< Isaiah 7 >

1 Nígbà tí Ahasi ọmọ Jotamu ọmọ Ussiah jẹ́ ọba Juda, ọba Resini ti Aramu àti Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli gòkè wá láti bá Jerusalẹmu jà, ṣùgbọ́n wọn kò sì le è borí i rẹ̀.
Et factum est in diebus Achaz, filii Joathan, filii Oziæ, regis Juda, ascendit Rasin, rex Syriæ, et Phacee, filius Romeliæ, rex Israël, in Jerusalem, ad præliandum contra eam: et non potuerunt
2 Báyìí, a sọ fún ilé Dafidi pé, “Aramu mà ti lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Efraimu”; fún ìdí èyí, ọkàn Ahasi àti àwọn ènìyàn rẹ̀ wárìrì gẹ́gẹ́ bí igi oko ṣe ń wárìrì níwájú afẹ́fẹ́.
debellare eam. Et nuntiaverunt domui David, dicentes: Requievit Syria super Ephraim. Et commotum est cor ejus, et cor populi ejus, sicut moventur ligna silvarum a facie venti.
3 Lẹ́yìn èyí, Olúwa sọ fún Isaiah pé, “Jáde, ìwọ àti ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ Ṣeari-Jaṣubu láti pàdé Ahasi ní ìpẹ̀kun ìṣàn omi ti adágún òkè, ní òpópó ọ̀nà tí ó lọ sí pápá Alágbàfọ̀.
Et dixit Dominus ad Isaiam: Egredere in occursum Achaz, tu et qui derelictus est Jasub, filius tuus, ad extremum aquæductus piscinæ superioris in via agri Fullonis;
4 Sọ fún un, ‘Ṣọ́ra à rẹ, fi ọkàn balẹ̀, kí o má ṣe bẹ̀rù. Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí kùkùté igi ìdáná méjèèjì yìí, nítorí ìbínú gbígbóná Resini àti Aramu àti ti ọmọ Remaliah.
et dices ad eum: [Vide ut sileas; noli timere, et cor tuum ne formidet a duabus caudis titionum fumigantium istorum, in ira furoris Rasin, regis Syriæ, et filii Romeliæ;
5 Aramu, Efraimu àti Remaliah ti dìtẹ̀ ìparun rẹ, wọ́n wí pé,
eo quod consilium inierit contra te Syria in malum, Ephraim, et filius Romeliæ, dicentes:
6 “Jẹ́ kí a kọlu Juda; jẹ́ kí a fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, kí a sì pín in láàrín ara wa, kí a sì fi ọmọ Tabeli jẹ ọba lórí i rẹ̀.”
Ascendamus ad Judam, et suscitemus eum, et avellamus eum ad nos, et ponamus regem in medio ejus filium Tabeel.
7 Síbẹ̀ èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: “‘Èyí kò ní wáyé èyí kò le ṣẹlẹ̀,
Hæc dicit Dominus Deus: Non stabit, et non erit istud;
8 nítorí Damasku ni orí Aramu, orí Damasku sì ni Resini. Láàrín ọdún márùnlélọ́gọ́ta Efraimu yóò ti fọ́ tí kì yóò le jẹ́ ènìyàn mọ́.
sed caput Syriæ Damascus, et caput Damasci Rasin; et adhuc sexaginta et quinque anni, et desinet Ephraim esse populus;
9 Orí Efraimu sì ni Samaria, orí Samaria sì ni ọmọ Remaliah. Bí ẹ̀yin kí yóò bá gbàgbọ́, lóòtítọ́, a kì yóò fi ìdí yín múlẹ̀.’”
et caput Ephraim Samaria, et caput Samariæ filius Romeliæ. Si non credideritis, non permanebitis.]
10 Bákan náà Olúwa tún bá Ahasi sọ̀rọ̀,
Et adjecit Dominus loqui ad Achaz, dicens:
11 “Béèrè fún àmì lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, bóyá ní ọ̀gbun tí ó jì jùlọ tàbí àwọn òkè tí ó ga jùlọ.” (Sheol h7585)
Pete tibi signum a Domino Deo tuo, in profundum inferni, sive in excelsum supra. (Sheol h7585)
12 Ṣùgbọ́n Ahasi sọ pé, “Èmi kì yóò béèrè; Èmi kò ní dán Olúwa wò.”
Et dixit Achaz: Non petam, et non tentabo Dominum.
13 Lẹ́yìn náà Isaiah sọ pé, “Gbọ́ ní ìsinsin yìí, ìwọ ilé Dafidi, kò ha tọ́ láti tán ènìyàn ní sùúrù, ìwọ yóò ha tan Ọlọ́run ní sùúrù bí?
