< Isaiah 49 >

1 Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin erékùṣù: gbọ́ èyí, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè jíjìnnà réré: kí a tó bí mi Olúwa ti pè mí; láti ìgbà bíbí mi ni ó ti dá orúkọ mi.
שמעו איים אלי והקשיבו לאמים מרחוק יהוה מבטן קראני ממעי אמי הזכיר שמי׃
2 Ó ṣe ẹnu mi bí idà tí a pọ́n, ní abẹ́ òjìji ọwọ́ rẹ̀ ni ó ti pa mí mọ́: ó ṣe mí ní ọfà tí a ti dán, ó sì fi mí pamọ́ sínú àpò rẹ̀.
וישם פי כחרב חדה בצל ידו החביאני וישימני לחץ ברור באשפתו הסתירני׃
3 Ó sọ fún mi pé, “Ìránṣẹ́ mi ni ìwọ í ṣe, Israẹli nínú ẹni tí n ó ti fi ògo mi hàn.”
ויאמר לי עבדי אתה ישראל אשר בך אתפאר׃
4 Ṣùgbọ́n èmi sọ pé, “Mo ti ṣe wàhálà lórí asán; mo ti lo gbogbo ipá mi lórí asán àti ìmúlẹ̀mófo. Síbẹ̀síbẹ̀ ohun tí ó tọ́ sí mi ṣì wà lọ́wọ́ Olúwa, èrè mi sì ń bẹ pẹ̀lú Ọlọ́run mi.”
ואני אמרתי לריק יגעתי לתהו והבל כחי כליתי אכן משפטי את יהוה ופעלתי את אלהי׃
5 Nísinsin yìí Olúwa wí pé ẹni tí ó mọ̀ mí láti inú wá láti jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ láti mú Jakọbu padà tọ̀ mí wá àti láti kó Israẹli jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, nítorí pé a bọ̀wọ̀ fún mi ní ojú Olúwa Ọlọ́run mi sì ti jẹ́ agbára mi,
ועתה אמר יהוה יצרי מבטן לעבד לו לשובב יעקב אליו וישראל לא יאסף ואכבד בעיני יהוה ואלהי היה עזי׃
6 Òun wí pé: “Ó jẹ́ ohun kékeré fún ọ láti jẹ́ ìránṣẹ́ mi láti mú ẹ̀yà Jakọbu padà bọ̀ sípò àti láti mú àwọn ti Israẹli tí mo ti pamọ́. Èmi yóò sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn kèfèrí, kí ìwọ kí ó lè mú ìgbàlà mi wá sí òpin ilẹ̀ ayé.”
ויאמר נקל מהיותך לי עבד להקים את שבטי יעקב ונצירי ישראל להשיב ונתתיך לאור גוים להיות ישועתי עד קצה הארץ׃
7 Ohun tí Olúwa wí nìyìí, Olùdáǹdè àti Ẹni Mímọ́ Israẹli— sí ẹni náà tí a gàn tí a sì kórìíra lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, sí ìránṣẹ́ àwọn aláṣẹ: “Àwọn ọba yóò rí ọ wọn yóò sì dìde sókè, àwọn ọmọ ọba yóò rí i wọn yóò sì wólẹ̀, nítorí Olúwa ẹni tí í ṣe olóòtítọ́, Ẹni Mímọ́ Israẹli tí ó ti yàn ọ́.”
כה אמר יהוה גאל ישראל קדושו לבזה נפש למתעב גוי לעבד משלים מלכים יראו וקמו שרים וישתחוו למען יהוה אשר נאמן קדש ישראל ויבחרך׃
8 Ohun tí Olúwa wí nìyìí: “Ní àkókò ojúrere mi, èmi yóò dá ọ lóhùn, àti ní ọjọ́ ìgbàlà, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́; Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́ láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn, láti mú ilẹ̀ padà bọ̀ sípò àti láti ṣe àtúnpín ogún rẹ̀ tí ó ti dahoro,
כה אמר יהוה בעת רצון עניתיך וביום ישועה עזרתיך ואצרך ואתנך לברית עם להקים ארץ להנחיל נחלות שממות׃
9 láti sọ fún àwọn ìgbèkùn pé, ‘Ẹ jáde wá,’ àti fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn pé, ‘Ẹ gba òmìnira!’ “Wọn yóò máa jẹ ní ẹ̀bá ọ̀nà àti koríko tútù lórí òkè aláìléwéko.
לאמר לאסורים צאו לאשר בחשך הגלו על דרכים ירעו ובכל שפיים מרעיתם׃
10 Ebi kì yóò pa wọ́n bẹ́ẹ̀ ni òǹgbẹ kì yóò gbẹ wọ́n, tàbí kí ooru inú aṣálẹ̀ tàbí oòrùn kí ó pa wọ́n. Ẹni tí ó ṣàánú fún wọn ni yóò máa tọ́ wọn, tí yóò sì mú wọn lọ sí ibi orísun omi.
לא ירעבו ולא יצמאו ולא יכם שרב ושמש כי מרחמם ינהגם ועל מבועי מים ינהלם׃
11 Èmi yóò sọ gbogbo àwọn òkè ńlá mi di ojú ọ̀nà àti gbogbo òpópónà mi ni a ó gbé sókè.
ושמתי כל הרי לדרך ומסלתי ירמון׃
12 Kíyèsi i, wọn yóò wá láti ọ̀nà jíjìn àwọn díẹ̀ láti àríwá àti àwọn díẹ̀ láti ìwọ̀-oòrùn, àwọn díẹ̀ láti ẹkùn Siene.”
הנה אלה מרחוק יבאו והנה אלה מצפון ומים ואלה מארץ סינים׃
13 Ẹ hó fún ayọ̀, ẹyin ọ̀run; yọ̀, ìwọ ilẹ̀ ayé; bú sórin, ẹ̀yin òkè ńlá! Nítorí Olúwa tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú yóò sì ṣàánú fún àwọn ẹni tí a ń pọ́n lójú.
