< Isaiah 39 >

1 Ní àkókò náà ni Merodaki-Baladani ọmọ Baladani ọba Babeli fi ìwé àti ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Hesekiah, nítorí ó gbọ́ pé ó ṣàìsàn ó sì gbádùn.
På den tid sendte Merodak Baladan, Baladans sønn, kongen i Babel, brev og gaver til Esekias, da han hørte at han hadde vært syk og var blitt frisk igjen.
2 Hesekiah gba àwọn ikọ̀ yìí tayọ̀tayọ̀, ó sì fi àwọn nǹkan tí ó wà nínú yàrá ìkẹ́rù sí mọ́ hàn wọ́n—fàdákà, wúrà, ohun olóòórùn dídùn, òróró dídára, gbogbo nǹkan ogun rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìṣúra rẹ̀ kò sí ohunkóhun tí ó wà nínú ààfin rẹ̀ tàbí ní ìjọba rẹ̀ tí Hesekiah kò fihàn wọ́n.
Esekias gledet sig over dem og lot dem få se sitt skattkammer, sølvet og gullet og krydderiene og den kostbare olje og hele sitt våbenhus og alt det som fantes i hans skattkammere; det var ikke den ting Esekias ikke lot dem få se i sitt hus og i hele sitt rike.
3 Lẹ́yìn náà wòlíì Isaiah lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekiah ọba ó sì béèrè pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí, níbo ni wọ́n sì ti wá?” “Láti ilẹ̀ jíjìnnà,” ni èsì Hesekiah. “Wọ́n wá sọ́dọ̀ mi láti Babeli.”
Da kom profeten Esaias til kong Esekias og sa til ham: Hvad sa disse menn, og hvorfra kommer de til dig? Esekias svarte: De er kommet til mig fra et land langt borte, fra Babel.
4 Wòlíì náà sì béèrè pé, “Kí ni wọ́n rí nínú ààfin rẹ?” Hesekiah si dáhùn pe, “Wọ́n rí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin mi. Kò sí ohun kankan nínú ìṣúra mi tí èmi kò fihàn wọ́n.”
Og han sa: Hvad fikk de se i ditt hus? Esekias svarte: Alt det som er i mitt hus, har de fått se; det var ikke den ting jeg ikke lot dem få se i mine skattkammer.
5 Lẹ́yìn náà ni Isaiah sọ fún Hesekiah pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
Da sa Esaias til Esekias: Hør Herrens, hærskarenes Guds ord:
6 Àsìkò ń bọ̀ nítòótọ́ nígbà tí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin rẹ, àti ohun gbogbo tí àwọn baba rẹ ti kójọ títí di ọjọ́ òní yóò di kíkó lọ sí Babeli. Ohun kankan kò ní ṣẹ́kù ni Olúwa wí.
Se, de dager kommer da alt det som er i ditt hus, og alle de skatter dine fedre har samlet like til denne dag, skal føres bort til Babel; det skal ikke bli nogen ting tilbake, sier Herren.
7 Àti díẹ̀ nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ, àwọn ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara rẹ tí a ó bí fún ọ ni a ó kó lọ, wọn yóò sì di ìwẹ̀fà nínú ààfin ọba Babeli.”
Og blandt dine sønner som skal utgå av dig, som du skal avle, skal det være nogen som blir tatt til hoffmenn i kongen av Babels palass.
8 Hesekiah wí fún Isaiah pé, “Rere ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ìwọ sọ.” Nítorí ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Àlàáfíà àti ààbò yóò wà ní ìgbà ayé tèmi.”
Da sa Esekias til Esaias: Det Herrens ord som du har talt, er godt. Så sa han: Det skal jo være fred og trygghet i mine dager.

< Isaiah 39 >