< Isaiah 37 >
1 Nígbà tí ọba Hesekiah gbọ́ èyí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara rẹ̀, ó sì wọ inú tẹmpili Olúwa lọ.
希西家王听见就撕裂衣服,披上麻布,进了耶和华的殿,
2 Òun sì rán Eliakimu alákòóso ààfin, Ṣebna akọ̀wé, àti aṣíwájú àwọn àlùfáà, gbogbo wọn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì Isaiah ọmọ Amosi.
使家宰以利亚敬和书记舍伯那,并祭司中的长老,都披上麻布,去见亚摩斯的儿子先知以赛亚,
3 Wọ́n sọ fún un pé, “Báyìí ni Hesekiah wí, ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ ìbànújẹ́, ìbáwí àti ẹ̀gàn gẹ́gẹ́ bí ìgbà ìbí àwọn ọmọdé tí kò sì ṣí agbára láti bí wọn.
对他说:“希西家如此说:‘今日是急难、责罚、凌辱的日子,就如妇人将要生产婴孩,却没有力量生产。
4 Ó lè jẹ́ pé Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀gágun ẹni tí ọ̀gá rẹ̀ ọba Asiria ti rán láti fi Ọlọ́run alààyè ṣe ẹlẹ́yà, àti pé òun ni yóò bá a wí nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Nítorí náà gbàdúrà fún àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n sì wà láààyè.”
或者耶和华—你的 神听见拉伯沙基的话,就是他主人亚述王打发他来辱骂永生 神的话;耶和华—你的 神听见这话就发斥责。故此,求你为余剩的民扬声祷告。’”
5 Nígbà tí àwọn ìjòyè ọba Hesekiah dé ọ̀dọ̀ Isaiah,
希西家王的臣仆就去见以赛亚。
6 Isaiah sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ fún ọ̀gá yín pé, ‘Ohun tí Olúwa sọ nìyìí. Má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba Asiria tí ó wà nínú ìdè ti fi sọ̀rọ̀-òdì sí mi.
以赛亚对他们说:“要这样对你们的主人说,耶和华如此说:‘你听见亚述王的仆人亵渎我的话,不要惧怕。
7 Tẹ́tí sílẹ̀! Èmi yóò fi ẹ̀mí kan sínú rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé bí o bá ti gbọ́ ìròyìn kan, òun yóò padà sí orílẹ̀-èdè rẹ̀, níbẹ̀ ni n ó sì ti jẹ́ kí wọn ké e lulẹ̀ pẹ̀lú idà.’”
我必惊动他的心;他要听见风声就归回本地,我必使他在那里倒在刀下。’”
8 Nígbà tí ọ̀gágun gbọ́ pé ọba Asiria ti fi Lakiṣi sílẹ̀, ó padà sẹ́yìn, ó sì bá ọba tí ń bá Libina jà.
拉伯沙基回去,正遇见亚述王攻打立拿;原来他早听见亚述王拔营离开拉吉。
9 Ní àkókò yìí Sennakeribu gbọ́ ìròyìn kan pé Tirakah ará Kuṣi ọba Ejibiti ń jáde bọ̀ wá bá òun jà. Nígbà tí ó gbọ́ èyí, ó rán oníṣẹ́ sí Hesekiah pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí,
亚述王听见人论古实王特哈加说:“他出来要与你争战。”亚述王一听见,就打发使者去见希西家,吩咐他们说:
10 “Ẹ sọ fún Hesekiah ọba Juda pé: Má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tàn ọ́ jẹ nígbà tí ó sọ pé, ‘A kì yóò jọ̀wọ́ Jerusalẹmu fún ọba Asiria.’
“你们对犹大王希西家如此说:‘不要听你所倚靠的 神欺哄你说:耶路撒冷必不交在亚述王的手中。
11 Dájúdájú, ìwọ ti gbọ́ ohun tí ọba Asiria ti ṣe sí àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó pa wọ́n run pátápátá. Ǹjẹ́ a ó ha dá ọ nídè bí?
你总听说亚述诸王向列国所行的乃是尽行灭绝,难道你还能得救吗?
12 Ǹjẹ́ àwọn òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi parun ha gbà wọ́n sílẹ̀ bí àwọn òrìṣà Gosani, Harani, Reṣefu àti àwọn ènìyàn Edeni tí wọ́n wà ní Teli-Assari?
我列祖所毁灭的,就是歌散、哈兰、利色,和属提·拉撒的伊甸人;这些国的神何曾拯救这些国呢?
13 Níbo ni ọba Hamati wà, ọba Arpadi, ọba ìlú Sefarfaimi tàbí Hena tàbí Iffa?”
哈马的王,亚珥拔的王,西法瓦音城的王,希拿和以瓦的王,都在哪里呢?’”
