< Isaiah 61 >

1 Ẹ̀mí Olúwa Olódùmarè wà lára mi nítorí Olúwa ti fi àmì òróró yàn mí láti wàásù ìyìnrere fún àwọn tálákà. Ó ti rán mi láti ṣe àwòtán oníròbìnújẹ́ láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn àti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n,
רוח אדני יהוה עלי--יען משח יהוה אתי לבשר ענוים שלחני לחבש לנשברי לב לקרא לשבוים דרור ולאסורים פקח קוח
2 láti kéde ọdún ojúrere Olúwa àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa, láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú,
לקרא שנת רצון ליהוה ויום נקם לאלהינו לנחם כל אבלים
3 àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú, òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀, àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn. A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo, irúgbìn Olúwa láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.
לשום לאבלי ציון לתת להם פאר תחת אפר שמן ששון תחת אבל--מעטה תהלה תחת רוח כהה וקרא להם אילי הצדק מטע יהוה להתפאר
4 Wọn yóò tún àwọn ahoro àtijọ́ kọ́ wọn yóò sì mú àwọn ibi ìparun àtijọ́-tijọ́ náà bọ̀ sípò; wọn yóò jí àwọn ahoro ìlú náà padà tí a ti parun láti ìrandíran sẹ́yìn.
ובנו חרבות עולם שממות ראשנים יקוממו וחדשו ערי חרב שממות דור ודור
5 Àwọn àjèjì ni yóò máa da ọ̀wọ́ ẹran rẹ; àwọn àlejò yóò sì ṣiṣẹ́ nínú oko àti ọgbà àjàrà rẹ.
ועמדו זרים ורעו צאנכם ובני נכר אכריכם וכרמיכם
6 A ó sì máa pè yín ní àlùfáà Olúwa, a ó pè yín ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa. Ẹ ó máa jẹ nínú ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti nínú ọrọ̀ wọn ni ẹ̀yin yóò máa ṣògo.
ואתם כהני יהוה תקראו--משרתי אלהינו יאמר לכם חיל גוים תאכלו ובכבודם תתימרו
7 Dípò àbùkù wọn àwọn ènìyàn mi yóò gba ìlọ́po méjì, àti dípò àbùkù wọn wọn yóò yọ̀ nínú ìní wọn; bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jogún ìlọ́po méjì ní ilẹ̀ wọn, ayọ̀ ayérayé yóò sì jẹ́ tiwọn.
תחת בשתכם משנה וכלמה ירנו חלקם לכן בארצם משנה יירשו שמחת עולם תהיה להם
8 “Nítorí Èmi, Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo; mo kórìíra olè jíjà àti ẹ̀ṣẹ̀. Ní òtítọ́ mi èmi yóò sẹ̀san fún wọn èmi yóò sì dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú wọn.
כי אני יהוה אהב משפט שנא גזל בעולה ונתתי פעלתם באמת וברית עולם אכרות להם
9 A ó mọ ìrandíran wọn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ìran wọn láàrín àwọn ènìyàn. Gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn yóò mọ̀ pé wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí Olúwa ti bùkún.”
ונודע בגוים זרעם וצאצאיהם בתוך העמים כל ראיהם יכירום כי הם זרע ברך יהוה
10 Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa; ọkàn mi yọ̀ nínú Ọlọ́run mi. Nítorí ó ti wọ̀ mí ní aṣọ ìgbàlà ó sì ṣe mí lọ́ṣọ̀ọ́ nínú aṣọ òdodo; gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ti ṣe orí rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ bí àlùfáà, àti bí ìyàwó ṣe ń ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́.
שוש אשיש ביהוה תגל נפשי באלהי--כי הלבישני בגדי ישע מעיל צדקה יעטני כחתן יכהן פאר וככלה תעדה כליה
11 Gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ti í mú irúgbìn jáde àti bí ọgbà ṣe ń mú irúgbìn dàgbà, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè yóò ṣe mú òdodo àti ìyìn kí ó ru sókè níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.
כי כארץ תוציא צמחה וכגנה זרועיה תצמיח--כן אדני יהוה יצמיח צדקה ותהלה נגד כל הגוים

< Isaiah 61 >