< Isaiah 66 >
1 Báyìí ni Olúwa wí: “Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi. Níbo ni ilé tí ẹ ó kọ́ fún mi wà? Níbo ní ibi ìsinmi mi yóò gbé wà?
여호와께서 이같이 말씀하시되 하늘은 나의 보좌요 땅은 나의 발등상이니 너희가 나를 위하여 무슨 집을 지을꼬 나의 안식할 처소가 어디랴
2 Kì í ha á ṣe ọwọ́ mi ló tí ṣe nǹkan wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì wà?” ni Olúwa wí. “Eléyìí ni ẹni tí mo kà sí: ẹni náà tí ó rẹra rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì kẹ́dùn ní ọkàn rẹ̀, tí ó sì wárìrì sí ọ̀rọ̀ mi.
나 여호와가 말하노라 나의 손이 이 모든 것을 지어서 다 이루었느니라 무릇 마음이 가난하고 심령에 통회하며 나의 말을 인하여 떠는 자 그 사람은 내가 권고하려니와
3 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fi akọ màlúù rú ẹbọ ó dàbí ẹni tí ó pa ènìyàn kan àti ẹni tí ó bá fi ọ̀dọ́-àgùntàn kan tọrẹ, dàbí ẹni tí ó bẹ́ ajá kan lọ́rùn; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi irúgbìn ìyẹ̀fun tọrẹ dàbí ẹni tí ó mú ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ wá, ẹni tí ó bá sì sun tùràrí ìrántí, dàbí ẹni tí ó súre fún òrìṣà. Wọ́n ti yan ipa ọ̀nà tì wọ́n, ọkàn wọn pẹ̀lú sì láyọ̀ nínú ohun ìríra wọn,
소를 잡아 드리는 것은 살인함과 다름이 없고 어린 양으로 제사드리는 것은 개의 목을 꺾음과 다름이 없으며 드리는 예물은 돼지의 피와 다름이 없고 분향하는 것은 우상을 찬송함과 다름이 없이 하는 그들은 자기의 길을 택하며 그들의 마음은 가증한 것을 기뻐한즉
4 fún ìdí èyí ni èmi pẹ̀lú yóò ṣe fi ọwọ́ líle mú wọn n ó sì mú ohun tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀ wá sórí wọn. Nítorí nígbà tí mo pè, kò sí ẹni tí ó dáhùn, nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹnikẹ́ni kò tẹ́tí sílẹ̀. Wọ́n ṣe ohun búburú ní ojú mi wọ́n sì yan ohun tí mo kórìíra rẹ̀.”
나도 유혹을 그들에게 택하여 주며 그 무서워하는 것을 그들에게 임하게 하리니 이는 내가 불러도 대답하는 자 없으며 내가 말하여도 그들이 청종하지 않고 오직 나의 목전에 악을 행하며 나의 기뻐하지 아니하는 것을 택하였음이니라 하시니라
5 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin tí ẹ ń wárìrì nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀: “Àwọn arákùnrin yín tí wọ́n kórìíra yín, tí wọ́n ta yín nù nítorí orúkọ mi, wí pé, ‘Jẹ́ kí a yin Olúwa lógo, kí a le rí ayọ̀ yín!’ Ṣùgbọ́n àwọn ni ojú yóò tì.
여호와의 말씀을 인하여 떠는 자들아 그 말씀을 들을지어다 이르시되 너희 형제가 너희를 미워하며 내 이름을 인하여 너희를 쫓아내며 이르기를 여호와께서는 영광을 나타내사 너희 기쁨을 우리에게 보이시기를 원하노라 하였으나 그들은 수치를 당하리라 하셨느니라
6 Gbọ́ rògbòdìyàn láti ìlú wá, gbọ́ ariwo náà láti tẹmpili wá! Ariwo tí Olúwa ní í ṣe tí ó ń san án fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ ohun tí ó tọ́ sí wọn.
훤화하는 소리가 성읍에서부터 오며 목소리가 성전에서부터 들리니 이는 여호와께서 그 대적에게 보응하시는 목소리로다
7 “Kí ó tó lọ sí ìrọbí, ó ti bímọ; kí ó tó di pé ìrora dé bá a, ó ti bí ọmọkùnrin.