14 Hesekiah gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ ó sì kà á. Lẹ́yìn náà ni ó gòkè lọ sí tẹmpili Olúwa ó sì tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú Olúwa.
希西家从使者手里接过书信来,看完了,就上耶和华的殿,将书信在耶和华面前展开。
15 Hesekiah sì gbàdúrà sí Olúwa:
希西家向耶和华祷告说:
16 Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli, tí ó gúnwà láàrín àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run lórí i gbogbo ìjọba orílẹ̀ ayé. Ìwọ ti dá ọ̀run àti ayé.
“坐在二基路伯上万军之耶和华—以色列的 神啊,你—惟有你是天下万国的 神,你曾创造天地。
17 Tẹ́tí sílẹ̀, ìwọ Olúwa, kí o gbọ́, ya ojú rẹ, Ìwọ Olúwa, kí o rí i; tẹ́tí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí Sennakeribu rán láti fi àbùkù kan Ọlọ́run alààyè.
耶和华啊,求你侧耳而听;耶和华啊,求你睁眼而看,要听西拿基立的一切话,他是打发使者来辱骂永生 神的。
18 “Òtítọ́ ni Olúwa pé àwọn ọba Asiria ti sọ àwọn ènìyàn àti ilẹ̀ wọn di asán.
耶和华啊,亚述诸王果然使列国和列国之地变为荒凉,
19 Wọ́n ti da àwọn òrìṣà wọn sínú iná wọ́n sì ti pa wọ́n run, nítorí àwọn wọ̀nyí kì í ṣe ọlọ́run bí kò ṣe igi àti òkúta lásán, tí a ti ọwọ́ ènìyàn ṣe.
将列国的神像都扔在火里;因为他本不是神,乃是人手所造的,是木头、石头的,所以灭绝他。
20 Nísinsin yìí, ìwọ Olúwa, Ọlọ́run wa, gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé yóò fi mọ̀ pé Ìwọ, Ìwọ nìkan, Olúwa ni Ọlọ́run.”
耶和华—我们的 神啊,现在求你救我们脱离亚述王的手,使天下万国都知道惟有你是耶和华。”
21 Lẹ́yìn náà Isaiah ọmọ Amosi rán iṣẹ́ kan sí Hesekiah: “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli sọ pé, nítorí pé ìwọ ti gbàdúrà sí mi nípa Sennakeribu ọba Asiria,
亚摩斯的儿子以赛亚就打发人去见希西家,说:“耶和华—以色列的 神如此说,你既然求我攻击亚述王西拿基立,
22 èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀: “Wúńdíá ọmọbìnrin Sioni ti kẹ́gàn rẹ, ó sì ti fi ọ ṣe ẹlẹ́yà. Ọmọbìnrin Jerusalẹmu ti mi orí rẹ̀ bí ó ti ń sálọ.
所以耶和华论他这样说: 锡安的处女藐视你,嗤笑你; 耶路撒冷的女子向你摇头。
23 Ta ni ìwọ ti bú tí ìwọ sì ti sọ̀rọ̀-òdì sí? Sí ta ní ìwọ ti gbé ohùn rẹ sókè tí o sì gbé ojú rẹ sókè ní ìgbéraga? Sí Ẹni Mímọ́ Israẹli!
你辱骂谁,亵渎谁? 扬起声来,高举眼目攻击谁呢? 乃是攻击以色列的圣者。
24 Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ, ìwọ ti sọ̀rọ̀ búburú sí Olúwa. Tì wọ sì wí pé, ‘Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ mi ni èmi sì fi dé orí àwọn òkè ńlá, sí ibi gíga jùlọ Lebanoni. Èmi a sì ké igi kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀, àti ààyò igi firi rẹ̀. Èmi ti dé ibi rẹ̀ tí ó ga jùlọ, igbó rẹ̀ tí ó dára jùlọ.
你借你的臣仆辱骂主说: 我率领许多战车上山顶, 到黎巴嫩极深之处; 我要砍伐其中高大的香柏树 和佳美的松树。 我必上极高之处, 进入肥田的树林。
25 Èmi ti gbẹ́ kànga ní ilẹ̀ àjèjì mo sì mu omi ní ibẹ̀, pẹ̀lú àtẹ́lẹsẹ̀ mi Èmi ti gbẹ́ gbogbo omi àwọn odò Ejibiti.’
我已经挖井喝水; 我必用脚掌踏干埃及的一切河。
26 “Ṣé o kò tí ì gbọ́? Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti fìdí rẹ̀ mulẹ̀. Láti ìgbà pípẹ́ ni mo ti ṣètò rẹ̀; ní àkókò yìí ni mo mú wá sí ìmúṣẹ, pé o ti sọ àwọn ìlú olódi di àkójọpọ̀ àwọn òkúta.
