< Isaiah 1 >

1 Ìran sí Juda àti Jerusalẹmu èyí tí Isaiah ọmọ Amosi rí ní àsìkò ìjọba Ussiah, Jotamu, Ahasi àti Hesekiah àwọn ọba Juda.
当乌西雅、约坦、亚哈斯、希西家作犹大王的时候,亚摩斯的儿子以赛亚得默示,论到犹大和耶路撒冷。
2 Gbọ́ ẹ̀yin ọ̀run! Fi etí sílẹ̀, ìwọ ayé! Nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀: “Mo tọ́ àwọn ọmọ dàgbà, ṣùgbọ́n wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi.
天哪,要听!地啊,侧耳而听! 因为耶和华说: 我养育儿女,将他们养大, 他们竟悖逆我。
3 Màlúù mọ olówó rẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì mọ ibùjẹ olówó rẹ̀, ṣùgbọ́n Israẹli kò mọ̀, òye kò yé àwọn ènìyàn mi.”
牛认识主人, 驴认识主人的槽, 以色列却不认识; 我的民却不留意。
4 Á à! Orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀, àwọn ènìyàn tí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lẹ́rù, ìran àwọn aṣebi, àwọn ọmọ tó ti di aṣèbàjẹ́! Wọn ti kọ Olúwa sílẹ̀ wọn ti gan Ẹni Mímọ́ Israẹli, wọn sì ti kẹ̀yìn sí i.
嗐!犯罪的国民, 担着罪孽的百姓; 行恶的种类, 败坏的儿女! 他们离弃耶和华, 藐视以色列的圣者, 与他生疏,往后退步。
5 Èéṣe tí a ó fi tún lù yín mọ́? Èéṣe tí ẹ ò dẹ́kun ọ̀tẹ̀ ṣíṣe? Gbogbo orí yín jẹ́ kìkì ọgbẹ́, gbogbo ọkàn yín sì ti pòruurù.
你们为什么屡次悖逆, 还要受责打吗? 你们已经满头疼痛, 全心发昏。
6 Láti àtẹ́lẹsẹ̀ yín dé àtàrí yín kò sí àlàáfíà rárá, àyàfi ọgbẹ́ òun ìfarapa àti ojú egbò, tí a kò nù kúrò tàbí kí á dì tàbí kí a kùn ún ní òróró.
从脚掌到头顶, 没有一处完全的, 尽是伤口、青肿,与新打的伤痕, 都没有收口,没有缠裹, 也没有用膏滋润。
7 Orílẹ̀-èdè yín dahoro, a dáná sun àwọn ìlú yín, oko yín ni àwọn àjèjì ti jẹ run lójú ara yín náà, ni gbogbo rẹ̀ ṣòfò bí èyí tí àwọn àjèjì borí rẹ̀.
你们的地土已经荒凉; 你们的城邑被火焚毁。 你们的田地在你们眼前为外邦人所侵吞, 既被外邦人倾覆就成为荒凉。
8 Ọmọbìnrin Sioni ni a fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àtíbàbà nínú ọgbà àjàrà, gẹ́gẹ́ bí abà nínú oko ẹ̀gúnsí, àti bí ìlú tí a dó tì.
仅存锡安城, 好像葡萄园的草棚, 瓜田的茅屋, 被围困的城邑。
9 Àyàfi bí Olúwa àwọn ọmọ-ogun bá ṣẹ́ díẹ̀ kù fún wà, a ò bá ti rí bí Sodomu, a ò bá sì ti dàbí Gomorra.
若不是万军之耶和华给我们稍留余种, 我们早已像所多玛、蛾摩拉的样子了。
10 Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin aláṣẹ Sodomu, tẹ́tí sí òfin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn Gomorra!
你们这所多玛的官长啊, 要听耶和华的话! 你们这蛾摩拉的百姓啊, 要侧耳听我们 神的训诲!
11 “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín kín ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín jásí fún mi?” ni Olúwa wí. “Mo ti ní ànító àti àníṣẹ́kù ẹbọ sísun ti àgbò àti ọ̀rá ẹran àbọ́pa, Èmi kò ní inú dídùn nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù, ti àgùntàn àti ti òbúkọ.
耶和华说: 你们所献的许多祭物与我何益呢? 公绵羊的燔祭和肥畜的脂油, 我已经够了; 公牛的血,羊羔的血,公山羊的血, 我都不喜悦。
12 Nígbà tí ẹ wá farahàn níwájú mi, ta ni ó béèrè èyí lọ́wọ́ yín, gìrì gìrì ẹsẹ̀ nínú àgbàlá mi?
你们来朝见我, 谁向你们讨这些, 使你们践踏我的院宇呢?
13 Ẹ má mú ọrẹ asán wá mọ́! Ìríra ni tùràrí yín jásí fún mi, oṣù tuntun àti ọjọ́ ìsinmi àti àwọn àpéjọ, Èmi kò lè faradà á, ẹ̀ṣẹ̀ ni àpéjọ yín wọ̀nyí.
你们不要再献虚浮的供物。 香品是我所憎恶的; 月朔和安息日,并宣召的大会, 也是我所憎恶的; 作罪孽,又守严肃会, 我也不能容忍。
14 Ayẹyẹ oṣù tuntun yín àti àjọ̀dún tí a yàn, ni ọkàn mi kórìíra. Wọ́n ti di àjàgà sí mi ní ọrùn, Ó sú mi láti fi ara dà wọ́n.