시온은 구로하기 전에 생산하며 고통을 당하기 전에 남자를 낳았으니
8 Ta ni ó ti gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí? Ta ni ó ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí? Ǹjẹ́ a le bí orílẹ̀-èdè kan níjọ́ kan tàbí kí orílẹ̀-èdè lalẹ̀hù ní ìṣẹ́jú kan? Síbẹ̀síbẹ̀ Sioni bẹ̀rẹ̀ rírọbí bẹ́ẹ̀ ni ó sì bí àwọn ọmọ rẹ̀.
이러한 일을 들은 자가 누구이며 이러한 일을 본 자가 누구이뇨 나라가 어찌 하루에 생기겠으며 민족이 어찌 순식간에 나겠느냐 그러나 시온은 구로하는 즉시에 그 자민을 순산하였도다
9 Ǹjẹ́ èmi a ha máa mú wá sí ìrọbí kí èmi má sì mú ni bí?” ni Olúwa wí. “Ǹjẹ́ èmi a ha máa ṣé ilé ọmọ nígbà tí mo ń mú ìbí wá?” Ni Ọlọ́run yín wí.
여호와께서 가라사대 내가 임산케 하였은즉 해산케 아니하겠느냐 네 하나님이 가라사대 나는 해산케 하는 자인즉 어찌 태를 닫겠느냐 하시니라
10 “Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀ kí inú yín kí ó sì dùn sí i, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀; ẹ yọ̀ gidigidi pẹ̀lú rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ó ti kẹ́dùn fún un.
예루살렘을 사랑하는 자여 다 그와 함께 기뻐하라 다 그와 함께 즐거워하라 그를 위하여 슬퍼하는 자여 다 그의 기쁨을 인하여 그와 함께 기뻐하라
11 Nítorí pé ẹ̀yin yóò mu ẹ o sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú ọmú rẹ̀ tí ó tu ni lára, ẹ̀yin yóò mu àmuyó ẹ ó sì gbádùn nínú àkúnwọ́sílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀.”
너희가 젖을 빠는 것 같이 그 위로하는 품에서 만족하겠고 젖을 넉넉히 빤 것같이 그 영광의 풍성함을 인하여 즐거워하리라
12 Nítorí báyìí ni Olúwa wí: “Èmi yóò fún un ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí odò àti ọrọ̀ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ìṣàn omi; ẹ̀yin yóò mu ọmú, a ó sì gbé yín ní apá rẹ̀ a ó bá yín ṣeré ní orúkún rẹ̀.
여호와께서 이같이 말씀하시되 보라 내가 그에게 평강을 강 같이, 그에게 열방의 영광을 넘치는 시내 같이 주리니 너희가 그 젖을 빨 것이며 너희가 옆에 안기며 그 무릎에서 놀 것이라
13 Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti í tu ọmọ rẹ̀ nínú, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò tù yín nínú a ó sì tù yín nínú lórí Jerusalẹmu.”
어미가 자식을 위로함 같이 내가 너희를 위로할 것인즉 너희가 예루살렘에서 위로를 받으리니
14 Nígbà tí ẹ bá rí èyí, inú yín yóò dùn ẹ̀yin yóò sì gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i koríko; ọwọ́ Olúwa ni a ó sọ di mí mọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ ni a ó fihàn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.
너희가 이를 보고 마음이 기뻐서 너희 뼈가 연한 풀의 무성함 같으리라 여호와의 손은 그 종들에게 나타나겠고 그의 진노는 그 원수에게 더하리라
15 Kíyèsi i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú iná àti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ tí ó dàbí ìjì líle; òun yóò mú ìbínú rẹ sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ìrunú, àti ìbáwí rẹ̀ pẹ̀lú ahọ́n iná.
보라 여호와께서 불에 옹위되어 강림하시리니 그 수레들은 회리바람 같으리로다 그가 혁혁한 위세로 노를 베푸시며 맹렬한 화염으로 견책하실 것이라
16 Nítorí pẹ̀lú iná àti idà ni Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ lórí i gbogbo ènìyàn, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí Olúwa yóò pa.
