< Isaiah 44 >

1 “Ṣùgbọ́n gbọ́ nísinsin yìí, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi, àti Israẹli, ẹni tí mo ti yàn.
ועתה שמע יעקב עבדי וישראל בחרתי בו׃
2 Ohun tí Olúwa wí nìyìí ẹni tí ó dá ọ, ẹni tí ó ti mọ̀ ọ́n láti inú ìyá rẹ wá, àti ẹni tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú. Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu, ìránṣẹ́ mi, Jeṣuruni ẹni tí mo ti yàn.
כה אמר יהוה עשך ויצרך מבטן יעזרך אל תירא עבדי יעקב וישרון בחרתי בו׃
3 Nítorí èmi yóò da omi sí ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ àti àwọn odò ní ilẹ̀ gbígbẹ, Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi sí ara àwọn ọmọ rẹ, àti ìbùkún mi sórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ.
כי אצק מים על צמא ונזלים על יבשה אצק רוחי על זרעך וברכתי על צאצאיך׃
4 Wọn yóò dàgbàsókè gẹ́gẹ́ bí i koríko nínú pápá oko tútù, àti gẹ́gẹ́ bí igi Poplari létí odò tí ń sàn.
וצמחו בבין חציר כערבים על יבלי מים׃
5 Ọ̀kan yóò wí pé, ‘Èmi jẹ́ ti Olúwa’; òmíràn yóò pe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orúkọ Jakọbu; bẹ́ẹ̀ ni òmíràn yóò kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀, ‘Ti Olúwa,’ yóò sì máa jẹ́ orúkọ náà Israẹli.
זה יאמר ליהוה אני וזה יקרא בשם יעקב וזה יכתב ידו ליהוה ובשם ישראל יכנה׃
6 “Ohun tí Olúwa wí nìyìí ọba Israẹli àti Olùdáǹdè, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn, lẹ́yìn mi kò sí Ọlọ́run kan.
כה אמר יהוה מלך ישראל וגאלו יהוה צבאות אני ראשון ואני אחרון ומבלעדי אין אלהים׃
7 Ta ni ó dàbí ì mi? Jẹ́ kí o kéde rẹ̀. Jẹ́ kí ó wí kí ó sì gbé síwájú mi kí ni ó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí mo fi ìdí àwọn ènìyàn ìṣẹ̀ǹbáyé kalẹ̀, àti kí ni ohun tí ń sì ń bọ̀, bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí ń bọ̀ wá.
ומי כמוני יקרא ויגידה ויערכה לי משומי עם עולם ואתיות ואשר תבאנה יגידו למו׃
8 Má ṣe wárìrì, má ṣe bẹ̀rù. Ǹjẹ́ èmi kò ti kéde èyí tí mo sì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tipẹ́tipẹ́? Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan ha ń bẹ lẹ́yìn mi? Bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sí àpáta mìíràn; Èmi kò mọ ọ̀kankan.”
אל תפחדו ואל תרהו הלא מאז השמעתיך והגדתי ואתם עדי היש אלוה מבלעדי ואין צור בל ידעתי׃
9 Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère jásí asán, àti àwọn ohun tí wọn ń kó pamọ́ kò jámọ́ nǹkan kan. Àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ fún wọn fọ́ lójú; wọ́n jẹ́ aláìmọ̀kan sí ìtìjú ara wọn.
יצרי פסל כלם תהו וחמודיהם בל יועילו ועדיהם המה בל יראו ובל ידעו למען יבשו׃
10 Ta ni ó mọ òrìṣà kan tí ó sì ya ère, tí kò lè mú èrè kankan wá fún un?
מי יצר אל ופסל נסך לבלתי הועיל׃
11 Òun àti nǹkan rẹ̀ wọ̀nyí ni a ó dójútì; àwọn oníṣọ̀nà kò yàtọ̀, ènìyàn ni wọ́n. Jẹ́ kí gbogbo wọn gbárajọ kí wọ́n sì fi ìdúró wọn hàn; gbogbo wọn ni a ó mú bọ́ sínú ìpayà àti àbùkù.
