< Isaiah 42 >

1 “Ìránṣẹ́ mi nìyìí, ẹni tí mo gbéró, àyànfẹ́ mi nínú ẹni tí mo láyọ̀; Èmi yóò fi Ẹ̀mí mi sínú rẹ̀ òun yóò sì mú ìdájọ́ wá sórí àwọn orílẹ̀-èdè.
Ιακωβ ὁ παῖς μου ἀντιλήμψομαι αὐτοῦ Ισραηλ ὁ ἐκλεκτός μου προσεδέξατο αὐτὸν ἡ ψυχή μου ἔδωκα τὸ πνεῦμά μου ἐπ’ αὐτόν κρίσιν τοῖς ἔθνεσιν ἐξοίσει
2 Òun kì yóò pariwo tàbí kígbe sókè, tàbí kí ó gbóhùn rẹ̀ sókè ní òpópónà.
οὐ κεκράξεται οὐδὲ ἀνήσει οὐδὲ ἀκουσθήσεται ἔξω ἡ φωνὴ αὐτοῦ
3 Koríko odò títẹ̀ kan ni òun kì yóò fọ́, àti òwú-fìtílà tí ń jó tan an lọ lòun kì yóò fẹ́ pa. Ní òdodo ni yóò mú ìdájọ́ wá;
κάλαμον τεθλασμένον οὐ συντρίψει καὶ λίνον καπνιζόμενον οὐ σβέσει ἀλλὰ εἰς ἀλήθειαν ἐξοίσει κρίσιν
4 òun kì yóò kọsẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò ní rẹ̀wẹ̀sì títí tí yóò fi fi ìdájọ́ múlẹ̀ ní ayé. Nínú òfin rẹ̀ ni àwọn erékùṣù yóò fi ìrètí wọn sí.”
ἀναλάμψει καὶ οὐ θραυσθήσεται ἕως ἂν θῇ ἐπὶ τῆς γῆς κρίσιν καὶ ἐπὶ τῷ ὀνόματι αὐτοῦ ἔθνη ἐλπιοῦσιν
5 Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí Ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run tí ó sì tẹ́ wọ́n sóde, tí ó tẹ́ ilẹ̀ ayé àti ohun gbogbo tí ó jáde nínú wọn, Ẹni tí ó fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní èémí àti ẹ̀mí fún gbogbo àwọn tí ń rìn nínú rẹ̀:
οὕτως λέγει κύριος ὁ θεὸς ὁ ποιήσας τὸν οὐρανὸν καὶ πήξας αὐτόν ὁ στερεώσας τὴν γῆν καὶ τὰ ἐν αὐτῇ καὶ διδοὺς πνοὴν τῷ λαῷ τῷ ἐπ’ αὐτῆς καὶ πνεῦμα τοῖς πατοῦσιν αὐτήν
6 “Èmi, Olúwa, ti pè ọ́ ní òdodo, Èmi yóò di ọwọ́ rẹ mú. Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́ láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn àti ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà
ἐγὼ κύριος ὁ θεὸς ἐκάλεσά σε ἐν δικαιοσύνῃ καὶ κρατήσω τῆς χειρός σου καὶ ἐνισχύσω σε καὶ ἔδωκά σε εἰς διαθήκην γένους εἰς φῶς ἐθνῶν
7 láti la àwọn ojú tí ó fọ́, láti tú àwọn òǹdè kúrò nínú túbú àti láti tú sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n àwọn tí ó jókòó nínú òkùnkùn.
ἀνοῖξαι ὀφθαλμοὺς τυφλῶν ἐξαγαγεῖν ἐκ δεσμῶν δεδεμένους καὶ ἐξ οἴκου φυλακῆς καθημένους ἐν σκότει
8 “Èmi ni Olúwa; orúkọ mi nìyìí! Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn tàbí ìyìn mi fún ère òrìṣà.
ἐγὼ κύριος ὁ θεός τοῦτό μού ἐστιν τὸ ὄνομα τὴν δόξαν μου ἑτέρῳ οὐ δώσω οὐδὲ τὰς ἀρετάς μου τοῖς γλυπτοῖς
9 Kíyèsi i, àwọn nǹkan àtijọ́ ti wáyé, àti àwọn nǹkan tuntun ni mo ti wí pé; kí wọn tó hù jáde mo ti kéde rẹ̀ fún ọ.”
τὰ ἀπ’ ἀρχῆς ἰδοὺ ἥκασιν καὶ καινὰ ἃ ἐγὼ ἀναγγελῶ καὶ πρὸ τοῦ ἀνατεῖλαι ἐδηλώθη ὑμῖν
10 Kọ orin tuntun sí Olúwa ìyìn rẹ̀ láti òpin ilẹ̀ ayé wá, ẹ̀yin tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú Òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, ẹ̀yin erékùṣù, àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú wọn.
