< Isaiah 47 >
1 “Sọ̀kalẹ̀, jókòó nínú eruku, wúńdíá ọmọbìnrin Babeli; jókòó ní ilẹ̀ láìsí ìtẹ́, ọmọbìnrin àwọn ará Babeli. A kì yóò pè ọ́ ní aláìlókun àti ẹlẹgẹ́ mọ́.
2 Mú òkúta-ọlọ kí o sì lọ ìyẹ̀fun; mú ìbòjú rẹ kúrò. Ká aṣọ ẹsẹ̀ rẹ sókè, ká aṣọ itan, kí o sì la odò wọ̀n-ọn-nì kọjá.
3 Ìhòhò rẹ ni a ó sí síta àti ìtìjú rẹ ni a ó ṣí sílẹ̀. Èmi yóò sì gba ẹ̀san, Èmi kì yóò sì dá ẹnìkan sí.”
4 Olùràpadà wa Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ òun ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.
5 “Jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, lọ sínú òkùnkùn, ọmọbìnrin àwọn ará Babeli; a kì yóò pè ọ́ ní ọbabìnrin àwọn ilẹ̀ ọba mọ́.
6 Inú bí mi sí àwọn ènìyàn mi tí mo sì ba ogún mi jẹ́, mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́, Ìwọ kò sì síjú àánú wò wọ́n. Lórí àwọn arúgbó pẹ̀lú ní o gbé àjàgà tí ó wúwo lé.
7 Ìwọ wí pé, ‘Èmi yóò tẹ̀síwájú títí láé— ọbabìnrin ayérayé!’ Ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi nǹkan wọ̀nyí tàbí kí o ronú nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀.
8 “Nísinsin yìí, tẹ́tí sílẹ̀, ìwọ oníwọ̀ra ẹ̀dá tí o kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ nínú ààbò rẹ tí o sì ń sọ fún ara rẹ pé, ‘Èmi ni, kò sì ṣí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi. Èmi kì yóò di opó tàbí kí n pàdánù àwọn ọmọ.’
9 Méjèèjì yìí ni yóò wá sórí rẹ láìpẹ́ jọjọ, ní ọjọ́ kan náà: pípàdánù ọmọ àti dídi opó. Wọn yóò wá sórí rẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìṣe oṣó rẹ àti àwọn èpè rẹ tí ko lágbára.
10 Ìwọ ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìwà ìkà rẹ ó sì ti wí pé, ‘Kò sí ẹni tí ó rí mi?’ Ọgbọ́n àti òye rẹ ti ṣì ọ́ lọ́nà nígbà tí o wí fún ara rẹ pé, ‘Èmi ni, kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.’
11 Ìparun yóò dé bá ọ bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò mọ ọ̀nà láti ré e kúrò. Àjálù kan yóò ṣubú lù ọ́ tí o kì yóò le è fi ètùtù ré kúrò; òfò kan tí o kò le faradà ni yóò wá lójijì sí oríì rẹ.
12 “Tẹ̀síwájú nígbà náà, pẹ̀lú àfọ̀ṣẹ rẹ àti pẹ̀lú ìwà oṣó rẹ gbogbo, tí o ti ń ṣiṣẹ́ fún láti ìgbà èwe rẹ wá. Bóyá o le è ṣàṣeyọrí, bóyá o le è dá rúgúdù sílẹ̀.
13 Gbogbo ìmọ̀ràn tí o ti gbà ni ó ti sọ ọ́ di akúrẹtẹ̀! Jẹ́ kí àwọn awòràwọ̀ rẹ bọ́ síwájú, àwọn awòràwọ̀ tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ láti oṣù dé oṣù, jẹ́ kí wọ́n gbà ọ́ lọ́wọ́ ohun tí ó ń bọ̀ wá bá ọ.
14 Lóòótọ́ wọ́n dàbí ìṣẹ́pẹ́ igi; iná ni yóò jó wọn dànù. Wọn kò kúkú lè gba ara wọn là lọ́wọ́ agbára iná náà. Kò sí èédú láti mú ara ẹnikẹ́ni gbóná níhìn-ín kò sí iná tí ènìyàn le jókòó tì.
15 Gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe fún ọ nìyìí gbogbo èyí ní o tí ṣíṣẹ́ pẹ̀lú u rẹ̀ tí o sì ti ń rù kiri láti ìgbà èwe. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń lọ nínú àṣìṣe rẹ̀; kò sí ẹyọ ẹnìkan tí ó lè gbà ọ́.