< Isaiah 45 >
1 “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún ẹni òróró rẹ̀, sí Kirusi, ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí mo dì mú láti dojú àwọn orílẹ̀-èdè bolẹ̀ níwájú rẹ̀ àti láti gba ohun ìjà àwọn ọba lọ́wọ́ wọn, láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé a kì yóò ti àwọn ẹnu-ọ̀nà.
Hæc dicit Dominus christo meo Cyro, cuius apprehendi dexteram, ut subiiciam ante faciem eius Gentes, et dorsa regum vertam, et aperiam coram eo ianuas, et portæ non claudentur.
2 Èmi yóò lọ síwájú rẹ, Èmi ó sì tẹ́ àwọn òkè ńlá pẹrẹsẹ Èmi yóò fọ gbogbo ẹnu-ọ̀nà idẹ èmi ó sì gé ọ̀pá irin.
Ego ante te ibo: et gloriosos terræ humiliabo: portas æreas conteram, et vectes ferreos confringam.
3 Èmi yóò sì fún ọ ní àwọn ọrọ̀ ibi òkùnkùn, ọrọ̀ tí a kó pamọ́ sí àwọn ibi tí ó fi ara sin, tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ yóò fi mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ.
Et dabo tibi thesauros absconditos, et arcana secretorum: ut scias quia ego Dominus, qui voco nomen tuum, Deus Israel.
4 Nítorí Jakọbu ìránṣẹ́ mi àti Israẹli ẹni tí mo yàn, Mo pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ, mo sì gbé oyè kan kà ọ́ lórí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò gbà mí.
Propter servum meum Iacob, et Israel electum meum, et vocavi te nomine tuo: assimilavi te, et non cognovisti me.
5 Èmi ni Olúwa, àti pé kò sí ẹlòmíràn; yàtọ̀ sí èmi kò sí ọlọ́run kan, Èmi yóò fún ọ ní okun, bí o kò tilẹ̀ tí ì gbà mí,
Ego Dominus, et non est amplius: extra me non est deus: accinxi te, et non cognovisti me:
6 tí o fi jẹ́ pé láti ìlà-oòrùn títí dé ibi ìwọ̀ rẹ̀ kí ènìyàn le mọ̀, kò sí ẹnìkan lẹ́yìn mi. Èmi ni Olúwa, lẹ́yìn mi kò sí ẹlòmíràn mọ́.
Ut sciant hi, qui ab ortu solis, et qui ab occidente, quoniam absque me non est: ego Dominus, et non est alter,
7 Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn, Mo mú àlàáfíà wá, Mo sì dá àjálù; Èmi Olúwa ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí.
formans lucem, et creans tenebras, faciens pacem, et creans malum: ego Dominus faciens omnia hæc.
8 “Ìwọ ọ̀run lókè rọ òjò òdodo sílẹ̀; jẹ́ kí àwọsánmọ̀ kí ó rọ̀ ọ́ sílẹ̀. Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó yanu gbagada, jẹ́ kí ìgbàlà kí ó dìde sókè, jẹ́ kí òdodo kí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀; Èmi Olúwa ni ó ti dá a.
Rorate cæli desuper, et nubes pluant iustum: aperiatur terra, et germinet salvatorem: et iustitia oriatur simul: ego Dominus creavi eum.
9 “Ègbé ni fún ènìyàn tí ó ń bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà, ẹni tí òun jẹ́ àpáàdì kan láàrín àwọn àpáàdì tí ó wà lórí ilẹ̀. Ǹjẹ́ amọ̀ lè sọ fún amọ̀kòkò, pé: ‘Kí ni ohun tí ò ń ṣe?’ Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ lè sọ pé, ‘Òun kò ní ọwọ́?’ ()
Væ qui contradicit Fictori suo, testa de samiis terræ: numquid dicet lutum figulo suo: Quid facis, et opus tuum absque manibus est?
10 Ègbé ni fún ẹni tí ó sọ fún baba rẹ̀ pé, ‘Kí ni o bí?’ tàbí sí ìyá rẹ̀, ‘Kí ni ìwọ ti bí?’
Væ qui dicit patri: Quid generas? et mulieri: Quid parturis?
11 “Ohun tí Olúwa wí nìyìí, Ẹni Mímọ́ Israẹli, àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Nípa ohun tí ó ń bọ̀, ǹjẹ́ o ń bi mí léèrè nípa àwọn ọmọ mi, tàbí kí o pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi bí?
Hæc dicit Dominus, Sanctus Israel, Plastes eius: Ventura interrogate me, super filios meos, et super opus manuum mearum mandate mihi.
12 Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayé tí ó sì da ọmọ ènìyàn sórí i rẹ̀. Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀run; mo sì kó àwọn àgbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta.
Ego feci terram, et hominem super eam creavi ego: manus meæ tetenderunt cælos, et omni militiæ eorum mandavi.
13 Èmi yóò gbé Kirusi sókè nínú òdodo mi. Èmi yóò mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́. Òun yóò tún ìlú mi kọ́ yóò sì tú àwọn àtìpó mi sílẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún owó tàbí ẹ̀bùn kan, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”
Ego suscitavi eum ad iustitiam, et omnes vias eius dirigam: ipse ædificabit civitatem meam, et captivitatem meam dimittet, non in pretio, neque in muneribus, dicit Dominus Deus exercituum.
