< Isaiah 59 >

1 Lódodo ọwọ́ Olúwa kò kúrú láti gbàlà, tàbí kí etí rẹ̀ wúwo láti gbọ́.
הן לא קצרה יד יהוה מהושיע ולא כבדה אזנו משמוע׃
2 Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yín ló ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run yín; ẹ̀ṣẹ̀ yín ti fi ojú u rẹ̀ pamọ́ fún un yín tó bẹ́ẹ̀ tí òun kò fi le gbọ́.
כי אם עונתיכם היו מבדלים בינכם לבין אלהיכם וחטאותיכם הסתירו פנים מכם משמוע׃
3 Nítorí ọwọ́ yín di aláìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀, àti ìka ọwọ́ yín fún ẹ̀bi. Ètè yín ń pa irọ́ púpọ̀, ahọ́n yín sì ń sọ̀rọ̀ nǹkan ibi.
כי כפיכם נגאלו בדם ואצבעותיכם בעון שפתותיכם דברו שקר לשונכם עולה תהגה׃
4 Kò sí ẹni tí ó béèrè fún ìdájọ́ òdodo; kò sí ẹni tí ó ro ẹjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́. Wọ́n gbẹ́kẹ̀lé àwíjàre asán àti ọ̀rọ̀ irọ́; wọ́n lóyún ìkà, wọn sì bí wàhálà.
אין קרא בצדק ואין נשפט באמונה בטוח על תהו ודבר שוא הרו עמל והוליד און׃
5 Wọn ń pa ẹ̀yin paramọ́lẹ̀ wọn sì ń ta owú aláǹtakùn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹyin wọn yóò kú, àti nígbà tí a pa ọ̀kan, paramọ́lẹ̀ ni ó jáde.
ביצי צפעוני בקעו וקורי עכביש יארגו האכל מביציהם ימות והזורה תבקע אפעה׃
6 Òwú wọn kò wúlò fún aṣọ rírán; wọn kò lè fi aṣọ tí wọ́n hun bo ara wọn. Iṣẹ́ wọn jẹ́ ti ibi, ìwà jàǹdùkú sì kún ọwọ́ wọn.
קוריהם לא יהיו לבגד ולא יתכסו במעשיהם מעשיהם מעשי און ופעל חמס בכפיהם׃
7 Ẹsẹ̀ wọn yára bọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀; wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀. Èrò wọn sì jẹ́ èrò ibi; ìparun àti ìdahoro ni ó wà ní ṣíṣe àmì ọ̀nà wọn.
רגליהם לרע ירצו וימהרו לשפך דם נקי מחשבותיהם מחשבות און שד ושבר במסלותם׃
8 Ọ̀nà àlàáfíà èyí ni wọn kò mọ̀; kò sí òdodo ní ojú ọ̀nà wọn wọ́n ti sọ wọ́n dì ọ̀nà kọ́rọkọ̀rọ, kò sí ẹni tí ó tọ ọ̀nà yìí tí yóò rí àlàáfíà.
דרך שלום לא ידעו ואין משפט במעגלותם נתיבותיהם עקשו להם כל דרך בה לא ידע שלום׃
9 Nítorí èyí ni ẹ̀tọ́ fi jìnnà sí wa, àti tí òdodo kò fi tẹ̀ wá lọ́wọ́. A ń wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ jẹ́ òkùnkùn; ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n à ń rìn nínú òjìji.
על כן רחק משפט ממנו ולא תשיגנו צדקה נקוה לאור והנה חשך לנגהות באפלות נהלך׃
10 Gẹ́gẹ́ bí afọ́jú à ń táràrà lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri tí a ń wá ọ̀nà wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí kò ní ojú. Ní ọ̀sán gangan ni à ń kọsẹ̀ bí ẹni pé alẹ́ ni; láàrín alágbára àwa dàbí òkú.
נגששה כעורים קיר וכאין עינים נגששה כשלנו בצהרים כנשף באשמנים כמתים׃
11 Gbogbo wa là ń ké bí i beari; àwa pohùnréré ẹkún bí àdàbà. A ń wá ìdájọ́ òdodo ṣùgbọ́n kò sí; à ń wọ́nà fún ìtúsílẹ̀, ṣùgbọ́n ó jìnnà réré.
