< Isaiah 31 >
1 Ègbé ni fún àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti fún ìrànlọ́wọ́, tí wọn gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin tí wọ́n fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́-ẹṣin wọn àti agbára ńlá àwọn ẹlẹ́ṣin wọn, ṣùgbọ́n tiwọn kò bojú wo Ẹni Mímọ́ Israẹli n nì, tàbí kí wọn wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Olúwa.
禍哉,那些南下埃及求救,依靠戰馬,信賴他們戰車眾多,依恃他們鐵騎驍勇,而不仰望以色列的聖者,也不求問上主的人!
2 Síbẹ̀síbẹ̀ òun pẹ̀lú jẹ́ ọlọ́gbọ́n ó sì lè mú ìparun wá; òun kì í kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ. Òun yóò dìde sí ilé àwọn ìkà, àti sí àwọn tí ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún aṣebi.
但是上主仍然能降下災禍,他決不收回自己的言語;他必要起來攻擊惡人的家,攻擊助人作惡的人。
3 Ṣùgbọ́n ènìyàn lásán ni àwọn ará Ejibiti wọn kì í ṣe Ọlọ́run; ẹran-ara ni àwọn ẹṣin wọn, kì í ṣe ẹ̀mí. Nígbà tí Olúwa bá na ọwọ́ rẹ̀ jáde, ẹni náà tí ó ń ṣèrànwọ́ yóò kọsẹ̀, ẹni náà tí à ń ràn lọ́wọ́ yóò ṣubú; àwọn méjèèjì yóò sì jùmọ̀ parun.
埃及人是人,並不是神;他們的戰馬是血肉,並不是靈;只要上主一伸手,施助的人必將仆倒,受助的人必要顛覆:二者同歸於盡。
4 Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi: “Gẹ́gẹ́ bí i kìnnìún ti í ké àní kìnnìún ńlá lórí ẹran ọdẹ rẹ̀ bí a tilẹ̀ rí ẹgbẹ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn tí a sì pè wọ́n papọ̀ láti kojú rẹ̀, ẹ̀rù kò lè bà á pẹ̀lú igbe wọn akitiyan wọn kò sì lè dí i lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò sọ̀kalẹ̀ wá láti jagun lórí òkè Sioni àti lórí ibi gíga rẹ̀.
因為上主曾這樣對我說:「猶如壯獅或幼獅為了獵物而怒吼,即使召集許多牧人攻擊牠,牠並不因他們的叫囂而畏懼,也不因他們的喧嚷而驚慌;同樣,萬軍的上主必要降下,為熙雍和她的丘嶺作戰。
5 Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹyẹ ti ń rábàbà lókè Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bo Jerusalẹmu, Òun yóò dáàbò bò ó, yóò sì tú u sílẹ̀ Òun yóò ré e kọjá yóò sì gbà á sílẹ̀.”
有如飛鳥展翼護雛,萬軍的上主也要這樣扞衛耶路撒冷,加以保護、拯救、憐恤、保存。」
6 Ẹ padà sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣọ̀tẹ̀ sí gidigidi, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.
以色列子民啊!再歸到你們所遠離的上主那裏罷!
7 Nítorí ní ọjọ́ náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò kọ àwọn ère fàdákà àti wúrà tí ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín ti ṣe.
因為到那一天,人人必要拋棄自己的銀偶像和金偶像,即你們以污穢的手所製造的。
8 “Asiria yóò ṣubú lọ́wọ́ idà kan tí kò ti ọwọ́ ènìyàn wá; idà tí kì í ṣe ti ẹ̀dá alààyè ni yóò pa wọ́n. Wọn yóò sì sá níwájú idà náà àti àwọn ọmọkùnrin wọn ni a ó fún ní iṣẹ́ ipá ṣe.
亞述必將傾覆於超人的刀下,超人的刀必將吞噬她;她將由刀劍面前逃走,她的壯丁必要充作苦役。
9 Àpáta rẹ yóò kọjá lọ fún ẹ̀rù; àwọn olórí rẹ yóò bẹ̀rù asia náà,” ni Olúwa wí, ẹni tí iná rẹ̀ ń bẹ ní Sioni, ẹni tí ìléru rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu.
她的磐石由於震驚必要逃避,她的王侯,由於恐慌必將放棄軍旗:這是在熙雍有火,在耶路撒冷有爐的上主的斷語。