi òòlù kàn án àti ìṣó kí ó má ba à ṣubú.
בכסף ובזהב ייפהו במסמרות ובמקבות יחזקום ולוא יפיק
5 Wọ́n wé mọ́ igi bí ẹ̀gúnsí inú oko, òrìṣà wọn kò le è fọhùn. Wọ́n gbọdọ̀ máa gbé wọn nítorí pé wọn kò lè rìn. Má ṣe bẹ̀rù wọn; wọn kò le è ṣe ibi kankan bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si lè ṣe rere kan.”
כתמר מקשה המה ולא ידברו נשוא ינשוא כי לא יצעדו אל תיראו מהם כי לא ירעו וגם היטיב אין אותם
6 Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ Olúwa; o tóbi orúkọ rẹ sì tóbi lágbára.
מאין כמוך יהוה גדול אתה וגדול שמך בגבורה
7 Ta ni kò yẹ kí ó bẹ̀rù rẹ? Ọba àwọn orílẹ̀-èdè? Nítorí tìrẹ ni. Láàrín àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní orílẹ̀-èdè àti gbogbo ìjọba wọn, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ.
מי לא יראך מלך הגוים כי לך יאתה כי בכל חכמי הגוים ובכל מלכותם מאין כמוך
8 Gbogbo wọn jẹ́ aláìlóye àti aṣiwèrè, wọ́n ń kọ́ ẹ̀kọ́ àwọn ère igi tí kò níláárí.
ובאחת יבערו ויכסלו מוסר הבלים עץ הוא
9 Fàdákà tí a ti kàn ni a mú wá láti Tarṣiṣi, àti wúrà láti Upasi. Èyí tí àwọn oníṣọ̀nà àti alágbẹ̀dẹ ṣe tí wọ́n kùn ní àwọ̀ aró àti elése àlùkò, èyí jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà.
כסף מרקע מתרשיש יובא וזהב מאופז--מעשה חרש וידי צורף תכלת וארגמן לבושם מעשה חכמים כלם
10 Ṣùgbọ́n Olúwa ni Ọlọ́run tòótọ́, òun ni Ọlọ́run alààyè, ọba ayérayé. Nígbà tí ó bá bínú, ayé yóò wárìrì; orílẹ̀-èdè kò lè fi ara da ìbínú rẹ̀.
ויהוה אלהים אמת הוא אלהים חיים ומלך עולם מקצפו תרעש הארץ ולא יכלו גוים זעמו
11 “Sọ èyí fún wọn: ‘Àwọn ọlọ́run kéékèèké tí kò dá ọ̀run àti ayé ni yóò ṣègbé láti ayé àti ní abẹ́ ọ̀run.’”
כדנה תאמרון להום אלהיא די שמיא וארקא לא עבדו יאבדו מארעא ומן תחות שמיא אלה
12 Ọlọ́run dá ayé pẹ̀lú agbára rẹ̀, ó dá àgbáyé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀, ó mú kí ọ̀run kí ó fẹ̀ síta nípa òye rẹ̀.
עשה ארץ בכחו מכין תבל בחכמתו ובתבונתו נטה שמים
13 Nígbà tí ó bá sán àrá, àwọn omi lọ́run a sì pariwo; ó mú kí ìkùùkuu ru sókè láti òpin ayé. Ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò, ó sì ń mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀.
לקול תתו המון מים בשמים ויעלה נשאים מקצה ארץ (הארץ) ברקים למטר עשה ויוצא רוח מאצרתיו
14 Gbogbo ènìyàn jẹ́ aṣiwèrè àti aláìnímọ̀, ojú ti gbogbo alágbẹ̀dẹ níwájú ère rẹ̀, nítorí ère dídá rẹ̀ èké ni, kò sì ṣí ẹ̀mí nínú rẹ̀.
