< Isaiah 43 >

1 Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, ohun tí Olúwa wí nìyìí, ẹni tí ó dá ọ, ìwọ Jakọbu, ẹni tí ó mọ ọ́, ìwọ Israẹli: “Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè; Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ; tèmi ni ìwọ ṣe.
ועתה כה אמר יהוה בראך יעקב ויצרך ישראל אל תירא כי גאלתיך קראתי בשמך לי אתה׃
2 Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá, Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ; àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjá wọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀. Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá, kò ní jó ọ; ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.
כי תעבר במים אתך אני ובנהרות לא ישטפוך כי תלך במו אש לא תכוה ולהבה לא תבער בך׃
3 Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli Olùgbàlà rẹ; Èmi fi Ejibiti ṣe ìràpadà rẹ, Kuṣi àti Seba dípò rẹ.
כי אני יהוה אלהיך קדוש ישראל מושיעך נתתי כפרך מצרים כוש וסבא תחתיך׃
4 Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi, àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ, Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ, àti ènìyàn dípò ẹ̀mí rẹ.
מאשר יקרת בעיני נכבדת ואני אהבתיך ואתן אדם תחתיך ולאמים תחת נפשך׃
5 Má bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ; Èmi yóò mú àwọn ọmọ rẹ láti ìlà-oòrùn wá èmi ó sì kó ọ jọ láti ìwọ̀-oòrùn.
אל תירא כי אתך אני ממזרח אביא זרעך וממערב אקבצך׃
6 Èmi yóò sọ fún àríwá pé, ‘Fi wọ́n sílẹ̀!’ Àti fún gúúsù, ‘Má ṣe dá wọn dúró.’ Mú àwọn ọmọkùnrin mi láti ọ̀nà jíjìn wá àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mi láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé—
אמר לצפון תני ולתימן אל תכלאי הביאי בני מרחוק ובנותי מקצה הארץ׃
7 ẹnikẹ́ni tí a ń pe orúkọ mi mọ́, tí mo dá fún ògo mi, tí mo mọ̀ àti tí mo ṣe.”
כל הנקרא בשמי ולכבודי בראתיו יצרתיו אף עשיתיו׃
8 Sin àwọn tí ó ní ojú ṣùgbọ́n tí wọ́n fọ́jú jáde, tí wọ́n ní etí ṣùgbọ́n tí wọn dití.
הוציא עם עור ועינים יש וחרשים ואזנים למו׃
9 Gbogbo orílẹ̀-èdè kó ra wọn jọ àwọn ènìyàn sì kó ra wọn papọ̀. Ta ni nínú wọn tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí tí ó sì kéde fún wa àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀? Jẹ́ kí wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn wọlé wá láti fihàn pé wọ́n tọ̀nà tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn mìíràn yóò gbọ́, tí wọn yóò sọ pé, “Òtítọ́ ni.”
כל הגוים נקבצו יחדו ויאספו לאמים מי בהם יגיד זאת וראשנות ישמיענו יתנו עדיהם ויצדקו וישמעו ויאמרו אמת׃
10 “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí, “Àti ìránṣẹ́ mi tí èmi ti yàn, tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi mọ̀ àti tí ẹ̀yin ó fi gbà mí gbọ́ tí yóò sì yé e yín pé èmi ni ẹni náà. Ṣáájú mi kò sí ọlọ́run tí a dá, tàbí a ó wa rí òmíràn lẹ́yìn mi.
אתם עדי נאם יהוה ועבדי אשר בחרתי למען תדעו ותאמינו לי ותבינו כי אני הוא לפני לא נוצר אל ואחרי לא יהיה׃
11 Èmi, àní Èmi, Èmi ni Olúwa, yàtọ̀ sí èmi, kò sí olùgbàlà mìíràn.
אנכי אנכי יהוה ואין מבלעדי מושיע׃
12 Èmi ti fihàn, mo gbàlà mo sì ti kéde Èmi, kì í sì í ṣe àwọn àjèjì òrìṣà láàrín yín. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí, “Pé Èmi ni Ọlọ́run.
אנכי הגדתי והושעתי והשמעתי ואין בכם זר ואתם עדי נאם יהוה ואני אל׃
13 Bẹ́ẹ̀ ni, àti láti ayérayé Èmi ni ẹni náà. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ mi. Nígbà tí mo bá ṣe nǹkan, ta ni ó lè yí i padà?”
גם מיום אני הוא ואין מידי מציל אפעל ומי ישיבנה׃
14 Èyí ni ohun tí Olúwa wí, olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli: “Nítorí rẹ Èmi yóò ránṣẹ́ sí Babeli láti mú wọn sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá, gbogbo ará Babeli, nínú ọkọ̀ ojú omi nínú èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga.