נהמה כדבים כלנו וכיונים הגה נהגה נקוה למשפט ואין לישועה רחקה ממנו׃
12 Nítorí àwọn àṣìṣe wa pọ̀ níwájú rẹ, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ń jẹ́rìí takò wá. Àwọn àìṣedéédéé wa sì wà pẹ̀lú wa, àwa pẹ̀lú sì mọ àìṣedéédéé wa,
כי רבו פשעינו נגדך וחטאותינו ענתה בנו כי פשעינו אתנו ועונתינו ידענום׃
13 ọ̀tẹ̀ àti àrékérekè wa sí Olúwa, kíkọ ẹ̀yìn wa sí Ọlọ́run, dídá yánpọnyánrin àti ìnilára sílẹ̀, pípààrọ̀ tí ọkàn wa ti gbèrò síta.
פשע וכחש ביהוה ונסוג מאחר אלהינו דבר עשק וסרה הרו והגו מלב דברי שקר׃
14 Nítorí èyí ni a ṣe lé ìdájọ́ òdodo sẹ́yìn, àti ti òdodo dúró lókèèrè; òtítọ́ ti ṣubú ní òpópó ọ̀nà, òdodo kò sì le è wọlé.
והסג אחור משפט וצדקה מרחוק תעמד כי כשלה ברחוב אמת ונכחה לא תוכל לבוא׃
15 A kò rí òtítọ́ mọ́, àti ẹni tí ó bá sá fun ibi tì di ìjẹ. Olúwa wò ó ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ pé kò sí ìdájọ́ òdodo.
ותהי האמת נעדרת וסר מרע משתולל וירא יהוה וירע בעיניו כי אין משפט׃
16 Òun rí i pé kò sí ẹnìkan, àyà fò ó pé kò sí ẹnìkan láti ṣèrànwọ́; nítorí apá òun tìkára rẹ̀ ló ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún ara rẹ̀, àti òdodo òun tìkára rẹ̀ ló gbé e ró.
וירא כי אין איש וישתומם כי אין מפגיע ותושע לו זרעו וצדקתו היא סמכתהו׃
17 Ó gbé òdodo wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbàyà rẹ̀, àti àṣíborí ìgbàlà ní orí rẹ̀; ó gbé ẹ̀wù ẹ̀san wọ̀ ó sì yí ara rẹ̀ ní ìtara bí ẹ̀wù.
וילבש צדקה כשרין וכובע ישועה בראשו וילבש בגדי נקם תלבשת ויעט כמעיל קנאה׃
18 Gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni yóò san án ìbínú fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ àti ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀; òun yóò san án fún àwọn erékùṣù ẹ̀tọ́ wọn.
כעל גמלות כעל ישלם חמה לצריו גמול לאיביו לאיים גמול ישלם׃
19 Láti ìwọ̀-oòrùn, àwọn ènìyàn yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa, àti láti ìlà-oòrùn, wọn yóò bọ̀wọ̀ fún ògo rẹ̀. Nítorí òun yóò wá gẹ́gẹ́ bí i rírú omi èyí tí èémí Olúwa ń tì lọ.
וייראו ממערב את שם יהוה וממזרח שמש את כבודו כי יבוא כנהר צר רוח יהוה נססה בו׃
20 “Olùdáǹdè yóò wá sí Sioni, sí àwọn tí ó wà ní Jakọbu tí ó ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni Olúwa wí.
ובא לציון גואל ולשבי פשע ביעקב נאם יהוה׃
21 “Àti fún èmi, májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn nìyìí,” ni Olúwa wí, “Ẹ̀mí mi, tí ó wà nínú yín, àti ọ̀rọ̀ mi tí mo ti fi sí ẹnu yín, kì yóò kúrò lẹ́nu yín, tàbí lẹ́nu àwọn ọmọ yín, tàbí láti ẹnu àwọn ìrandíran wọn láti àkókò yìí lọ àti títí láéláé,” ni Olúwa wí.
ואני זאת בריתי אותם אמר יהוה רוחי אשר עליך ודברי אשר שמתי בפיך לא ימושו מפיך ומפי זרעך ומפי זרע זרעך אמר יהוה מעתה ועד עולם׃

< Isaiah 59 >