נבער כל אדם מדעת הביש כל צורף מפסל כי שקר נסכו ולא רוח בם
15 Asán ni wọ́n, iṣẹ́ ìṣìnà; nígbà ìbẹ̀wò wọn, wọn yóò ṣègbé.
הבל המה מעשה תעתעים בעת פקדתם יאבדו
16 Ẹni tí ó bá jẹ́ ìpín Jakọbu kò sì dàbí èyí, nítorí òun ni ó ṣẹ̀dá ohun gbogbo àti Israẹli tí ó jẹ́ ẹ̀yà ìjogún rẹ̀. Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.
לא כאלה חלק יעקב כי יוצר הכל הוא וישראל שבט נחלתו יהוה צבאות שמו
17 Kó ẹrù rẹ kúrò láti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀ ìwọ tí o ń gbé ní ìlú tí a dó tì.
אספי מארץ כנעתך--ישבתי (ישבת) במצור
18 Nítorí èyí ni Olúwa wí: “Ní àkókò yìí, èmi yóò gbọn àwọn tí ó ń gbé ilẹ̀ náà jáde. Èmi yóò mú ìpọ́njú bá wọn, kí wọn kí ó lè rí wọn mú.”
כי כה אמר יהוה הנני קולע את יושבי הארץ בפעם הזאת והצרתי להם למען ימצאו
19 Ègbé ni fún mi nítorí ìpalára mi! Ọgbẹ́ mi jẹ́ èyí tí kò lè sàn, bẹ́ẹ̀ ni mọ sọ fún ara mi, “Èyí ni àìsàn mi, mo sì gbọdọ̀ fi orí tì í.”
אוי לי על שברי נחלה מכתי ואני אמרתי אך זה חלי ואשאנו
20 Àgọ́ mi bàjẹ́, gbogbo okùn rẹ̀ sì já. Àwọn ọmọ mi ti lọ lọ́dọ̀ mi, wọn kò sì sí mọ́, kò sí ẹnìkankan tí yóò na àgọ́ mi ró mọ́, tàbí yóò ṣe ibùgbé fún mi.
אהלי שדד וכל מיתרי נתקו בני יצאני ואינם--אין נטה עוד אהלי ומקים יריעותי
21 Àwọn olùṣọ́-àgùntàn jẹ́ aṣiwèrè, wọn kò sì wá Olúwa: nítorí náà wọn kì yóò ṣe rere àti pé gbogbo agbo wọn ni yóò túká.
כי נבערו הרעים ואת יהוה לא דרשו על כן לא השכילו וכל מרעיתם נפוצה
22 Fetísílẹ̀! ariwo igbe ń bọ̀, àti ìdàrúdàpọ̀ ńlá láti ilẹ̀ àríwá wá! Yóò sì sọ ìlú Juda di ahoro, àti ihò ọ̀wàwà.
קול שמועה הנה באה ורעש גדול מארץ צפון לשום את ערי יהודה שממה--מעון תנים
23 Èmi mọ̀ Olúwa wí pé ọ̀nà ènìyàn kì í ṣe ti ara rẹ̀, kì í ṣe fún ènìyàn láti tọ́ ìgbésẹ̀ ara rẹ̀.
ידעתי יהוה כי לא לאדם דרכו לא לאיש הלך והכין את צעדו
24 Tún mi ṣe Olúwa, pẹ̀lú ìdájọ́ nìkan kí o má sì ṣe é nínú ìbínú rẹ, kí ìwọ má ṣe sọ mí di òfo.
יסרני יהוה אך במשפט אל באפך פן תמעטני
25 Tú ìbínú rẹ jáde sórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́n, sórí àwọn ènìyàn tí wọn kò pe orúkọ rẹ. Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run, wọ́n ti jẹ ẹ́ run pátápátá, wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ̀ di ahoro.
שפך חמתך על הגוים אשר לא ידעוך ועל משפחות אשר בשמך לא קראו כי אכלו את יעקב ואכלהו ויכלהו ואת נוהו השמו

< Jeremiah 10 >