< Isaiah 51 >
1 “Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ó ń lépa òdodo àti ẹ̀yin tí ń wá Olúwa. Wo àpáta, nínú èyí tí a ti gé yín jáde àti ihò òkúta níbi tí a ti gbẹ́ yín jáde;
2 ẹ wo Abrahamu baba yín, àti Sara, ẹni tó bí i yín. Nígbà tí mo pè é, òun nìkan ni, Èmi sì bùkún un, mo sì ṣọ́ ọ di ọ̀pọ̀lọpọ̀.
3 Dájúdájú, Olúwa yóò tu Sioni nínú yóò sì bojú àánú wo gbogbo ahoro rẹ̀; Òun yóò sọ gbogbo aṣálẹ̀ rẹ̀ di Edeni, àti aṣálẹ̀ rẹ̀ yóò rí bí ọgbà Olúwa. Ayọ̀ àti inú dídùn ni a ó rí nínú rẹ̀, ọpẹ́ àti ariwo orín kíkọ.
4 “Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ènìyàn mi; gbọ́ tèmi, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè mi. Òfin yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde wá; ìdájọ́ mi yóò di ìmọ́lẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè.
5 Òdodo mi ń bọ̀ wá kíkankíkan, ìgbàlà mi ń bọ̀ lójú ọ̀nà, àti apá mi yóò sì mú ìdájọ́ wá sí àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn erékùṣù yóò wò mí wọn yóò sì dúró ní ìrètí fún apá mi.
6 Gbé ojú rẹ sókè sí àwọn ọ̀run, wo ilẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀; àwọn ọ̀run yóò pòórá bí èéfín, ilẹ̀ yóò sì gbó bí ẹ̀wù àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò kú gẹ́gẹ́ bí àwọn eṣinṣin. Ṣùgbọ́n ìgbàlà mi yóò wà títí láé, òdodo mi kì yóò yẹ̀ láé.
7 “Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin tí ó mọ ohun òtítọ́, ẹ̀yin ènìyàn tí ó ní òfin mi ní àyà yín. Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn ènìyàn tàbí kí ẹ̀rù èébú wọn já a yín láyà.
8 Nítorí kòkòrò yóò mú wọn lá bí aṣọ, ìdin yóò sì mú wọn jẹ bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ṣùgbọ́n òdodo mi yóò wà títí ayérayé, àti ìgbàlà mi láti ìrandíran.”
9 Dìde, dìde! Kí o sì wọ ara rẹ ní agbára ìwọ apá Olúwa; dìde gẹ́gẹ́ bí i ti ọjọ́ ìgbà n nì, àti gẹ́gẹ́ bí i ti ìran àtijọ́. Ìwọ kọ́ lo ké Rahabu sí wẹ́wẹ́ tí o sì fa ẹ̀mí búburú ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ?
10 Ìwọ kọ́ ni ó gbẹ omi Òkun bí àti àwọn omi inú ọ̀gbun, tí o sì ṣe ọ̀nà nínú ìsàlẹ̀ Òkun tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹni ìràpadà yóò fi le là á kọjá?
11 Àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá. Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin kíkọ; ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo orí wọn. Ayọ̀ àti inú dídùn yóò sì bà lé wọn ìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò.
12 “Èmi, àní Èmi, èmi ni ẹni tí ó tù ọ́ nínú. Ta ni ọ́ tí o fi ń bẹ̀rù ènìyàn ẹlẹ́ran ara, àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ koríko lásán,
13 tí ìwọ sì gbàgbé Olúwa ẹlẹ́dàá rẹ, ẹni tí ó ta àwọn ọ̀run tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, tí ẹ sì ń gbé nínú ìpayà lójoojúmọ́ nítorí ìbínú àwọn aninilára, tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀lé ìpanirun? Nítorí ibo ni ìbínú àwọn aninilára gbé wà?
14 Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ń ṣojo la ó dá sílẹ̀ ní àìpẹ́ jọjọ wọn kò ní kú sínú túbú wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ṣe aláìní àkàrà.
15 Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó ń ru Òkun sókè tó bẹ́ẹ̀ tí ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.
16 Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ mo sì ti fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́, Èmi tí mo tẹ́ àwọn ọ̀run sí ààyè rẹ̀, ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀, àti ẹni tí ó sọ fún Sioni pé, ‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi.’”
17 Jí, jí! Gbéra nílẹ̀ ìwọ Jerusalẹmu, ìwọ tí o ti mu láti ọwọ́ Olúwa ago ìbínú rẹ̀, ìwọ tí o ti fà á mu dé gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ tí ó n mú kí ènìyàn ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n.
18 Nínú gbogbo ọmọ tí ó bí kò sí ọ̀kankan tí ó lè tọ́ ọ ṣọ́nà nínú gbogbo ọmọ tí ó tọ́ kò sí èyí tí ó le fà á lọ́wọ́.
19 Àjálù ìlọ́po ìlọ́po yìí ti dé bá ọ— ta ni yóò tù ọ́ nínú? Ìparun àti ìdahoro, ìyàn àti idà ta ni yó pẹ̀tù sí ọ lọ́kàn?
20 Àwọn ọmọkùnrin rẹ ti dákú; wọ́n sùn sí oríta gbogbo òpópónà, gẹ́gẹ́ bí etu tí a dé mọ́nú àwọ̀n. Ìbínú Olúwa ti kún inú wọn fọ́fọ́ àti ìbáwí Ọlọ́run yín.
21 Nítorí náà ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí a ti ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́, tí ọtí ń pa, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wáìnì.
22 Ohun tí Olúwa Olódùmarè yín wí nìyìí, Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ń pa ènìyàn rẹ̀ mọ́, “Kíyèsi i, mo ti mú un kúrò ní ọwọ́ rẹ ago tí ó mú ọ ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n; láti inú ago náà, ẹ̀kún ìbínú mi, ni ìwọ kì yóò mu mọ́.
23 Èmi yóò fi lé àwọn apọ́nilójú rẹ lọ́wọ́, àwọn tí ó wí fún ọ pé, ‘Dọ̀bálẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí a ó fi máa rìn lórí rẹ.’ Ìwọ náà ṣe ẹ̀yìn rẹ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òpópónà láti máa rìn lórí i rẹ̀.”