הן כל חבריו יבשו וחרשים המה מאדם יתקבצו כלם יעמדו יפחדו יבשו יחד׃
12 Alágbẹ̀dẹ mú ohun èlò, ó fi ń ṣiṣẹ́ nínú èédú; ó fi òòlù ya ère kan, ó ṣe é pẹ̀lú agbára apá rẹ̀, ebi ń pa á, àárẹ̀ sì mú un; kò mu omi rárá, ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá a.
חרש ברזל מעצד ופעל בפחם ובמקבות יצרהו ויפעלהו בזרוע כחו גם רעב ואין כח לא שתה מים וייעף׃
13 Gbẹ́nàgbẹ́nà fi ìwọ̀n wọ́n ọ́n ó sì fi lẹ́ẹ̀dì ṣe àmì sí ara rẹ̀, Ó tún fi ìfà fá a jáde ó tún fi òsùwọ̀n ṣe àmì sí i. Ó gbẹ́ ẹ ní ìrí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nínú ògo rẹ̀, kí ó lè máa gbé nínú ilé òrìṣà.
חרש עצים נטה קו יתארהו בשרד יעשהו במקצעות ובמחוגה יתארהו ויעשהו כתבנית איש כתפארת אדם לשבת בית׃
14 Ó gé igi kedari lulẹ̀, tàbí bóyá ó mú sípírẹ́ṣì tàbí igi óákù. Ó jẹ́ kí ó dàgbà láàrín àwọn igi inú igbó, ó sì le gbin igi páínì, èyí tí òjò mú kí ó dàgbà.
לכרת לו ארזים ויקח תרזה ואלון ויאמץ לו בעצי יער נטע ארן וגשם יגדל׃
15 Ohun èlò ìdáná ni fún ènìyàn; díẹ̀ nínú rẹ̀ ni ó mú láti mú kí ara rẹ̀ lọ́wọ́ọ́rọ́, ó dá iná ó sì fi ṣe àkàrà. Ṣùgbọ́n bákan náà ni ó ṣe òrìṣà tí ó sì ń sìn ín; ó yá ère, ó sì ń foríbalẹ̀ fún un.
והיה לאדם לבער ויקח מהם ויחם אף ישיק ואפה לחם אף יפעל אל וישתחו עשהו פסל ויסגד למו׃
16 Ìlàjì igi náà ni ó jó nínú iná; lórí i rẹ̀ ni ó ti ń tọ́jú oúnjẹ rẹ̀, ó dín ẹran rẹ̀ ó sì jẹ àjẹyó. Ó tún mú ara rẹ̀ gbóná ó sì sọ pé, “Á à! Ara mi gbóná, mo rí iná.”
חציו שרף במו אש על חציו בשר יאכל יצלה צלי וישבע אף יחם ויאמר האח חמותי ראיתי אור׃
17 Nínú èyí tí ó kù ni ó ti ṣe òrìṣà, ère rẹ̀; ó foríbalẹ̀ fún un, ó sì sìn ín. Ó gbàdúrà sí i, ó wí pé, “Gbà mí, ìwọ ni Ọlọ́run mi.”
ושאריתו לאל עשה לפסלו יסגוד לו וישתחו ויתפלל אליו ויאמר הצילני כי אלי אתה׃
18 Wọn kò mọ nǹkan kan, nǹkan kan kò yé wọn; a fi ìbòjú bo ojú wọn, wọn kò lè rí nǹkan kan; bẹ́ẹ̀ ni àyà wọn sébọ́, wọn kò lè mọ nǹkan kan.
לא ידעו ולא יבינו כי טח מראות עיניהם מהשכיל לבתם׃
19 Kò sí ẹni tí ó dúró láti ronú, kò sí ẹni tí ó ní ìmọ̀ tàbí òye láti sọ wí pé, “Ìlàjì rẹ̀ ni mo fi dáná; mo tilẹ̀ ṣe àkàrà lórí èédú rẹ̀, mo dín ẹran, mo sì jẹ ẹ́. Ǹjẹ́ ó wá yẹ kí n ṣe ohun ìríra kan nínú èyí tí ó ṣẹ́kù bí? Ǹjẹ́ èmi yóò ha foríbalẹ̀ fún ìtì igi?”
