< Isaiah 58 >

1 “Kígbe rẹ̀ sókè, má ṣe fàsẹ́yìn. Gbé ohùn rẹ sókè bí i ti fèrè. Jẹ́ kí ó di mí mọ̀ fún àwọn ènìyàn mi, ọ̀tẹ̀ wọn, àti fún ilé Jakọbu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
ἀναβόησον ἐν ἰσχύι καὶ μὴ φείσῃ ὡς σάλπιγγα ὕψωσον τὴν φωνήν σου καὶ ἀνάγγειλον τῷ λαῷ μου τὰ ἁμαρτήματα αὐτῶν καὶ τῷ οἴκῳ Ιακωβ τὰς ἀνομίας αὐτῶν
2 Nítorí ọjọ́ dé ọjọ́ ni wọ́n ń wá mi kiri; wọ́n ṣe bí ẹni ní ìtara láti mọ ọ̀nà mi, àfi bí ẹni pé wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè kan tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà tí òun kò sì tí ì kọ àṣẹ Ọlọ́run rẹ̀. Wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ mi fún ìpinnu nìkan wọ́n sì ṣe bí ẹni ń tara fún Ọlọ́run láti súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn.
ἐμὲ ἡμέραν ἐξ ἡμέρας ζητοῦσιν καὶ γνῶναί μου τὰς ὁδοὺς ἐπιθυμοῦσιν ὡς λαὸς δικαιοσύνην πεποιηκὼς καὶ κρίσιν θεοῦ αὐτοῦ μὴ ἐγκαταλελοιπὼς αἰτοῦσίν με νῦν κρίσιν δικαίαν καὶ ἐγγίζειν θεῷ ἐπιθυμοῦσιν
3 Wọ́n wí pé, ‘Èéṣe tí àwa fi ń gbààwẹ̀, tí ìwọ kò sì tí ì rí? Èéṣe tí àwa fi rẹra wa sílẹ̀, tí ìwọ kò sì tí ì ṣe àkíyèsí?’ “Síbẹ̀síbẹ̀ ní ọjọ́ àwẹ̀ yín, ẹ̀yin ń ṣe bí ó ti wù yín ẹ sì ń pọ́n àwọn òṣìṣẹ́ yín gbogbo lójú.
λέγοντες τί ὅτι ἐνηστεύσαμεν καὶ οὐκ εἶδες ἐταπεινώσαμεν τὰς ψυχὰς ἡμῶν καὶ οὐκ ἔγνως ἐν γὰρ ταῖς ἡμέραις τῶν νηστειῶν ὑμῶν εὑρίσκετε τὰ θελήματα ὑμῶν καὶ πάντας τοὺς ὑποχειρίους ὑμῶν ὑπονύσσετε
4 Àwẹ̀ yín sì parí nínú ìjà àti asọ̀, àti lílu ọmọnìkejì ẹni pa pẹ̀lú ìkùùkuu. Ẹ̀yin kò le è gbààwẹ̀ bí ẹ ti ń ṣe lónìí kí ẹ sì retí kí a gbọ́ ohùn un yín ní ibi gíga.
εἰ εἰς κρίσεις καὶ μάχας νηστεύετε καὶ τύπτετε πυγμαῖς ταπεινόν ἵνα τί μοι νηστεύετε ὡς σήμερον ἀκουσθῆναι ἐν κραυγῇ τὴν φωνὴν ὑμῶν
5 Ǹjẹ́ èyí ha ni irú àwẹ̀ tí mo yàn bí, ọjọ́ kan ṣoṣo fún ènìyàn láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀? Ó ha jẹ pe kí ènìyàn tẹ orí rẹ̀ ba bí i koríko lásán ni bí àti sísùn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú? Ṣé ohun tí ẹ̀ ń pè ní àwẹ̀ nìyí, ọjọ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa?
οὐ ταύτην τὴν νηστείαν ἐξελεξάμην καὶ ἡμέραν ταπεινοῦν ἄνθρωπον τὴν ψυχὴν αὐτοῦ οὐδ’ ἂν κάμψῃς ὡς κρίκον τὸν τράχηλόν σου καὶ σάκκον καὶ σποδὸν ὑποστρώσῃ οὐδ’ οὕτως καλέσετε νηστείαν δεκτήν
6 “Ǹjẹ́ irú àwẹ̀ tí mo ti yàn kọ́ ni èyí: láti já gbogbo ẹ̀wọ̀n àìṣòdodo àti láti tú gbogbo okùn àjàgà, láti tú gbogbo àwọn ti à ń ni lára sílẹ̀ àti láti fọ́ gbogbo àjàgà?
οὐχὶ τοιαύτην νηστείαν ἐγὼ ἐξελεξάμην λέγει κύριος ἀλλὰ λῦε πάντα σύνδεσμον ἀδικίας διάλυε στραγγαλιὰς βιαίων συναλλαγμάτων ἀπόστελλε τεθραυσμένους ἐν ἀφέσει καὶ πᾶσαν συγγραφὴν ἄδικον διάσπα
7 Kì í ha á ṣe láti pín oúnjẹ yín fún àwọn tí ebi ń pa àti láti pèsè ibùgbé fún àwọn òtòṣì tí ń rìn káàkiri. Nígbà tí ẹ bá rí ẹni tí ó wà níhòhò, láti daṣọ bò ó, àti láti má ṣe lé àwọn ìbátan yín sẹ́yìn?