你们的月朔和节期,我心里恨恶, 我都以为麻烦; 我担当,便不耐烦。
15 Nígbà tí ẹ bá tẹ́ ọwọ́ yín sókè ni àdúrà, Èmi yóò fi ojú mi pamọ́ fún un yín, kódà bí ẹ bá gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà, Èmi kò ni tẹ́tí sí i. “Ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀.
你们举手祷告,我必遮眼不看; 就是你们多多地祈祷,我也不听。 你们的手都满了杀人的血。
16 “Wẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí ara yín mọ́. Ẹ mú ìwà ibi yín kúrò níwájú mi! Dáwọ́ àìṣedéédéé dúró,
你们要洗濯、自洁, 从我眼前除掉你们的恶行, 要止住作恶,
17 kọ́ láti ṣe rere! Wá ìdájọ́ òtítọ́, tu àwọn tí a ń pọ́n lójú nínú. Ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba, gbà ẹjọ́ opó rò.
学习行善, 寻求公平, 解救受欺压的; 给孤儿伸冤, 为寡妇辨屈。
18 “Ẹ wá ní ìsinsin yìí, ẹ jẹ́ kí a jọ ṣàṣàrò,” ni Olúwa wí. “Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín bá rí bí osùn, wọn ó sì funfun bí i yìnyín, bí wọn bá sì pọ́n bí ẹ̀jẹ̀, wọn ó sì dàbí ẹ̀gbọ̀n òwú.
耶和华说: 你们来,我们彼此辩论。 你们的罪虽像朱红,必变成雪白; 虽红如丹颜,必白如羊毛。
19 Tí ẹ̀yin bá fẹ́, tí ẹ sì gbọ́rọ̀, ẹ̀yin yóò sì jẹ ojúlówó adùn ilẹ̀ náà.
你们若甘心听从, 必吃地上的美物,
20 Ṣùgbọ́n tí ẹ bá kọ̀ tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀, idà ni a ó fi pa yín run.” Nítorí ẹnu Olúwa la ti sọ ọ́.
若不听从,反倒悖逆, 必被刀剑吞灭。 这是耶和华亲口说的。
21 Wo bí ìlú òtítọ́ ṣe di àgbèrè! Ó ti kún fún ìdájọ́ òtítọ́ nígbà kan rí, òdodo ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí, ṣùgbọ́n báyìí àwọn apànìyàn!
可叹,忠信的城变为妓女! 从前充满了公平, 公义居在其中, 现今却有凶手居住。
22 Fàdákà rẹ ti di ìpẹ́pẹ́, ààyò wáìnì rẹ la ti bu omi là.
你的银子变为渣滓; 你的酒用水搀对。
23 Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn aláṣẹ yín, akẹgbẹ́ àwọn olè, gbogbo wọn ló fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n sì ń wá ẹ̀bùn kiri. Wọ́n kì í ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba, ẹjọ́ opó kì í sì í dé iwájú wọn.
你的官长居心悖逆, 与盗贼作伴, 各都喜爱贿赂, 追求赃私。 他们不为孤儿伸冤; 寡妇的案件也不得呈到他们面前。
24 Nítorí náà ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, alágbára kan ṣoṣo tí Israẹli sọ wí pé: “Á à! Èmi yóò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá mi n ó sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi.
因此,主—万军之耶和华、 以色列的大能者说: 哎!我要向我的对头雪恨, 向我的敌人报仇。
25 Èmi yóò pa ọwọ́ mi dà sí ọ, èmi ó sì ku ìpẹ́pẹ́ rẹ dànù, n ó sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò.
我必反手加在你身上, 炼尽你的渣滓, 除净你的杂质。
26 Èmi yóò mú àwọn adájọ́ rẹ bọ̀ sí ipò gẹ́gẹ́ bí i ti àtijọ́, àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ bí i ti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Lẹ́yìn náà ni a ó pè ọ ní ìlú òdodo, ìlú òtítọ́.”
我也必复还你的审判官,像起初一样, 复还你的谋士,像起先一般。 然后,你必称为公义之城, 忠信之邑。
27 A ó fi ìdájọ́ òtítọ́ ra Sioni padà, àti àwọn tí ó ronúpìwàdà pẹ̀lú òdodo.
锡安必因公平得蒙救赎; 其中归正的人必因公义得蒙救赎。
28 Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni a ó parun. Àwọn tí ó bá sì kọ Olúwa sílẹ̀ ni yóò ṣègbé.
但悖逆的和犯罪的必一同败亡; 离弃耶和华的必致消灭。
29 “Ojú yóò tì yín nítorí igi óákù mímọ́ èyí tí ẹ ní inú dídùn sí, a ó kàn yín lábùkù nítorí àwọn ọgbà yìí tí ẹ ti yàn fúnra yín.
那等人必因你们所喜爱的橡树抱愧; 你们必因所选择的园子蒙羞。
30 Ẹ ó sì dàbí igi óákù tí ewé rẹ̀ ti rọ, bí ọgbà tí kò ní omi.
因为,你们必如叶子枯干的橡树, 好像无水浇灌的园子。
31 Alágbára ọkùnrin náà yóò sì dàbí ohun ìdáná, iṣẹ́ rẹ̀ bí ẹ̀ṣẹ́-iná, àwọn méjèèjì ni yóò jóná papọ̀, láìsí ẹni tí yóò lè pa iná yìí.”
有权势的必如麻瓤; 他的工作好像火星, 都要一同焚毁,无人扑灭。

< Isaiah 1 >