כה אמר יהוה גאלכם קדוש ישראל למענכם שלחתי בבלה והורדתי בריחים כלם וכשדים באניות רנתם׃
15 Èmi ni Olúwa, Ẹni Mímọ́ rẹ, Ẹlẹ́dàá Israẹli, ọba rẹ.”
אני יהוה קדושכם בורא ישראל מלככם׃
16 Èyí ni ohun tí Olúwa wí, Ẹni náà tí ó la ọ̀nà nínú Òkun, ipa ọ̀nà láàrín alagbalúgbú omi,
כה אמר יהוה הנותן בים דרך ובמים עזים נתיבה׃
17 ẹni tí ó wọ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jáde, àwọn jagunjagun àti ohun ìjà papọ̀, wọ́n sì sùn síbẹ̀, láìní lè dìde mọ́, wọ́n kú pirá bí òwú-fìtílà:
המוציא רכב וסוס חיל ועזוז יחדו ישכבו בל יקומו דעכו כפשתה כבו׃
18 “Gbàgbé àwọn ohun àtẹ̀yìnwá; má ṣe gbé nínú ohun àtijọ́.
אל תזכרו ראשנות וקדמניות אל תתבננו׃
19 Wò ó, Èmi ń ṣe ohun tuntun! Nísinsin yìí, ó ti yọ sókè; àbí o kò rí i bí? Èmi ń ṣe ọ̀nà kan nínú aṣálẹ̀ àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá.
הנני עשה חדשה עתה תצמח הלוא תדעוה אף אשים במדבר דרך בישמון נהרות׃
20 Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi, àwọn ajáko àti àwọn òwìwí, nítorí pé mo pèsè omi nínú aṣálẹ̀ àti odò nínú ilẹ̀ sísá, láti fi ohun mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi,
תכבדני חית השדה תנים ובנות יענה כי נתתי במדבר מים נהרות בישימן להשקות עמי בחירי׃
21 àwọn ènìyàn tí mo dá fún ara mi kí wọn kí ó lè kéde ìyìn mi.
עם זו יצרתי לי תהלתי יספרו׃
22 “Síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ kò tí ì ké pè mí, ìwọ Jakọbu, àárẹ̀ kò tí ì mú ọ nítorí mi ìwọ Israẹli.
ולא אתי קראת יעקב כי יגעת בי ישראל׃
23 Ìwọ kò tí ì mú àgùntàn wá fún mi fún ẹbọ sísun, tàbí kí o bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ẹbọ rẹ. Èmi kò tí ì wàhálà rẹ pẹ̀lú ọrẹ ìyẹ̀fun tàbí kí n dààmú rẹ pẹ̀lú ìbéèrè fún tùràrí.
לא הביאת לי שה עלתיך וזבחיך לא כבדתני לא העבדתיך במנחה ולא הוגעתיך בלבונה׃
24 Ìwọ kò tí ì ra kalamusi olóòórùn dídùn fún mi, tàbí kí o da ọ̀rá ẹbọ rẹ bò mí. Ṣùgbọ́n ẹ ti wàhálà mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ yín ẹ sì ti dààmú mi pẹ̀lú àìṣedéédéé yín.
לא קנית לי בכסף קנה וחלב זבחיך לא הרויתני אך העבדתני בחטאותיך הוגעתני בעונתיך׃
25 “Èmi, àní Èmi, Èmi ni ẹni tí ó wẹ àwọn àìṣedéédéé rẹ nù, nítorí èmi fún ara mi, tí n kò sì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ mọ́.
אנכי אנכי הוא מחה פשעיך למעני וחטאתיך לא אזכר׃
26 Bojú wo ẹ̀yìn rẹ fún mi, jẹ́ kí a jọ ṣe àríyànjiyàn ọ̀rọ̀ náà papọ̀; ro ẹjọ́ láti fihàn pé o kò lẹ́sẹ̀ lọ́rùn.
הזכירני נשפטה יחד ספר אתה למען תצדק׃
27 Baba yín àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀; àwọn agbẹnusọ yín ṣọ̀tẹ̀ sí mi.
אביך הראשון חטא ומליציך פשעו בי׃
28 Nítorí náà, èmi ti sọ àwọn olórí ibi mímọ́ náà di àìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi ti fi Jakọbu fún ègún àti Israẹli fún ẹ̀gàn.
ואחלל שרי קדש ואתנה לחרם יעקב וישראל לגדופים׃

< Isaiah 43 >