< James 4 >
1 Níbo ni ogun ti wá, níbo ni ìjà sì ti wá láàrín yín? Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín ha kọ́ ni tí ó ń jagun nínú àwọn ẹ̀yà ara yín bí?
Where do the wars and disputes among you come from? Is it not precisely from your pleasures, the ones at war in your members?
2 Ẹ̀yin ń fẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ẹ kò sì ní, ẹ̀yin ń pànìyàn, ẹ sì ń ṣe ìlara, ẹ kò sì le ní: ẹ̀yin ń jà, ẹ̀yin sì ń jagun; ẹ kò ní, nítorí tí ẹ̀yin kò béèrè.
You crave and do not have; you murder and covet and are not able to obtain; you fight and war. You do not have because you do not ask.
3 Ẹ̀yin béèrè, ẹ kò sì rí gbà, nítorí tí ẹ̀yin ṣì béèrè, kí ẹ̀yin kí ó lè lò ó fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín.
You ask and do not receive because you ask wrongly, so that you may lavish it on your pleasures.
4 Ẹ̀yin panṣágà ọkùnrin, àti panṣágà obìnrin, ẹ kò mọ̀ pé ìbárẹ́ ayé ìṣọ̀tá Ọlọ́run ni? Nítorí náà ẹni tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé di ọ̀tá Ọlọ́run.
Adulterers and adulteresses! Do you not know that friendship with the world is enmity with God? So whoever may want to be a friend of the world makes himself an enemy of God.
5 Ẹ̀yin ṣe bí Ìwé Mímọ́ sọ lásán pé, Ẹ̀mí tí ó fi sínú wa ń jowú gidigidi lórí wa?
Or do you suppose that the Scripture says in vain that the Spirit who dwells in us yearns jealously?
6 Ṣùgbọ́n ó fún ni ní oore-ọ̀fẹ́ sí i. Nítorí náà ni ìwé mímọ́ ṣe wí pé, “Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn agbéraga, ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn.”
But He gives greater grace; therefore He says: “God resists proud ones, but gives grace to humble ones.”
7 Nítorí náà, ẹ tẹríba fún Ọlọ́run. Ẹ kọ ojú ìjà sí èṣù, òun ó sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.
Therefore submit to God. Resist the devil and he will flee from you.
8 Ẹ súnmọ́ Ọlọ́run, òun ó sì súnmọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀; ẹ sì ṣe ọkàn yín ní mímọ́, ẹ̀yin oníyèméjì.
Draw near to God and He will draw near to you. Sinners, cleanse your hands! Double-minded, purify your hearts!
9 Ẹ banújẹ́, ẹ ṣọ̀fọ̀, kí ẹ sì hu fún ẹkún. Ẹ jẹ́ kí ẹ̀rín yín kí ó di ọ̀fọ̀, àti ayọ̀ yín kí ó di ìbànújẹ́.
Lament and mourn and weep! Let your laughter be turned into mourning, and your joy into dejection.
10 Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Olúwa, òun ó sì gbé yín ga.
Humble yourself before the Lord and He will exalt you.
11 Ará, ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ ibi sí ara yín. Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ibi sí arákùnrin rẹ̀, tí ó ń dá arákùnrin rẹ̀ lẹ́jọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ibi sí òfin, ó sì ń dá òfin lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń dá òfin lẹ́jọ́, ìwọ kì í ṣe olùfẹ́ òfin, bí kò ṣe onídàájọ́.
Brothers, do not speak evil of one another. Because the one speaking against a brother and judging his brother speaks against a law and judges a law. So if you judge a law you are not a law-doer but a judge.
12 Aṣòfin àti onídàájọ́ kan ṣoṣo ní ó ń bẹ, àní ẹni tí ó lè gbàlà tí ó sì le parun, ṣùgbọ́n ta ni ìwọ tí ó ń dá ẹnìkejì rẹ lẹ́jọ́?
The Lawgiver and Judge is One, the one who is able to save and to destroy. So who are you (sg) to be judging someone who is different?
13 Ẹ wá nísinsin yìí, ẹ̀yin tí ó ń wí pé, “Lónìí tàbí lọ́la àwa ó lọ sí ìlú báyìí, a ó sì ṣe ọdún kan níbẹ̀, a ó sì ṣòwò, a ó sì jèrè.”
Come now, you who say, “Today and tomorrow let us travel to that certain city, spend a year there, do business and make a profit;”
14 Nígbà tí ẹ̀yin kò mọ ohun tí yóò hù lọ́la. Kí ni ẹ̀mí yín? Ìkùùkuu sá à ni yín, tí ó hàn nígbà díẹ̀, lẹ́yìn náà a sì túká lọ.
whereas you do not know anything about the morrow. For what is our life? It is even a vapor that appears for a little time but then vanishes away.
15 Èyí tí ẹ̀ bá fi wí pé, “Bí Olúwa bá fẹ́, àwa yóò wà láààyè, àwa ó sì ṣe èyí tàbí èyí i nì.”
Instead you ought to say, “If the Lord wills, we will live and do this or that.”
16 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ń gbéraga nínú ìfọ́nnu yín, gbogbo irú ìfọ́nnu bẹ́ẹ̀, ibi ni.
But now you boast in your arrogant pretensions. All such boasting is malignant.
17 Nítorí náà ẹni tí ó bá mọ rere í ṣe tí kò sì ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni fún un.
Therefore, to the one knowing to do good and not doing it, to him it is sin.