14 Ohun tí Olúwa wí nìyìí: “Àwọn èròjà ilẹ̀ Ejibiti àti àwọn ọjà ilẹ̀ Kuṣi, àti àwọn Sabeani— wọn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ wọn yóò sì jẹ́ tìrẹ; wọn yóò máa wọ́ tẹ̀lé ọ lẹ́yìn, wọn yóò máa wá lọ́wọ̀ọ̀wọ́. Wọn yóò máa foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀, wọn yóò sì máa bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ pé, ‘Nítòótọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ kò sì ṣí ẹlòmíràn; kò sí ọlọ́run mìíràn.’”
Hæc dicit Dominus: Labor Ægypti, et negotiatio Æthiopiæ, et Sabaim viri sublimes, ad te transibunt, et tui erunt: Post te ambulabunt, vincti manicis pergent: et te adorabunt, teque deprecabuntur: Tantum in te est Deus, et non est absque te Deus.
15 Nítòótọ́ ìwọ jẹ́ Ọlọ́run tí ó fi ara rẹ̀ pamọ́, Ìwọ Ọlọ́run àti Olùgbàlà Israẹli,
Vere tu es Deus absconditus, Deus Israel Salvator.
16 Gbogbo àwọn tí ó ń gbẹ́ ère ni ojú yóò tì wọn yóò sì kan àbùkù; gbogbo wọn ni yóò bọ́ sínú àbùkù papọ̀.
Confusi sunt, et erubuerunt omnes: simul abierunt in confusionem fabricatores errorum.
17 Ṣùgbọ́n Israẹli ni a ó gbàlà láti ọwọ́ Olúwa pẹ̀lú ìgbàlà ayérayé; a kì yóò kàn yín lábùkù tàbí kí a dójútì yín, títí ayé àìnípẹ̀kun.
Israel salvatus est in Domino salute æterna: non confundemini, et non erubescetis usque in sæculum sæculi.
18 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí, ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run, Òun ni Ọlọ́run; ẹni tí ó mọ tí ó sì dá ayé, Òun ló ṣe é; Òun kò dá a láti wà lófo, ṣùgbọ́n ó ṣe é kí a lè máa gbé ibẹ̀, Òun wí pé: “Èmi ni Olúwa, kò sì ṣí ẹlòmíràn.
Quia hæc dicit Dominus creans cælos, ipse Deus formans terram, et faciens eam, ipse Plastes eius: non in vanum creavit eam: ut habitaretur, formavit eam. Ego Dominus, et non est alius.
19 Èmi kò sọ̀rọ̀ níbi tí ó fi ara sin, láti ibìkan ní ilẹ̀ òkùnkùn, Èmi kò tí ì sọ fún àwọn ìran Jakọbu pé, ‘Ẹ wá mi lórí asán.’ Èmi Olúwa sọ òtítọ́, Mo sì sọ èyí tí ó tọ̀nà.
Non in abscondito locutus sum, in loco terræ tenebroso: non dixi semini Iacob: Frustra quærite me. Ego Dominus loquens iustitiam, annuncians recta.
20 “Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ sì wá; ẹ kórajọ, ẹ̀yin ìsáǹsá láti àwọn orílẹ̀-èdè wá. Aláìmọ̀kan ni àwọn tí ó ń ru ère igi káàkiri, tí wọ́n gbàdúrà sí àwọn òrìṣà tí kò le gba ni.
Congregamini, et venite, et accedite simul qui salvati estis ex Gentibus: nescierunt qui levant lignum sculpturæ suæ, et rogant deum non salvantem.
21 Jẹ́ kí a mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀, fihàn wá, jẹ́ kí wọn jọ dámọ̀ràn papọ̀. Ta ló ti sọ èyí lọ́jọ́ tí o ti pẹ́, ta ló ti wí èyí láti àtètèkọ́ṣe? Kì í ha á ṣe Èmi, Olúwa? Àti pé kò sí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi, Ọlọ́run olódodo àti olùgbàlà; kò sí ẹlòmíràn àfi èmi.
Annunciate, et venite, et consiliamini simul: Quis auditum fecit hoc ab initio, ex tunc prædixit illud? Numquid non ego Dominus, et non est ultra deus absque me? Deus iustus, et salvans non est præter me.
22 “Yípadà sí mi kí a sì gbà ọ́ là, ẹ̀yin ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé; nítorí Èmi ni Ọlọ́run kò sì ṣí ẹlòmíràn.
Convertimini ad me, et salvi eritis omnes fines terræ: quia ego Deus, et non est alius.
23 Nípa èmi tìkára mi ni mo ti búra, ẹnu mi ni ó ti sọ ọ́ pẹ̀lú gbogbo ipá mi, ọ̀rọ̀ náà tí a kì yóò lè parẹ́. Níwájú mi ni gbogbo orúnkún yóò wólẹ̀; nípa mi ni gbogbo ahọ́n yóò búra.
In memetipso iuravi, egredietur de ore meo iustitiæ verbum, et non revertetur: quia mihi curvabitur omne genu, et iurabit omnis lingua.
24 Wọn yóò sọ ní ti èmi, ‘Nínú Olúwa nìkan ni òdodo àti agbára wà.’” Gbogbo àwọn tí ó ti bínú sí; yóò wá sọ́dọ̀ rẹ̀ a ó sì dójútì wọn.
Ergo in Domino, dicet, meæ sunt iustitiæ et imperium: ad eum venient, et confundentur omnes qui repugnant ei.
25 Ṣùgbọ́n nínú Olúwa gbogbo àwọn ìran Israẹli ni a ó rí ní òdodo, a o sì gbé wọn ga.
In Domino iustificabitur, et laudabitur omne semen Israel.