רנו שמים וגילי ארץ יפצחו הרים רנה כי נחם יהוה עמו ועניו ירחם׃
14 Ṣùgbọ́n Sioni sọ pé, “Olúwa ti kọ̀ mí sílẹ̀, Olúwa ti gbàgbé è mi.”
ותאמר ציון עזבני יהוה ואדני שכחני׃
15 “Ǹjẹ́ abiyamọ ha le gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀ kí ó má sì ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ó ti bí? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun le gbàgbé, Èmi kì yóò gbàgbé rẹ!
התשכח אשה עולה מרחם בן בטנה גם אלה תשכחנה ואנכי לא אשכחך׃
16 Kíyèsi i, mo ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ mi ògiri rẹ wà níwájú mi nígbà gbogbo.
הן על כפים חקתיך חומתיך נגדי תמיד׃
17 Àwọn ọmọ rẹ ti kánjú padà, àti àwọn tí ó sọ ọ́ dahoro ti padà lẹ́yìn rẹ.
מהרו בניך מהרסיך ומחרביך ממך יצאו׃
18 Gbójú rẹ sókè kí o sì wò yíká; gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ kórajọ wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ. Níwọ́n ìgbà tí mo bá wà láààyè,” ni Olúwa wí, “Ìwọ yóò wọ gbogbo wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀ṣọ́; ìwọ yóò wọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ìyàwó.
שאי סביב עיניך וראי כלם נקבצו באו לך חי אני נאם יהוה כי כלם כעדי תלבשי ותקשרים ככלה׃
19 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí run ọ́, a sì sọ ọ́ di ahoro tí gbogbo ilẹ̀ rẹ sì di ìparun, ní ìsinsin yìí, ìwọ yóò kéré jù fún àwọn ènìyàn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ó jẹ ọ́ run ni yóò wà láti ọ̀nà jíjìn réré.
כי חרבתיך ושממתיך וארץ הרסתיך כי עתה תצרי מיושב ורחקו מבלעיך׃
20 Àwọn ọmọ tí a bí ní àkókò ọ̀fọ̀ rẹ yóò sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ, ‘Ibi yìí ti kéré jù fún wa; ẹ fún wa láyè sí i tí a ó máa gbé.’
עוד יאמרו באזניך בני שכליך צר לי המקום גשה לי ואשבה׃
21 Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní ọkàn rẹ pé, ‘Ta ló bí àwọn yìí fún mi? Mo ti ṣọ̀fọ̀ mo sì yàgàn; a sọ mi di àtìpó a sì kọ̀ mí sílẹ̀. Ta ló wo àwọn yìí dàgbà? A fi èmi nìkan sílẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí níbo ni wọ́n ti wá?’”
ואמרת בלבבך מי ילד לי את אלה ואני שכולה וגלמודה גלה וסורה ואלה מי גדל הן אני נשארתי לבדי אלה איפה הם׃
22 Ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nìyìí, “Kíyèsi i, Èmi yóò ké sí àwọn aláìkọlà, Èmi yóò gbé àsíá mi sókè sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn; wọn yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín wá ní apá wọn wọn yóò sì gbé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ní èjìká wọn.
כה אמר אדני יהוה הנה אשא אל גוים ידי ואל עמים ארים נסי והביאו בניך בחצן ובנתיך על כתף תנשאנה׃
23 Àwọn ọba ni yóò jẹ́ alágbàtọ́ baba fún ọ, àwọn ayaba wọn ni yóò sì jẹ́ ìyá-alágbàtọ́. Wọn yóò foríbalẹ̀ ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ojú wọn dídàbolẹ̀; wọn yóò máa lá erùpẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa; gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìrètí nínú mi ni a kì yóò jákulẹ̀.”
והיו מלכים אמניך ושרותיהם מיניקתיך אפים ארץ ישתחוו לך ועפר רגליך ילחכו וידעת כי אני יהוה אשר לא יבשו קוי׃
24 Ǹjẹ́ a le gba ìkógun lọ́wọ́ jagunjagun, tàbí kí á gba ìgbèkùn lọ́wọ́ akíkanjú?
היקח מגבור מלקוח ואם שבי צדיק ימלט׃
25 Ṣùgbọ́n ohun tí Olúwa wí nìyìí: “Bẹ́ẹ̀ ni, a ó gba àwọn ìgbèkùn lọ́wọ́ àwọn jagunjagun, àti ìkógun lọ́wọ́ àwọn akíkanjú; ẹni tí ó bá ọ jà ni èmi ó bá jà, àti àwọn ọmọ rẹ ni èmi ó gbàlà.
כי כה אמר יהוה גם שבי גבור יקח ומלקוח עריץ ימלט ואת יריבך אנכי אריב ואת בניך אנכי אושיע׃
26 Èmi yóò mú kí àwọn aninilára rẹ̀ jẹ ẹran-ara wọn; wọn yóò mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn yó bí ẹni mu wáìnì. Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn yóò mọ̀ pé, Èmi, Olúwa, èmi ni Olùgbàlà rẹ, Olùdáǹdè rẹ, Alágbára kan ṣoṣo ti Jakọbu.”
והאכלתי את מוניך את בשרם וכעסיס דמם ישכרון וידעו כל בשר כי אני יהוה מושיעך וגאלך אביר יעקב׃

< Isaiah 49 >