< Isaiah 63 >

1 Ta nì eléyìí tí ó Edomu wá, ti òun ti aṣọ àrẹpọ́n láti Bosra wá? Ta nì eléyìí, tí ó ní ògo nínú aṣọ rẹ̀, tí ó ń yan bọ̀ wá nínú ọláńlá agbára rẹ̀? “Èmi ni ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú òdodo tí ó ní ipa láti gbàlà.”
¿Quién es este que viene de Edom: de Bosra, con vestidos bermejos? ¿Este, hermoso en su vestido, que va con la grandeza de su poder? Yo, el que hablo en justicia, grande para salvar.
2 Èéṣe tí aṣọ yín fi pupa gẹ́gẹ́ bí i tàwọn tí ń ṣiṣẹ́ ní ìfúntí?
¿Por qué es bermejo tu vestido? ¿y tus ropas como de el que ha pisado en lagar?
3 “Èmi nìkan ti dá tẹ ìfúntí wáìnì; láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹnikẹ́ni kò sì wà pẹ̀lú mi. Mo tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ ní ìbínú mi mo sì tẹ̀ wọ́n rẹ́ ní ìrunú mi ẹ̀jẹ̀ wọn sì fọ́n sí aṣọ mi, mo sì da àbàwọ́n sí gbogbo aṣọ mi.
Solo pisé el lagar, y de los pueblos nadie fue conmigo. Pisélos con mi ira, y los hollé con mi furor; y su sangre salpicó mis vestidos, y ensucié todas mis ropas.
4 Nítorí ọjọ́ ẹ̀san wà ní ọkàn mi àti pé ọdún ìràpadà mi ti dé.
Porque el día de la venganza está en mi corazón; y el año de mis redimidos es venido.
5 Mo wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti ṣe ìrànwọ́. Àyà fò mí pé ẹnikẹ́ni kò ṣèrànwọ́; nítorí náà apá mi ni ó ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún mi àti ìrunú mi ni ó gbé mi ró.
Miré pues, y no había quien ayudase; y abominé, que no hubiese quien me sustentase: y salvóme mi brazo, y me sustentó mi ira.
6 Mo tẹ orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀ nínú ìbínú mi; nínú ìrunú mi mo jẹ́ kí wọ́n mu mo sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ lórí erùpẹ̀.”
Y hollé los pueblos con mi ira, y los embriagué de mi furor, y derribé a tierra su fortaleza.
7 Èmi yóò sọ nípa àánú Olúwa, ìṣe rẹ gbogbo tí ó yẹ kí a yìn ín fún, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Olúwa ti ṣe fún wa, bẹ́ẹ̀ ni, ohun rere gbogbo tí ó ti ṣe fún ilé Israẹli, gẹ́gẹ́ bí àánú àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore rẹ̀.
De las misericordias de Jehová haré memoria, de las alabanzas de Jehová, como sobre todo lo que Jehová nos ha dado; y de la grandeza de su beneficencia a la casa de Israel, que les ha hecho según sus misericordias, y según la multitud de sus miseraciones.
8 Ó wí pé, “Lóòtítọ́ ènìyàn mi ni wọ́n, àwọn ọmọ tí kì yóò jẹ́ òpùrọ́ fún mi”; bẹ́ẹ̀ ni, ó sì di Olùgbàlà wọn.
Y dijo: Ciertamente mi pueblo son, hijos que no mienten; y fue su Salvador.
9 Nínú gbogbo ìpọ́njú wọn, inú òun pẹ̀lú bàjẹ́ àti angẹli tí ó wà níwájú rẹ̀ gbà wọ́n là. Nínú ìfẹ́ àti àánú rẹ̀, ó rà wọ́n padà; ó gbé wọn sókè ó sì pọ̀n wọ́n ní gbogbo ọjọ́ ìgbà n nì.
En toda angustia de ellos él fue angustiado, y el ángel de su faz los salvó: con su amor, y con su clemencia los redimió, y los trajo a cuestas, y los levantó todos los días del siglo.
10 Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ṣọ̀tẹ̀ wọ́n sì ba Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ nínú jẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà ó sì di ọ̀tá wọn òun tìkára rẹ̀ sì bá wọn jà.
