< Isaiah 56 >
1 Èyí ni ohun ti Olúwa sọ: “Ẹ pa ìdájọ́ mọ́ ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ̀nà, nítorí ìgbàlà mi súnmọ́ tòsí àti òdodo mi ni a ó fihàn láìpẹ́ jọjọ.
Thus saith the Lord: Keep ye judgment, and do justice: for my salvation is near to come, and my justice to be revealed.
2 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣe èyí, àti fún ọmọ ènìyàn tí ó dìímú ṣinṣin, tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́, tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi ṣíṣe.”
Blessed is the man that doth this, and the son of man that shall lay hold on this: that keepeth the sabbath from profaning it, that keepeth his hands from doing any evil.
3 Má ṣe jẹ́ kí àjèjì kan tí ó ti di ara rẹ̀ mọ́ Olúwa sọ wí pé, “Olúwa yóò yà mí sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.” Àti kí ìwẹ̀fà kan ṣe àròyé pé, “Igi gbígbẹ lásán ni mí.”
And let not the son of the stranger, that adhereth to the Lord, speak, saying: The Lord will divide and separate me from his people. And let not the eunuch say: Behold I am a dry tree.
4 Nítorí pé báyìí ni Olúwa wí: “Sí àwọn ìwẹ̀fà yìí tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, tí wọ́n yan ohun tí ó dùn mọ́ mi tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin
For thus saith the Lord to the eunuchs, They that shall keep my sabbaths, and shall choose the things that please me, and shall hold fast my covenant:
5 fún wọn ni Èmi yóò fún nínú tẹmpili àti àgbàlá rẹ̀ ìrántí kan àti orúkọ kan tí ó sàn ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin, Èmi yóò fún wọn ní orúkọ ayérayé tí a kì yóò ké kúrò.
I will give to them in my house, and within my walls, a place, and a name better than sons and daughters: I will give them an everlasting name which shall never perish.
6 Àti àwọn àjèjì tí ó so ara wọn mọ́ Olúwa láti sìn ín, láti fẹ́ orúkọ Olúwa àti láti foríbalẹ̀ fún un gbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́ àti tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin—
And the children of the stranger that adhere to the Lord, to worship him, and to love his name, to be his servants: every one that keepeth the sabbath from profaning it, and that holdeth fast my covenant:
7 àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mi, èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi. Ẹbọ sísun wọn àti ìrúbọ wọn, ni a ó tẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi; nítorí a ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀-èdè.”
I will bring them into my holy mount, and will make them joyful in my house of prayer: their holocausts, and their victims shall please me upon my altar: for my house shall be called the house of prayer, for all nations.
8 Olúwa Olódùmarè sọ wí pé— ẹni tí ó kó àwọn àtìpó Israẹli jọ: “Èmi yóò kó àwọn mìíràn jọ pẹ̀lú wọn yàtọ̀ sí àwọn tí a ti kójọ.”
The Lord God, who gathereth the scattered of Israel, saith: I will still gather unto him his congregation.
9 Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú pápá, ẹ wá jẹ àwọn ẹranko inú igbó run!
All ye beasts of the field come to devour, all ye beasts of the forest.
10 Àwọn olùṣọ́ Israẹli fọ́jú, gbogbo wọn ṣe aláìní ìmọ̀; gbogbo wọn jẹ́ adití ajá, wọn kò lè gbó; wọ́n sùn sílẹ̀ wọ́n ń lálàá, wọ́n fẹ́ràn láti máa sùn.
His watchmen are all blind, they are all ignorant: dumb dogs not able to bark, seeing vain things, sleeping and loving dreams.
11 Wọ́n jẹ́ àwọn ajá tí ó kúndùn púpọ̀; wọn kì í ní ànító. Wọ́n jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn tí kò ní òye; olúkúlùkù ń yà ṣọ́nà ara rẹ̀, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sì wá ère tirẹ̀.
And meet impudent dogs, they never had enough: the shepherds themselves knew no understanding: all have turned aside into their own way, every one after his own gain, from the first even to the last.
12 Igbe ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ni wí pé, “Wá, fún mi ní ọtí wáìnì! Jẹ́ kí a mu ọtí líle wa lámu yó ọ̀la yóò sì dàbí òní, tàbí kí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ.”
Come, let us take wine, and be filled with drunkenness: and it shall be as today, so also tomorrow, and much more.