耶和华说:你岂没有听见 我早先所做的、古时所立的吗? 现在借你使坚固城荒废,变为乱堆。
27 Àwọn ènìyàn, tí agbára ti wọ̀ lẹ́wù, ni wọ́n banújẹ́ tí a sì dójútì. Wọ́n dàbí ohun ọ̀gbìn nínú pápá, gẹ́gẹ́ bí ọ̀jẹ̀lẹ̀ èhíhù tuntun, gẹ́gẹ́ bí i koríko tí ó ń hù lórí òrùlé, tí ó jóná kí ó tó dàgbàsókè.
所以其中的居民力量甚小, 惊惶羞愧。 他们像野草,像青菜, 如房顶上的草, 又如田间未长成的禾稼。
28 “Ṣùgbọ́n mo mọ ibi tí o wà àti ìgbà tí o wá tí o sì lọ àti bí inú rẹ ṣe ru sí mi.
你坐下,你出去,你进来, 你向我发烈怒,我都知道。
29 Nítorí pé inú rẹ ru sí mi àti nítorí pé orí kunkun rẹ ti dé etí ìgbọ́ mi, Èmi yóò fi ìwọ̀ mi sí ọ ní imú, àti ìjẹ mi sí ọ lẹ́nu, èmi yóò sì jẹ́ kí o padà láti ọ̀nà tí o gbà wá.
因你向我发烈怒, 又因你狂傲的话达到我耳中, 我就要用钩子钩上你的鼻子, 把嚼环放在你口里, 使你从原路转回去。
30 “Èyí ni yóò ṣe àmì fún ọ, ìwọ Hesekiah: “Ní ọdún yìí, ìwọ yóò jẹ ohun tí ó hù fúnra rẹ̀, àti ní ọdún kejì ohun tí ó jáde láti ara rẹ. Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, ẹ gbìn kí ẹ sì kórè, ẹ gbin ọgbà àjàrà kí ẹ sì jẹ èso wọn.
“以色列人哪,我赐你们一个证据:你们今年要吃自生的,明年也要吃自长的,至于后年,你们要耕种收割,栽植葡萄园,吃其中的果子。
31 Lẹ́ẹ̀kan sí i, àṣẹ́kù láti ilé Juda yóò ta gbòǹgbò nísàlẹ̀ yóò sì ṣo èso lókè.
犹大家所逃脱余剩的,仍要往下扎根,向上结果。
32 Nítorí láti Jerusalẹmu ni àwọn àṣẹ́kù yóò ti wá, àti láti òkè Sioni ni ikọ̀ àwọn tí ó sálà. Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú èyí ṣẹ.
必有余剩的民从耶路撒冷而出;必有逃脱的人从锡安山而来。万军之耶和华的热心必成就这事。
33 “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọba Asiria, “Òun kì yóò wọ ìlú yìí wá tàbí ta ẹyọ ọfà kan níhìn-ín Òun kì yóò wá síwájú rẹ pẹ̀lú asà tàbí kí ó kó dágunró sílẹ̀ fún un.
“所以耶和华论亚述王如此说:他必不得来到这城,也不在这里射箭,不得拿盾牌到城前,也不筑垒攻城。
34 Nípa ọ̀nà tí ó gbà wá náà ni yóò padà lọ; òun kì yóò wọ inú ìlú yìí,” ni Olúwa wí.
他从哪条路来,必从那条路回去,必不得来到这城。这是耶和华说的。
35 “Èmi yóò dáàbò bo ìlú yìí èmi ó sì gbà á là, nítorí mi àti nítorí Dafidi ìránṣẹ́ mi!”
因我为自己的缘故,又为我仆人大卫的缘故,必保护拯救这城。”
36 Lẹ́yìn náà ni angẹli Olúwa jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní i ibùdó àwọn Asiria. Nígbà tí àwọn ènìyàn yìí jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì gbogbo wọn ti dòkú!
耶和华的使者出去,在亚述营中杀了十八万五千人。清早有人起来一看,都是死尸了。
37 Nítorí náà Sennakeribu ọba Asiria fọ́ bùdó ó sì pẹsẹ̀dà. Òun sì padà sí Ninefe, ó sì dúró síbẹ̀.
亚述王西拿基立就拔营回去,住在尼尼微。
38 Ní ọjọ́ kan, bí ó ti ń jọ́sìn nínú tẹmpili Nisroki òrìṣà rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ Adrameleki àti Ṣareseri gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n sì sálọ sí ilẹ̀ Ararati. Bẹ́ẹ̀ ni Esarhadoni ọmọ rẹ̀ sì gba ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
一日在他的神—尼斯洛庙里叩拜,他儿子亚得米勒和沙利色用刀杀了他,就逃到亚拉腊地。他儿子以撒哈顿接续他作王。