ὑμνήσατε τῷ κυρίῳ ὕμνον καινόν ἡ ἀρχὴ αὐτοῦ δοξάζετε τὸ ὄνομα αὐτοῦ ἀπ’ ἄκρου τῆς γῆς οἱ καταβαίνοντες εἰς τὴν θάλασσαν καὶ πλέοντες αὐτήν αἱ νῆσοι καὶ οἱ κατοικοῦντες αὐτάς
11 Jẹ́ kí aginjù àti àwọn ìlú rẹ̀ kí ó gbé ohùn wọn sókè; jẹ́ kí ibùdó ti àwọn ìlú Kedari ń gbé máa yọ̀. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Sela kọrin fún ayọ̀; jẹ́ kí wọn pariwo láti orí òkè.
εὐφράνθητι ἔρημος καὶ αἱ κῶμαι αὐτῆς ἐπαύλεις καὶ οἱ κατοικοῦντες Κηδαρ εὐφρανθήσονται οἱ κατοικοῦντες Πέτραν ἀπ’ ἄκρων τῶν ὀρέων βοήσουσιν
12 Jẹ́ kí wọn fi ògo fún Olúwa àti kí wọn sì kéde ìyìn rẹ̀ ní erékùṣù.
δώσουσιν τῷ θεῷ δόξαν τὰς ἀρετὰς αὐτοῦ ἐν ταῖς νήσοις ἀναγγελοῦσιν
13 Olúwa yóò rìn jáde gẹ́gẹ́ bí i ọkùnrin alágbára, yóò ru owú sókè bí ológun; yóò kígbe nítòótọ́, òun yóò ké igbe ogun, òun yóò sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀.
κύριος ὁ θεὸς τῶν δυνάμεων ἐξελεύσεται καὶ συντρίψει πόλεμον ἐπεγερεῖ ζῆλον καὶ βοήσεται ἐπὶ τοὺς ἐχθροὺς αὐτοῦ μετὰ ἰσχύος
14 “Fún ìgbà pípẹ́ ni mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́, mo ti wà ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, mo sì kó ara ró. Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí, mo sọkún, mo sì ń mí hẹlẹ hẹlẹ.
ἐσιώπησα μὴ καὶ ἀεὶ σιωπήσομαι καὶ ἀνέξομαι ἐκαρτέρησα ὡς ἡ τίκτουσα ἐκστήσω καὶ ξηρανῶ ἅμα
15 Èmi yóò sọ òkè ńlá àti kékeré di ahoro tí n ó sì gbẹ gbogbo ewéko rẹ̀ dànù, Èmi yóò sọ àwọn odò di erékùṣù n ó sì gbẹ àwọn adágún.
καὶ θήσω ποταμοὺς εἰς νήσους καὶ ἕλη ξηρανῶ
16 Èmi yóò tọ àwọn afọ́jú ní ọ̀nà tí wọn kò tí ì mọ̀, ní ipa ọ̀nà tí ó ṣàjèjì sí wọn ni èmi yóò tọ́ wọn lọ; Èmi yóò sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájú wọn àti ibi pálapàla ni èmi ó sọ di kíkúnná. Àwọn nǹkan tí máa ṣe nìyìí; Èmi kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
καὶ ἄξω τυφλοὺς ἐν ὁδῷ ᾗ οὐκ ἔγνωσαν καὶ τρίβους οὓς οὐκ ᾔδεισαν πατῆσαι ποιήσω αὐτούς ποιήσω αὐτοῖς τὸ σκότος εἰς φῶς καὶ τὰ σκολιὰ εἰς εὐθεῖαν ταῦτα τὰ ῥήματα ποιήσω καὶ οὐκ ἐγκαταλείψω αὐτούς
17 Ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé òrìṣà, tí wọ́n wí fún ère pé, ‘Ẹ̀yin ni Ọlọ́run wa,’ ni a ó dá padà pẹ̀lú ìtìjú.