Et dixit: [Audite ergo, domus David. Numquid parum vobis est molestos esse hominibus, quia molesti estis et Deo meo?
14 Nítorí náà, Olúwa fúnra ara rẹ̀ ni yóò fún ọ ní àmì kan. Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli.
Propter hoc dabit Dominus ipse vobis signum: ecce virgo concipiet, et pariet filium, et vocabitur nomen ejus Emmanuel.
15 Òun yóò jẹ wàrà àti oyin nígbà tí ó bá ní ìmọ̀ tó láti kọ ẹ̀bi àti láti yan rere.
Butyrum et mel comedet, ut sciat reprobare malum, et eligere bonum.
16 Ṣùgbọ́n kí ọ̀dọ́mọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń kọ ẹ̀bi àti láti yan rere, ilẹ̀ àwọn ọba méjèèjì tí ń bà ọ́ lẹ́rù wọ̀nyí yóò ti di ahoro.
Quia antequam sciat puer reprobare malum et eligere bonum, derelinquetur terra quam tu detestaris a facie duorum regum suorum.
17 Olúwa yóò mú àsìkò mìíràn wá fún ọ àti àwọn ènìyàn rẹ àti lórí ilé baba rẹ irú èyí tí kò sí láti ìgbà tí Efraimu ti yà kúrò ní Juda, yóò sì mú ọba Asiria wá.”
Adducet Dominus super te, et super populum tuum, et super domum patris tui, dies qui non venerunt a diebus separationis Ephraim a Juda, cum rege Assyriorum.
18 Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò súfèé pe àwọn eṣinṣin láti àwọn odò tó jìnnà ní Ejibiti wá, àti fún àwọn oyin láti ilẹ̀ Asiria.
Et erit in die illa: sibilabit Dominus muscæ quæ est in extremo fluminum Ægypti, et api quæ est in terra Assur;
19 Gbogbo wọn yóò sì wá dó sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè àti pàlàpálá òkúta, lára koríko ẹ̀gún àti gbogbo ibi ihò omi.
et venient, et requiescent omnes in torrentibus vallium, et in cavernis petrarum, et in omnibus frutetis, et in universis foraminibus.
20 Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò lo abẹ fífẹ́lẹ́ tí a yá láti ìkọjá odò Eufurate, ọba Asiria, láti fá irun orí àti ti àwọn ẹsẹ̀ ẹ yín, àti láti mú irùngbọ̀n yín kúrò pẹ̀lú.
In die illa radet Dominus in novacula conducta in his qui trans flumen sunt, in rege Assyriorum, caput et pilos pedum, et barbam universam.
21 Ní ọjọ́ náà, ọkùnrin kan yóò máa sin ọ̀dọ́ abo màlúù kan àti ewúrẹ́ méjì.
Et erit in die illa: nutriet homo vaccam boum, et duas oves,
22 Àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà tí wọn yóò máa fún un, yóò ní wàràǹkàṣì láti jẹ. Gbogbo àwọn tí ó bá kù ní ilẹ̀ náà yóò jẹ wàràǹkàṣì àti oyin.
et præ ubertate lactis comedet butyrum; butyrum enim et mel manducabit omnis qui relictus fuerit in medio terræ.
23 Ní ọjọ́ náà, ni gbogbo ibi tí àjàrà tí ó tó ẹgbẹ̀rún ṣékélì fàdákà, ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n nìkan ni yóò wà níbẹ̀.
Et erit in die illa: omnis locus ubi fuerint mille vites, mille argenteis, in spinas et in vepres erunt.
24 Àwọn ènìyàn yóò máa lọ síbẹ̀ pẹ̀lú ọrun àti ọfà nítorí pé ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n ni yóò bo gbogbo ilẹ̀ náà.
Cum sagittis et arcu ingredientur illuc: vepres enim et spinæ erunt in universa terra.
25 Àti ní orí àwọn òkè kéékèèké tí a ti ń fi ọkọ́ ro nígbà kan rí, ẹ kò ní lọ síbẹ̀ mọ́ nítorí ìbẹ̀rù ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n, wọn yóò di ibi tí a ń da màlúù lọ, àti ibi ìtẹ̀mọ́lẹ̀ fún àwọn àgùntàn kéékèèké.
Et omnes montes qui in sarculo sarrientur, non veniet illuc terror spinarum et veprium: et erit in pascua bovis, et in conculcationem pecoris.]

< Isaiah 7 >