Mas ellos fueron rebeldes, e hicieron enojar su Espíritu Santo: por lo cual se les volvió enemigo, y él mismo peleó contra ellos.
11 Lẹ́yìn náà ni àwọn ènìyàn rẹ̀ rántí ọjọ́ ìgbà n nì, àwọn ọjọ́ Mose àti àwọn ènìyàn rẹ̀ níbo ni ẹni náà wà tí ó mú wọn la Òkun já, pẹ̀lú olùṣọ́-àgùntàn agbo ẹran rẹ̀? Níbo ni ẹni náà wà tí ó rán Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrín wọn,
Empero acordóse de los días antiguos, de Moisés, y de su pueblo: ¿Dónde está el que los hizo subir de la mar con el pastor de su rebaño? ¿Dónde está el que puso en medio de él su Espíritu Santo?
12 ta ni ó rán apá ògo ti agbára rẹ̀ láti wà ní apá ọ̀tún Mose, ta ni ó pín omi ní yà níwájú wọn, láti gba òkìkí ayérayé fún ara rẹ̀,
¿El que los guió por la diestra de Moisés con el brazo de su gloria? ¿El que rompió las aguas, haciéndose a sí nombre perpetuo?
13 ta ni ó síwájú wọn la àwọn ọ̀gbun nì já? Gẹ́gẹ́ bí ẹṣin ni gbangba ìlú wọn tí kò sì kọsẹ̀;
El que los hizo ir por los abismos como un caballo por el desierto, nunca tropezaron.
14 gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran tí ó lọ sí pápá oko, a fún wọn ní ìsinmi láti ọwọ́ Ẹ̀mí Olúwa. Báyìí ni ẹ ṣe tọ́ àwọn ènìyàn yín láti fún ara yín ní orúkọ kan tí ó lógo.
El Espíritu de Jehová los pastoreó, como a una bestia que desciende al valle: así pastoreaste tu pueblo, para hacerte nombre glorioso.
15 Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì rí i láti ìtẹ́ ògo rẹ, mímọ́ àti ológo. Níbo ni ìtara àti agbára rẹ wà? Ìwà jẹ́ẹ́jẹ́ rẹ àti àánú rẹ ni a ti mú kúrò níwájú wa.
Mira desde el cielo, desde la morada de tu santidad, y de tu gloria. ¿Dónde está tu zelo, y tu fortaleza, la multitud de tus entrañas, y de tus miseraciones para conmigo? ¿Hánse estrechado?
16 Ṣùgbọ́n ìwọ ni baba wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Abrahamu kò mọ̀ wá tàbí Israẹli mọ ẹni tí à á ṣe; ìwọ, Olúwa ni Baba wa, Olùràpadà wa láti ìgbà n nì ni orúkọ rẹ.
Porque tú eres nuestro padre, que Abraham nos ignora, e Israel no nos conoce: Tú, Jehová, eres nuestro padre, nuestro Redentor perpetuo es tu nombre.
17 Èéṣe Olúwa tí o fi jẹ́ kí a ṣáko kúrò ní ojú ọ̀nà rẹ tí o sì ṣé àyà wa le tó bẹ́ẹ̀ tí àwa kò fi bọ̀wọ̀ fún ọ? Padà nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ẹ̀yà tí ṣe ogún ìní rẹ.
¿Por qué, o! Jehová, nos has hecho errar de tus caminos? ¿Endureciste nuestro corazón a tu temor? Vuélvete por tus siervos, por las tribus de tu heredad.
18 Fún ìgbà díẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ fi gba ibi mímọ́ rẹ, ṣùgbọ́n nísinsin yìí àwọn ọ̀tá wa ti tẹ ibi mímọ́ rẹ mọ́lẹ̀.
Por poco tiempo poseyó la tierra prometida, el pueblo de tu santidad: nuestros enemigos han hollado tu santuario.
19 Àwa jẹ́ tìrẹ láti ìgbà n nì; ṣùgbọ́n ìwọ kò tí ì jẹ ọba lé wọn lórí, a kò sì tí ì pè wọ́n mọ́ orúkọ rẹ.
Habemos sido como aquellos de quienes nunca te enseñoreaste, sobre los cuales nunca fue llamado tu nombre.

< Isaiah 63 >