αὐτοὶ δὲ ἀπεστράφησαν εἰς τὰ ὀπίσω αἰσχύνθητε αἰσχύνην οἱ πεποιθότες ἐπὶ τοῖς γλυπτοῖς οἱ λέγοντες τοῖς χωνευτοῖς ὑμεῖς ἐστε θεοὶ ἡμῶν
18 “Gbọ́, ìwọ adití, wò ó, ìwọ afọ́jú, o sì rí!
οἱ κωφοί ἀκούσατε καὶ οἱ τυφλοί ἀναβλέψατε ἰδεῖν
19 Ta ló fọ́jú bí kò ṣe ìránṣẹ́ mi, àti odi gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ tí mo rán? Ta ni ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a fi jìnmí, ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Olúwa?
καὶ τίς τυφλὸς ἀλλ’ ἢ οἱ παῖδές μου καὶ κωφοὶ ἀλλ’ ἢ οἱ κυριεύοντες αὐτῶν καὶ ἐτυφλώθησαν οἱ δοῦλοι τοῦ θεοῦ
20 Ẹ̀yin ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan, ṣùgbọ́n ẹ kò ṣe àkíyèsí; etí yín yà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́ nǹkan kan.”
εἴδετε πλεονάκις καὶ οὐκ ἐφυλάξασθε ἠνοιγμένα τὰ ὦτα καὶ οὐκ ἠκούσατε
21 Ó dùn mọ́ Olúwa nítorí òdodo rẹ̀ láti mú òfin rẹ lágbára àti ògo.
κύριος ὁ θεὸς ἐβούλετο ἵνα δικαιωθῇ καὶ μεγαλύνῃ αἴνεσιν καὶ εἶδον
22 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kan nìyìí tí a jà lógun tí a sì kó lẹ́rú, gbogbo wọn ni ó wà nínú ọ̀gbun, tàbí tí a fi pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n. Wọ́n ti di ìkógun, láìsí ẹnìkan tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀; wọ́n ti di ìkógun, láìsí ẹni tí yóò sọ pé, “Dá wọn padà.”
καὶ ἐγένετο ὁ λαὸς πεπρονομευμένος καὶ διηρπασμένος ἡ γὰρ παγὶς ἐν τοῖς ταμιείοις πανταχοῦ καὶ ἐν οἴκοις ἅμα ὅπου ἔκρυψαν αὐτούς ἐγένοντο εἰς προνομήν καὶ οὐκ ἦν ὁ ἐξαιρούμενος ἅρπαγμα καὶ οὐκ ἦν ὁ λέγων ἀπόδος
23 Ta ni nínú yín tí yóò tẹ́tí sí èyí tàbí kí ó ṣe àkíyèsí gidi ní àsìkò tí ó ń bọ̀?
τίς ἐν ὑμῖν ὃς ἐνωτιεῖται ταῦτα εἰσακούσεται εἰς τὰ ἐπερχόμενα
24 Ta ni ó fi Jakọbu lélẹ̀ fún ìkógun, àti Israẹli sílẹ̀ fún onísùnmọ̀mí? Kì í ha ṣe Olúwa ni, ẹni tí àwa ti ṣẹ̀ sí? Nítorí pé wọn kò ní tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀; wọn kò mú òfin rẹ̀ ṣẹ.
τίς ἔδωκεν εἰς διαρπαγὴν Ιακωβ καὶ Ισραηλ τοῖς προνομεύουσιν αὐτόν οὐχὶ ὁ θεός ᾧ ἡμάρτοσαν αὐτῷ καὶ οὐκ ἐβούλοντο ἐν ταῖς ὁδοῖς αὐτοῦ πορεύεσθαι οὐδὲ ἀκούειν τοῦ νόμου αὐτοῦ
25 Nítorí náà ni ó ṣe rọ̀jò ìbínú un rẹ̀ lé wọn lórí, rògbòdìyàn ogun. Èyí tí ó fi ahọ́n iná yí wọn po, síbẹ̀ èdè kò yé wọn; ó jó wọn run, síbẹ̀ wọn kò fi sọ́kàn wọn rárá.
καὶ ἐπήγαγεν ἐπ’ αὐτοὺς ὀργὴν θυμοῦ αὐτοῦ καὶ κατίσχυσεν αὐτοὺς πόλεμος καὶ οἱ συμφλέγοντες αὐτοὺς κύκλῳ καὶ οὐκ ἔγνωσαν ἕκαστος αὐτῶν οὐδὲ ἔθεντο ἐπὶ ψυχήν

< Isaiah 42 >