ולא ישיב אל לבו ולא דעת ולא תבונה לאמר חציו שרפתי במו אש ואף אפיתי על גחליו לחם אצלה בשר ואכל ויתרו לתועבה אעשה לבול עץ אסגוד׃
20 Ó ń jẹ eérú, ọkàn ẹlẹ́tàn ni ó ṣì í lọ́nà; òun kò lè gba ara rẹ̀ là, tàbí kí ó wí pé, “Ǹjẹ́ nǹkan tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún mi yìí irọ́ kọ́?”
רעה אפר לב הותל הטהו ולא יציל את נפשו ולא יאמר הלוא שקר בימיני׃
21 “Rántí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ìwọ Jakọbu, nítorí ìránṣẹ́ mi ni ìwọ, ìwọ Israẹli. Èmi ti dá ọ, ìránṣẹ́ mi ni ìwọ ṣe, ìwọ Israẹli, Èmi kì yóò gbàgbé rẹ.
זכר אלה יעקב וישראל כי עבדי אתה יצרתיך עבד לי אתה ישראל לא תנשני׃
22 Èmi ti gbá gbogbo ìkùnà rẹ dànù bí i kurukuru, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bí ìrì òwúrọ̀. Padà sọ́dọ̀ mi, nítorí mo ti rà ọ́ padà.”
מחיתי כעב פשעיך וכענן חטאותיך שובה אלי כי גאלתיך׃
23 Kọrin fáyọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí Olúwa ló ti ṣe èyí; kígbe sókè, ìwọ ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀. Bú sí orin, ẹ̀yin òkè ńlá, ẹ̀yin igbó àti gbogbo igi yín, nítorí Olúwa ti ra Jakọbu padà, ó ti fi ògo rẹ̀ hàn ní Israẹli.
רנו שמים כי עשה יהוה הריעו תחתיות ארץ פצחו הרים רנה יער וכל עץ בו כי גאל יהוה יעקב ובישראל יתפאר׃
24 “Ohun tí Olúwa wí nìyìí Olùràpadà rẹ tí ó mọ ọ́ láti inú ìyá rẹ wá: “Èmi ni Olúwa tí ó ti ṣe ohun gbogbo tí òun nìkan ti na àwọn ọ̀run tí o sì tẹ́ ayé pẹrẹsẹ òun tìkára rẹ̀,
כה אמר יהוה גאלך ויצרך מבטן אנכי יהוה עשה כל נטה שמים לבדי רקע הארץ מי אתי׃
25 ta ni ó ba àmì àwọn wòlíì èké jẹ́ tí ó sì sọ àwọn aláfọ̀ṣẹ di òmùgọ̀, tí ó dojú ìmọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n délẹ̀ tí ó sì sọ wọ́n di òmùgọ̀,
מפר אתות בדים וקסמים יהולל משיב חכמים אחור ודעתם ישכל׃
26 ẹni tí ó gbé ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jáde tí ó sì mú àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìmúṣẹ, “ẹni tí ó wí nípa ti Jerusalẹmu pé, ‘A ó máa gbé inú rẹ̀,’ àti ní ti àwọn ìlú Juda, ‘A ó tún kọ́,’ àti àwọn ahoro rẹ̀, ‘Èmi yóò mú un bọ̀ sípò,’
מקים דבר עבדו ועצת מלאכיו ישלים האמר לירושלם תושב ולערי יהודה תבנינה וחרבותיה אקומם׃
27 ta ni ó sọ fún omi jíjìn pé, ‘Ìwọ gbẹ, èmi yóò sì mú omi odò rẹ gbẹ,’
האמר לצולה חרבי ונהרתיך אוביש׃
28 ta ni ó sọ nípa Kirusi pé, ‘Òun ni Olùṣọ́-àgùntàn mi àti pé òun yóò ṣe ohun gbogbo tí mo fẹ́; òun yóò sọ nípa Jerusalẹmu pé, “Jẹ́ kí a tún kọ́,” àti nípa tẹmpili, “Jẹ́ kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀.”’”
האמר לכורש רעי וכל חפצי ישלם ולאמר לירושלם תבנה והיכל תוסד׃

< Isaiah 44 >