διάθρυπτε πεινῶντι τὸν ἄρτον σου καὶ πτωχοὺς ἀστέγους εἴσαγε εἰς τὸν οἶκόν σου ἐὰν ἴδῃς γυμνόν περίβαλε καὶ ἀπὸ τῶν οἰκείων τοῦ σπέρματός σου οὐχ ὑπερόψῃ
8 Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ rẹ yóò tàn jáde bí òwúrọ̀ àti ìmúláradá rẹ yóò farahàn kíákíá; nígbà náà ni òdodo rẹ yóò sì lọ níwájú rẹ, ògo Olúwa yóò sì jẹ́ ààbò lẹ́yìn rẹ.
τότε ῥαγήσεται πρόιμον τὸ φῶς σου καὶ τὰ ἰάματά σου ταχὺ ἀνατελεῖ καὶ προπορεύσεται ἔμπροσθέν σου ἡ δικαιοσύνη σου καὶ ἡ δόξα τοῦ θεοῦ περιστελεῖ σε
9 Nígbà yìí ni ẹ̀yin yóò pè, tí Olúwa yóò sì dáhùn; ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé, Èmi nìyí. “Bí ìwọ bá mú àjàgà aninilára, nínà ìka àlébù àti sísọ ọ̀rọ̀ asán kúrò láàrín rẹ,
τότε βοήσῃ καὶ ὁ θεὸς εἰσακούσεταί σου ἔτι λαλοῦντός σου ἐρεῖ ἰδοὺ πάρειμι ἐὰν ἀφέλῃς ἀπὸ σοῦ σύνδεσμον καὶ χειροτονίαν καὶ ῥῆμα γογγυσμοῦ
10 àti bí ẹ̀yin bá ná ara yín bí owó nítorí àwọn tí ebi ń pa tí ẹ sì tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí à ń ni lára lọ́rùn, nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóò ràn nínú òkùnkùn, àti òru yín yóò dàbí ọ̀sán gangan.
καὶ δῷς πεινῶντι τὸν ἄρτον ἐκ ψυχῆς σου καὶ ψυχὴν τεταπεινωμένην ἐμπλήσῃς τότε ἀνατελεῖ ἐν τῷ σκότει τὸ φῶς σου καὶ τὸ σκότος σου ὡς μεσημβρία
11 Olúwa yóò máa tọ́ ọ yín nígbà gbogbo; òun yóò tẹ́ gbogbo àìní yín lọ́rùn ní ilẹ̀ tí oòrùn ń tan ìmọ́lẹ̀ yóò sì fún egungun rẹ lókun. Ìwọ yóò sì dàbí ọgbà tí a bomirin dáradára, àti bí orísun tí omi rẹ̀ kì í gbẹ.
καὶ ἔσται ὁ θεός σου μετὰ σοῦ διὰ παντός καὶ ἐμπλησθήσῃ καθάπερ ἐπιθυμεῖ ἡ ψυχή σου καὶ τὰ ὀστᾶ σου πιανθήσεται καὶ ἔσῃ ὡς κῆπος μεθύων καὶ ὡς πηγὴ ἣν μὴ ἐξέλιπεν ὕδωρ καὶ τὰ ὀστᾶ σου ὡς βοτάνη ἀνατελεῖ καὶ πιανθήσεται καὶ κληρονομήσουσι γενεὰς γενεῶν
12 Àwọn ènìyàn rẹ yóò tún ahoro àtijọ́ kọ́ wọn yóò sì gbé ìpìlẹ̀ àtijọ́-tijọ́ ró a ó sì pè ọ́ ní alátúnṣe ògiri tí ó ti wó àti olùmúbọ̀sípò àwọn òpópónà tí ènìyàn gbé inú rẹ̀.
καὶ οἰκοδομηθήσονταί σου αἱ ἔρημοι αἰώνιοι καὶ ἔσται σου τὰ θεμέλια αἰώνια γενεῶν γενεαῖς καὶ κληθήσῃ οἰκοδόμος φραγμῶν καὶ τοὺς τρίβους τοὺς ἀνὰ μέσον παύσεις
13 “Bí ìwọ bá pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú bíba ọjọ́ ìsinmi jẹ́, àti ṣíṣe bí ó ti wù ọ́ ni ọjọ́ mímọ́ mi, bí ìwọ bá pe ọjọ́ ìsinmi ní ohun dídùn àti ọjọ́ mímọ́ Olúwa ní ohun ọ̀wọ̀ àti bí ìwọ bá bu ọlá fún un láti máa bá ọ̀nà tìrẹ lọ àti láti má ṣe bí ó ti wù ọ́ tàbí kí o máa sọ̀rọ̀ aláìníláárí,
ἐὰν ἀποστρέψῃς τὸν πόδα σου ἀπὸ τῶν σαββάτων τοῦ μὴ ποιεῖν τὰ θελήματά σου ἐν τῇ ἡμέρᾳ τῇ ἁγίᾳ καὶ καλέσεις τὰ σάββατα τρυφερά ἅγια τῷ θεῷ σου οὐκ ἀρεῖς τὸν πόδα σου ἐπ’ ἔργῳ οὐδὲ λαλήσεις λόγον ἐν ὀργῇ ἐκ τοῦ στόματός σου
14 nígbà náà ni ìwọ yóò ní ayọ̀ nínú Olúwa rẹ, èmi yóò sì jẹ́ kí ìwọ kí ó máa gun ibi gíga ilẹ̀ ayé, àti láti máa jàdídùn ìní ti Jakọbu baba rẹ.” Ẹnu Olúwa ni ó ti sọ̀rọ̀.
καὶ ἔσῃ πεποιθὼς ἐπὶ κύριον καὶ ἀναβιβάσει σε ἐπὶ τὰ ἀγαθὰ τῆς γῆς καὶ ψωμιεῖ σε τὴν κληρονομίαν Ιακωβ τοῦ πατρός σου τὸ γὰρ στόμα κυρίου ἐλάλησεν ταῦτα

< Isaiah 58 >