< Isaiah 50 >
1 Ohun tí Olúwa wí nìyìí: “Níbo ni ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ ìyá rẹ wà èyí tí mo fi lé e lọ? Tàbí èwo nínú àwọn olùyánilówó mi ni mo tà ọ́ fún? Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ni a fi tà ọ́; nítorí àìṣedéédéé rẹ ni a fi lé ìyá rẹ lọ.
This is what the LORD says: “Where is your mother’s certificate of divorce with which I sent her away? Or to which of My creditors did I sell you? Look, you were sold for your iniquities, and for your transgressions your mother was sent away.
2 Nígbà tí mo wá, èéṣe tí a kò fi rí ẹnìkan? Nígbà tí mo pè, èéṣe tí kò fi sí ẹnìkan láti dáhùn? Ọwọ́ mi a kúrú láti gbà ọ́? Èmi kò ha ní agbára láti gbà ọ́ bí? Nípa ìbáwí lásán, Èmi gbẹ omi òkun, Èmi yí àwọn odò sí aṣálẹ̀; àwọn ẹja wọn rà fún àìsí omi wọ́n sì kú fún òǹgbẹ.
Why was no one there when I arrived? Why did no one answer when I called? Is My hand too short to redeem you? Or do I lack the strength to deliver you? Behold, My rebuke dries up the sea; I turn the rivers into a desert; the fish rot for lack of water and die of thirst.
3 Èmi fi òkùnkùn bo sánmọ̀ mo sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ ṣe ìbòrí rẹ̀.”
I clothe the heavens in black and make sackcloth their covering.”
4 Olúwa Olódùmarè ti fún mi ni ahọ́n tí a fi iṣẹ́ rán, láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé àwọn aláàárẹ̀ ró. O jí mi láràárọ̀, o jí etí mi láti gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí à ń kọ́.
The Lord GOD has given Me the tongue of discipleship, to sustain the weary with a word. He awakens Me morning by morning; He awakens My ear to listen as a disciple.
5 Olúwa Olódùmarè ti ṣí mi ní etí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ṣọ̀tẹ̀ rí; Èmi kò sì padà sẹ́yìn.
The Lord GOD has opened My ears, and I have not been rebellious, nor have I turned back.
6 Mo ṣí ẹ̀yìn mi sílẹ̀ fún àwọn tí ó ń nà mí, àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ń fa irùngbọ̀n mi; Èmi kò fi ojú mi pamọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́yà àti ìyọṣùtì sí.
I offered My back to those who struck Me, and My cheeks to those who tore out My beard. I did not hide My face from scorn and spittle.
7 Nítorí Olúwa Olódùmarè ràn mí lọ́wọ́, a kì yóò dójútì mí. Nítorí náà ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí òkúta akọ èmi sì mọ pé, ojú kò ní tì mí.
Because the Lord GOD helps Me, I have not been disgraced; therefore I have set My face like flint, and I know that I will not be put to shame.
8 Ẹni tí ó dá mi láre wà nítòsí. Ta ni ẹni náà tí yóò fẹ̀sùn kàn mí? Jẹ́ kí a kojú ara wa! Ta ni olùfisùn mi? Jẹ́ kí ó kò mí lójú!
The One who vindicates Me is near. Who will dare to contend with Me? Let us confront each other! Who has a case against Me? Let him approach Me!
9 Olúwa Olódùmarè ni ó ń ràn mí lọ́wọ́. Ta ni ẹni náà tí yóò dá mi lẹ́bi? Gbogbo wọn yóò gbó bí aṣọ; kòkòrò ni yóò sì jẹ wọn run.
Surely the Lord GOD helps Me. Who is there to condemn Me? See, they will all wear out like a garment; the moths will devour them.
10 Ta ni nínú yín tí ó bẹ̀rù Olúwa tí ó sì ń gbọ́rọ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nu? Jẹ́ kí ẹni tí ń rìn ní òkùnkùn tí kò ní ìmọ́lẹ̀, kí ó gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa kí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run rẹ̀.
Who among you fears the LORD and obeys the voice of His Servant? Who among you walks in darkness and has no light? Let him trust in the name of the LORD; let him lean on his God.
11 Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gbogbo ẹ̀yin ti ń tanná tí ẹ sì ń fi pèsè iná ìléwọ́ fún ara yín, ẹ lọ, kí ẹ sì máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yín, àti nínú ẹta iná tí ẹ ti dá. Èyí ni yóò jẹ́ tiyín láti ọwọ́ mi wá. Ẹ̀yin ó dùbúlẹ̀ nínú ìrora.
Behold, all you who kindle a fire, who array yourselves with firebrands, walk in the light of your fire and of the firebrands you have lit! This is what you will receive from My hand: You will lie down in a place of torment.