여호와께서 불과 칼로 모든 혈육에게 심판을 베푸신즉 여호와께 살륙 당할 자가 많으리니
17 “Gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì sọ ara wọn di mímọ́ láti lọ sínú ọgbà, tí wọ́n tẹ̀lé ẹni tí ó wà láàrín àwọn tí ó jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èkúté àti àwọn ohun ìríra mìíràn ni wọn yóò bá òpin wọn pàdé papọ̀,” ni Olúwa wí.
스스로 거룩히 구별하며 스스로 정결케 하고 동산에 들어가서 그 가운데 있는 자를 따라 돼지 고기와 가증한 물건과 쥐를 먹는자가 다 함께 망하리라 여호와의 말씀이니라
18 “Àti Èmi, nítorí ìgbésẹ̀ wọn àti èrò wọn, èmi ti múra tán láti wá kó àwọn orílẹ̀-èdè àti ahọ́n jọ, wọn yóò sì wá wo ògo mi.
내가 그들의 소위와 사상을 아노라 때가 이르면 열방과 열족을 모으리니 그들이 와서 나의 영광을 볼 것이며
19 “Èmi yóò sì gbé àmì kan kalẹ̀ láàrín wọn, èmi yóò sì rán díẹ̀ nínú àwọn tí ó sálà lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè Tarṣiṣi, sí àwọn ará Libia àti Ludi, sí Tubali àti ará Giriki, àti sí àwọn erékùṣù tí ó jìnnà réré tí kò tí ìgbọ́ nípa òkìkí mi tàbí kí ó rí ògo mi. Wọn yóò kéde ògo mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.
내가 그들 중에 징조를 세워서 그들 중 도피한 자를 열방 곧 다시스와 뿔과 활을 당기는 룻과 및 두발과 야완과 또 나의 명성을 듣지도 못하고 나의 영광을 보지도 못한 먼 섬들로 보내리니 그들이 나의 영광을 열방에 선파하리라
20 Wọn yóò sì mú àwọn arákùnrin yín wá, láti gbogbo orílẹ̀-èdè, sí òkè mímọ́ mi ní Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí Olúwa lórí ẹṣin, lórí kẹ̀kẹ́ ẹrù àti ọkọ̀-ẹṣin, àti lórí ìbáaka àti ìbákasẹ,” ni Olúwa wí. “Wọn yóò kó wọn wá, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israẹli ti mú ọrẹ oníhóró wọn wá, sínú Tẹmpili Olúwa nínú ohun èlò mímọ́.
나 여호와가 말하노라 이스라엘 자손이 예물을 깨끗한 그릇에 담아 여호와의 집에 드림 같이 그들이 너희 모든 형제를 열방에서 나의 성산 예루살렘으로 말과 수레와 교자와 노새와 약대에 태워다가 여호와께 예물로 드릴 것이요
21 Àti pé èmi yóò sì yan àwọn kan nínú wọn pẹ̀lú láti jẹ́ àlùfáà àti Lefi,” ni Olúwa wí.
나는 그 중에서 택하여 제사장과 레위인을 삼으리라 여호와의 말이니라
22 “Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun tí mo dá yóò ṣe wà níwájú mi títí láé,” ni Olúwa wí, “Bẹ́ẹ̀ ni orúkọ yín àti ìrandíran yín yóò pegedé.
나 여호와가 말하노라 나의 지을 새 하늘과 새 땅이 내 앞에 항상 있을 것 같이 너희 자손과 너희 이름이 항상 있으리라
23 Láti oṣù tuntun kan dé òmíràn àti láti ọjọ́ ìsinmi kan dé òmíràn, ni gbogbo ọmọ ènìyàn yóò wá, wọn yóò sì tẹríba níwájú mi,” ni Olúwa wí.
여호와가 말하노라 매 월삭과 매 안식일에 모든 혈육이 이르러 내 앞에 경배하리라
24 “Wọn yóò sì jáde lọ wọn yóò sì lọ wo òkú àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ sí mi; kòkòrò wọn kì yóò kú, bẹ́ẹ̀ ni iná wọn ni a kì yóò pa, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jẹ́ ohun ìríra fún gbogbo ọmọ ènìyàn.”
그들이 나가서 내게 패역한 자들의 시체들을 볼 것이라 그 벌레가 죽지 아니하며 그 불이 꺼지지 아니하여 모든 혈육에게 가증함이 되리라